Agbolé Akọni: Mọ̀ nípa Ogboriefon, akọni tí wọ́n rí he lórí àkìtàn tó di jagunjagun ńlá

Àkọlé fídíò, Ogboriefon
Agbolé Akọni: Mọ̀ nípa Ogboriefon, akọni tí wọ́n rí he lórí àkìtàn tó di jagunjagun ńlá
Published

Bi ọmọde ko ba ba itan dandan ko ba arọba, arọba si ni baba itan.

Lori eto Agbole Akọni BBC News Yoruba, idile Ogboriefon ni ilu Ibadan ni a balẹ si lati mọ nipa bi akọni yii ṣe lo igbesi aye rẹ nigba to wa laye.

Mogaji ile Ogboriefon, Kazeem Adedeji sọ fun BBC bi akọni naa ṣe lo igbe aye rẹ ati bi o ṣe gba orukọ Ogboriefon eyi ti ọpọ eeyan mọ ọn si titi di oni.

Adedeji salaye pe alajẹ lasan ni Ogboriefon jẹ nitori Ajayi Olosunde ni orukọ ti awọn obi rẹ sọ ọ gangan.

O sọ pe ilu Ejigbo, ni ipinlẹ Osun ni wọn ti bi Ogboriefon ṣugbọn to ṣe irinajo wọ ilu Ibadan gẹgẹ bi awọn jagunjagun ṣe maa n ṣe ni aye atijọ.

Pipa ẹni to n da ilu Ibadan laamu ni Ogboriefon fi gba orukọ

O fi kun ọpọ ogun ni Ogboriefon ja niluu Ibadan to si jẹ pe ogun to ja naa lo fi gba orukọ alajẹ Ogboriofon ti ko parẹ titi di oni.

O salaye pe laye atijọ, ẹnikan to maa n sa sinu igbo lati fi ṣe awọn eeyan ilu Ibadan ni ijamba, to si maa n pa awọn eeyan ninu igbo.

"Ọjọ kan ni Ogboriefon lọgẹgun sori igi lati fẹ mọ ẹni to n ṣe Ibadan ni suta, bo ṣe wa lori igi naa lo ri onitọhun to si yinbọn pa a.

"Bo ṣe pa ẹni naa tan ni o ge ori rẹ to si eyin rẹ di ori naa mu, to gbe awọn nnkan ogun ti ẹni naa n lo si ọwọ mejeeji to si sare wọ inu Ibadan lati fi eni naa han awọn agbaagba ilu.

"Lati igba yẹn ni wọn ti n pe e ni Ogboriefon."

'Ko si bi a ṣe maa sọrọ Ogboriefon lai mu ni ba Latoosa'

Baale ile Ogboriefon ni tirẹ, Marufu Oyebode sọ pe ọdẹ kan lo ri Ogboriefon he lori akitan ti wọn sọ ọ nu si lẹyin ti wọn bi tan, ti eṣinsin si n kun-un bi o tilẹ jẹ pe ko i tii ku.

O ni ọdẹ naa lo tọju rẹ titi to fi dagba ko to fi ilu Ejigbo silẹ.

O ni eyi ni wọn ṣe maa n ki awọn ọmọ ile Ogboriefon ni o ja fikan, o run fikan titi di oni.

Lara awọn ogun ti Ogboriefon ja nigba aye rẹ ni ogun Ijaye, ogun Abeokuta, ogun Efon Alaaye, ogun Ekiti parapọ, to si tun kopa ninu ogun Jalumi ti wọn si ṣẹgun awọn ogun naa.

Adedeji tun sọ pe ibaṣepọ wa laaarin Ogboriefon ati Aarẹ Latoosa nitori ko si bi eeyan ṣe le sọrọ ẹnikan lai mu ẹnu ba ẹnikeji.