Seyi Makinde ni yóò ṣojú wa nínú ètò ìdìbò Ààrẹ ọdún 2027 – Ẹgbẹ́ òṣèlú APM

Oríṣun àwòrán, Adelaja Adeoye
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ni ẹgbẹ oṣelu Allied Peoples Movement (APM) ti fontẹ lu gẹgẹ bii ẹni ti yoo dije du ipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu ọhun lọdun to n bọ.
Ikede yii lo waye nibi eto idibo abẹlẹ ẹgbẹ oṣelu naa to waye ninu gbangan ọmọwe agba Theofilus Ogunlesi to wa ni adojuko ile iwosan UCH, nilu uIbadan.
Ṣaaju, Yusuf Dantale ẹni ti o jẹ alaga agba fun ẹgbẹ oṣelu APM atawọn alaga ẹgbẹ oṣelu naa kede wi pe Seyi Makinde ni gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ọhun fọwọ si gẹgẹ bii ẹniti yoo dije du ipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ ọhun.
Lẹyin eyi ni alaga ẹgbẹ oṣelu APM fi iwe ẹri oludije ti ẹgbẹ oṣelu naa fun gomina Seyi Makinde.
"Makinde to gbangba sun loyẹ"

Ṣaaju ni igbakeji gomina ipinlẹ Bauchi, Mohammed Jatau ti kọkọ kọrin ki gomina Makinde gẹgẹ bi ẹniti o nifon ni eekana lati dije du ipo Aarẹ orile-ede yii.
O ni pẹlu bii idagbasoke nla ṣe ba ipinlẹ Oyo, paapaa julọ bi awọn opopona ipinlẹ Oyo ṣe rege, to fi mọ awọn idagbasoke miran to ba ipinlẹ Oyo, o fi han pe Seyi Makinde yoo ṣe daadaa to ba di Aarẹ Orilẹ-ede Naijiria.
Oludije fun ipo gomina labẹ asia APM nipinlẹ Oyo, Adelaja Adeoye ninu ọrọ ikinni rẹ ni idagbasoke ti orilẹ-ede yii nilo ko le wa lai ṣe wi pe gomina Makinde di Aarẹ Naijiria.
Adelaja ni isẹ takuntakun ti Seyi Makinde ti ṣe ni ipinlẹ Oyo ti fi han wi pe o to gbangba sun loyẹ.
Mo ṣetan lati mu atunto ba Naijiria – Makinde
Ninu ọrọ rẹ, gomina Seyi Makinde ni bi inu oun ṣe dun to lati gba asia ẹgbẹ oṣelu APM gẹgẹ bi ẹni ti yoo dije du ipo Aarẹ, eto Naijiria, paapaa julọ ti ipinlẹ Oyo kọ oun lominu.
Makinde ni aisi ifọkanbalẹ, ọwọngogo epo, ebi, aisi aabo to peye wa lara iṣoro ti ọpọ ọmọ Naijiria n koju.
O ni "Igbesẹ miran gbọdọ bẹrẹ, bi mo ṣe n ba yin sọrọ bayii, awọn ọmọ ile ẹkọ ti ko mọwọ-mẹsẹ wa ni igbekun awọn agbebon lọwọlọwọ.
"Gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Oyo ati olori alaabo ipinlẹ Oyo, mi o ni agbara patapata lori awọn oṣiṣẹ ajọ alaabo, eyi lo si faa ti mi o le fi ja ija aabo ilu bo ṣe yẹ.
" Mo ṣeleri lati ṣe atunto to yẹ, paapaa julọ nipa ọrọ aabo ti mo ba di Aarẹ Naijiria.
"Mọ ṣeleri lati ri wi pe ounjẹ wa fun gbogbo ọmọ orilẹede yii, a o bẹrẹ lati ma ṣe akojọpọ ifitonileti lati mo bi a ṣe n pese ounjẹ kalẹ, ṣe abojuto bi ounjẹ yoo ṣe san wa ni yanturu lorilẹede yii."


























