Àwọn aṣojú-ṣòfin tó wà níjọba wọlé ìbò abẹ́nú APC ní ìpínlẹ̀ Oyo, àwọn alátakò fọnmú pé Tinubu ń ṣàtìlẹ́yìn fún wọn

Awọn oludije sipo aṣoju sofin niluu Abuja labẹ ẹgbẹ oṣelu APC lati ipinlẹ Oyo ti koro oju si bi ''Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ṣe n ṣe atilẹyin fun awọn aṣoju sofin to n se ijọba lọwọ nibi eto idibo abẹnu'' to waye lọjọ Abamẹta ọjọ kẹrindinlogun oṣu Karun un yii.
Eto idibo naa bẹrẹ ni deede agogo mẹjọ owurọ ti ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa sii tu jade ni ọpọ yanturu lati dibo fun ẹni ti o wu wọn.
Wọọdu si wọọdu ni wọn ṣe eto idibo naa ti a o si gbọ ija kankan lawọn ibi ti BBC Yoruba de niluu Ibadan.
Ṣugbọn bẹẹ kọ ni ọrọ ri ni agbegbe oke ogun ni ipinlẹ Ọyọ.
Lara iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn oludije labẹ ẹgbẹ òṣèlú APC sipo aṣoju sofin lagbegbe ATISBO, Saki East, ati Saki West koro oju si bi nnkan ti wọn sọ pe Tinubu ṣe atilẹyin fun awọn aṣoju sofin to n se ijọba lọwọ.
Ninu atẹjade ti wọn fi ṣọwọ si alaga apapọ fun ẹgbẹ oṣelu APC, awọn Oludije lagbegbe naa sọ pe awọn o fara mọ eto idibo abẹnu to waye naa pẹlu wi pe bii awọn to n dari eto idibo naa ṣe n darukọ Aarẹ Tinubu pé ki gbogbo awọn aṣoju sofin to n ṣe ijọba lọwọlọwọ ni ki awọn ọmọ ẹgbẹ dibo fun.
Awọn ti wọn buwọlu iroyin naa ni Amofin Yisa Yusuf Oyedemi Muslim, Alhaji Jimoh Adeniyi Akanni, Ọgbẹni Kodir Tunde Ajibade, Ọmọwe Lukman Adise Salami, ati Ọmọwe Ismail Adewoyin.
Ti ẹ o ba gbagbe, awọn Oludije kan ṣe ifẹhonuhan niwaju ile ẹgbẹ wọn to wa niluu Ibadan ni ọjọ kẹrinla oṣu karun ọdun t'awa yii lasiko ti alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ ba gbogbo awọn oludije ninu ẹgbẹ oṣelu APC naa sọrọ.
Awọn Oludije naa fẹsun kan awọn alakoso naa pe wọn ni Tinubu ti fọwọ si awọn aṣoju sofin to n ṣe ijọba lọwọlọwọ
Ni Egbeda-Ona Ara, aṣofin to n ṣe ijọba lọwọlọwọ Họnarebu Akin Alabi si jawe Olubori ati gbogbo awọn aṣoju sofin lati ẹkun Ọyọ to fi mọ Ọmọba Akeem Adeyemi, aṣoju sofin lati ẹkun Akinyẹle Aṣofin Lafisoye Akinmoyede, aṣoju sofin lati ẹkun Oluyọle Abiodun Gbọlagade, aṣoju sofin lati ẹkun ila-oorun Ibadan Faruq Umar Arisekola - Alao


























