Wo ìdí tí Demond Elliot ṣe ń bẹ Femi Gbajabiamila lórí ìkúnlẹ̀

Femi Gbajabiamila ati Desmond Elliot

Oríṣun àwòrán, @EleluAyoola

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Fidio bi ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko nni, Desmond Elliot, ṣe n bẹ olori oṣiṣẹ Aarẹ Naijiria, Femi Gbajabiamila lori ikunlẹ ti bẹrẹ si n milẹ titi lori ayelujara.

Ọpọ lo ti n woye ohun to le mu ki odidi aṣofin to tun jẹ gbajumọ oṣera tiata Nollywood maa bẹbẹ lori ekun rẹ bii ọmọ ile ẹkọ.

Idahun si ibere yii wa ninu ibaṣepọ ọjọ pipẹ laarin awọn mejeji ati eto oṣelu ipinlẹ Eko.

Ọpọ lo gbagbọ pe Gbajabiamila ni baba isalẹ Elliot ninu oṣelu ipinlẹ Eko, paapaa ninu oṣelu agbegbe Surulere.

Ọdun 2015 ni wọn kọkọ dibo yan Elliot sile aṣofin ipinlẹ Eko, ki wọn to tun fi ibo gbe wọle lọdun 2019 ati ọdun 2023.

Amọ idarudapọ bẹrẹ laarin awọn oloṣelu mejeji lẹyin ti awọn ọmọ ile aṣofin naa yọ abẹnugan rẹ, Mudashiru Obasa, bi jiga ninu oṣu Kinni, ọdun 2025.

Ipa ti ọrọ Obasa ko laarin Elliot ati Gbajabiamila

Lẹyin ti igbiyanju lati yọ Obasa nipo fori ṣọpan, iroyin ni Gbajabiamila sọ pe diẹ lo ku ki igbesẹ ọhun ṣakoba fun oun gẹgẹ bii olori oṣiṣẹ Aarẹ.

Gẹgẹ bo ṣe, Aarẹ Bola Tinubu gbọ pe Elliot wa lara to n lewaju bi wọn yoo ṣe yọ Obasa nipo, eyii ti ko dun mọ Aarẹ ninu.

Ṣaaju ni Gbajabiamila ti kọkọ gbe lẹyin Elliot pe ko mọ nipa rẹ, amọ lẹyinorẹyin, o kilọ fun ko jawọ ninu 'iditẹ' naa to ba mọ nipa rẹ.

Nigba ti Elliot yoo fesi, o ni kii ṣe ohun lo wa nidi iyọnipo Obasa, ati pe oun ko si ni Naijiria lasiko ti awọn aṣofun ẹgbẹ oun n tọwọ bọwe lati yọ ọ nipo, niṣe loun naa kan tọwọ bọwe ọhun nigba ti awọn akẹgbẹ oun ti tọwọ bọ ọ ṣaaju ki oun to ti ajo de.

Iṣẹlẹ naa ni a gbọ pe o fa ija laarin awọn oloṣelu mejeji.

Eto idbo ẹkun Surulere

Iroyin ni ede aiyede aarin awọn mejeji tunbọ buru si lẹyin ti Elliot gbe apoti lati pada sile aṣofin naa lati ṣoju ẹkuun Surulere.

A gbọ pe kaka ki Gbajabiamila gbe lẹyin Elliot gẹgẹ bii iṣe rẹ ṣaaju, niṣe lo yan lati ṣatilẹyin fun Barakat Odunuga-Bakare, to jẹ agbẹjọro ati oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Eko tẹlẹ.

Elliot kọ lati ju ọwọ silẹ fun Barakat, o si tẹsiwaju ninu eto idibo abẹnu ẹgbẹ naa ko le dije.

Nigba ti esi yoo jade, Elliot lulẹ pẹlu ibo 270 nigba to Barakat Odunuga-Bakare ni ibo to le ni 11,000.

Idi ti Elliot fi n bẹbẹ bii ọmọ ile ẹkọ

Lẹyin esi ibo yii ni a gbọ pe Elliot bẹrẹ si n bẹ Gbajabiamila to jẹ ọga fun ninu oṣelu, to si bẹrẹ si n pe e 'baba' ati 'ẹgbọn.'

Ọpọ lo gbagbọ pe Elliot n kunlẹ fun Gbajabiamilla nitori agbara to ni ninu oselu nipinlẹ Eko ati ibaṣepọ rẹ pẹlu Aarẹ Tinubu.

Awọn kan tilẹ n sọ pe ti Elliot ko ba fi ẹnu gbolẹ niwaju awọn 'baba rẹ ninu oṣelu' ọhun, o ṣeeṣe ki wọn pa irawọ rẹ ninu oselu ipinlẹ Eko ko si di ẹni to n pada si oko tiata ṣiṣe.

Bo tilẹ jẹ pe a ko le fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni Elliot dalẹ Gbajabiamila, ẹkọ fi oju mimu han pe Elliot ti tẹ aṣọ agba mọlẹ ninu oṣelu ipinlẹ Eko lo ṣe n bẹbẹ lori ekun rẹ.