NCDC ṣàwári èèyàn méjì tó ṣeéṣe kí wọ́n ní àrun ebola

Awọn olutọju awọn alaarun ebola
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba Naijiria ti kede pe oun ti ṣawari eeyan meji ti wọn fura si pe o ṣeeṣe ki wọn ni arun ebola.

Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun ni Naijiria, NCDC, sọ pe apa ariwa ni wọn ti ṣawari awọn eeyan naa.

Iroyin yii lo n jade lẹyin ti wọn gbe obinrin kan ati ọkọ rẹ lọ si orilẹede Switzerland lẹyin ti obinrin naa lugbadi arun ọhun.

Atẹjade kan lati orilẹede naa fidi rẹ mulẹ pe obinrin naa n gba itọju nile iwosan Geneva University Hospital, nigba ti ọkọ rẹ n gba itọju nile iwosan mii.

Tọkọtaya naa, ti wọn jẹ ọmọ orilẹede Switzerland ni wọn jọ fi Naijiria silẹ lọjọ Aje, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 yii.

Wayi o, NCDC ti sọ pe ko tumọ si pe awọn eeyan meji ti a n sọrọ wọn yii ti ni arun naa o, amọ wọn yoo fidi ipo ti wọn wa mulẹ lẹyin ti wọn ba pari ayẹwo ti wọn n ṣe fun wọn lọwọ tan.

Ajọ ọhun sọ siwaju si pe awọn ti ya awọn mejeji sọtọ fun itọju ati ayẹwo, iṣẹ si ti bẹrẹ lati ṣawari gbogbo awọn eeyan mii ti wọn ti ba wọn pade lẹnu lọlọ yii.

Wọn ni awọn yoo maa bun araalu gbọ nipa awọn eeyan naa lẹyin iwadii awọn.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ẹnu lọlọ yii ni ijọba kede pe oun ya owo ti iye rẹ to biliọnu mẹwaa naira sọtọ lati gbogun ti arun ebola.

olutọju arun ebola

Awọn onimọ sọ pe awọn apẹrẹ arun naa le kọkọ fara jọ iba lasan ko to bẹrẹ si n gbọna mii yọ.

Ajọ NCDC ti kede awọn apẹrẹ ti arun ọhun ṣaba maa n fi lede ati ohun ti awọn araalu le ṣe lati dena rẹ layin kan wọn.

Ọdun 2014 ni ebola kọkọ ṣuyọ ni Naijiria lẹyin ti ọkunrin kan, Patrick Sawyer, balẹ si papakọ ofurufu ilu Eko lati Liberia.

Arun naa ṣekupa eeyan mẹjọ lọdun naa lọhun amọ ijọba tete kapa rẹ ko di ohun to n ran gbogbo ilu.

Arun Ebola buru to bẹẹ to le gbẹmi eeyan laarin ọjọ mẹfa si mẹrindinlogun lẹyin to ba ti n fi apẹrẹ han.

Lara awọn orilẹede Afrika ti Ebola ti n ṣọṣẹ lọwọ yii ni Kenya ati DR Condo, nibi to ti gbẹmi eeyan to le ni irinwo.

Ki ni awọn apẹrẹ arun ebola?

Oniruru awọn apẹrẹ ni abola maa n fi han to ba kọlu eeyan.

Gẹgẹ bii atẹjade ajọ NCDC, lara awọn apẹrẹ ebola ni iba, ara rirẹ ju bo ṣe yẹ lọ, iṣan ara riro, ori fifọ, ọfun to n dun eeyan, eebi ati igbọnsẹ gbuuru.

Arun naa tun le mu ki inu maa dun eeyan, ki ifun ati ẹdọforo eeyan si tun kọṣẹ.

Ajọ WHO ni arun naa le wa lagọ ara eeyan laarin ọjọ meji si ọjọ mejilelogun ko to bẹrẹ si n farahan.

Bi o ṣe le dena arun ebola

Lara awọn ọna lati dena arun ebola gẹgẹ bii ajọ NCDC ṣe sọ ni fifọ ọwọ rẹ pẹlu omi ati ọṣẹ loorekoore, paapaa ti o ba gbọnsẹ tan.

Ṣọra fun omi ara ẹni to ni arun naa; lara omi ara bẹẹ ni itọ́, ìtọ̀, ẹjẹ ati igbọnsẹ wọn.

Da ara rẹ lẹkọọ nipa awọn apẹrẹ ebola ki o le mọ bi o ṣe le tete yẹra fun.

Tẹlẹ imọran awọn eleto ilera ti o ba ni nnkan lati ṣe pẹlu ẹni to ni arun naa.

Ṣọra fun fifi ọwọ kan awọn ẹranko to ti ku bii adan.

Yẹra fun pinpin awọn nnkan ti omi ara ẹlomii n kan bii aṣọ, abẹrẹ atawọn nnkan mii.

Ma ṣe itọju ẹni to ni ebola funra rẹ lai kii ṣe onimọ eto ilera tabi lai ni imọ itọju alaarun naa ṣaaju.

Ẹwẹ, ajọ WHO kede awọn abẹrẹ Ervebo ti ileeṣẹ Merck & Co. ṣe, to fi mọ Zabdeno ati Mvabea ti Janssen Pharmaceutica ṣe gẹgẹ bii awọn abẹrẹ ajẹsara rẹ amọ awọn abẹrẹ naa ṣọwọn.