Àwọn ajínigbé de àwọn olùkọ́ ọkùnrin tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso mọ́lẹ̀, wón tún fi aṣọ bò wọ́n lójú fún ọjọ́ mérìndínlọ́gọ́ta - Soun

Soun Ilẹ Ogbomoso wọ agbada ati fila nibi to ti n ṣabẹwo sawọn akẹkọọ atawọn olukọ to gbominira lọwọ ajinigbe

Oríṣun àwòrán, Oba Ghandi Afolabi Olaoye/Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Soun ti ilẹ Ogbomoso, Ọba Ghandi Afolabi Olaoye, ti sabẹwo s'awọn akẹkọọ at'awọn olukọ Ahoro Esinele ati Yawota l'Ogbomoso ti wọn ṣẹṣẹ gbòmìnira lọwọ ajinigbe.

Ọba Olaoye lanfaani lati ri awọn akẹẹkọ at'awọn olukọ naa lasiko ti o kan sí ẹka ileeṣẹ ọmogun Naijiria to wa niluu Ibadan nibi ti kabiyesi ti gboṣuba kare fun ọga agba oludari ẹka naa to wa ni agbegbe Ojoo fun iṣẹ takun takun ti wọn ṣe lori bi wọn ṣe doola awọn akẹẹkọ at'awọn olukọ naa.

Soun ni ọrọ t'awọn olukọ at'awọn akẹkọọ naa sọ fi idi rẹ múlẹ pe oju wọn rí to ni akata awọn ajinigbe.

Ọba Ghandi ni eyi to buru ju ni pe awọn janduku ajinigbe naa so awọn olukọ ọkunrin to wa ninu awon ti wọn ji gbe mọlẹ fun odidi ọjọ mẹrindinlọgọta ti wọn fi wa ninu igbo.

Bakan naa ni kabiyesi tun sọ pe awọn olukọ naa ni awọn janduku agbébọn naa tun fi aṣọ bo àwọn loju t'awọn ko si le rí nkankan.

Oriade naa ni ko si ẹnikẹni to yẹ ko la iru nnkan bayii kọjá lọwọ àwọn ajinigbe.

''Bi awọn ọmọ wa atawọn olukọ wọn ṣe pada sile fi idi rẹ mulẹ pe Ọlọrun n gbọ adura''

Amọ, Ọba Olaoye sọ pe ''gbogbo ọrọ naa ti ja sayọ bayii.

Bi awọn ọmọ wa atawọn olukọ wọn ṣe pada sile fi idi rẹ mulẹ pe Ọlọrun n gbọ adura.

A dupẹ lọwọ Ọlọrun fun bi o ti daabo bawọn akẹkọọ atawọn olukọ wa.

Gbogbo wọn ni wọn n gba itọju lọwọ bayii nile iwosan, nnkan ti ọpọ ti ro pe yoo ja si ibanujẹ lo ti di ẹri bayii.

Mo tun fi asiko yii dupẹ lọwọ ijọba apapọ ati ti ipinlẹ, ati lọwọ gbogbo ẹṣọ eleto aabo to fi mọ gbogbo araalu fun ipa kan tabi omiran ti wọn ko lori ati doola awọn akẹkọọ atawọn olukọ Esinele ati Yawota nijọba ibilẹ Oriire.''

Kabiyesi wa rọ gbogbo olugbe ilu Ogbomoso wi pe ki wọn tubọ maa gbadura fawọn eeyan mii ti wọn wa lakata awọn ajinigbe kaakiri orilẹede Naijiria kawọn naa le gbominira.

Ọba Olaoye tun gbadura wi pe ki Eledua tu gbogbo awọn ti inira ti ba latari eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria ninu.

Soun tun gbadura wi pe ilu Ogbomoso ko ni ni iru iriri buruku bayii mọ.

Lara awọn to kọwọọ rin pẹlu kabiyesi ni Oba Thompson Adeyeye Oyetunji, Alaajawa ti Ajaawa, Oba Bolarinwa Ezekiel Olajide, Onisapa ti Isapa, ati Sẹnẹtọ Fatai Buhari.