Wo orúkọ gbogbo àwọn ọmọ ogun àti ọlọ́pàá tó kú sínú ìgbìyànjú láti dóòlà àwọn olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ Oriire

Aworan bata ati fila awọn ologun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba ti kede orukọ awọn ẹṣọ alaabo ati ọmọ ogun ti wọn padanu ẹmi wọn lasiko ti wọn doola awọn akẹkọọ ati olukọ ti agbesunmọmi ji gbe ni ijọba ibilẹ Oriire, nipinlẹ Oyo.

Ikede yii n ṣfihan pe ko rọrun lati gba awọn eeyan naa lakata agbesunmọmi ati pe awọn kan lo fi ẹmi ara wọ lelẹ fun awọn eeyan ọhun.

Ile igbimọ aṣofin Naijiria ni wọn ti kede orukọ awọn ologun ati agbofinro naa lati bu iyi ati iranti fun wọn.

Lara awọn to fara gbọta ibọn nibẹ ni Lance Corporal Adamu Hussain to n ṣiṣẹ pẹlu ẹka 81 Battalion ilu Ibadan.

O wa lara awọn ti ọta ibọn ba amọ o moribọ bo tilẹ jẹ pe o fara gbọta.

Awọn ọmọ ogun ati ọlọpaa to ku gẹgẹ bii ikede ile aṣofin

  • Lieutenant F. A. Isaac ti ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria
  • Private Silas Musa ti ẹka 81 Battalion, ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria
  • Sergeant Abena John Jerome ti ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria

Mọ̀ síi nípa ṣọ́jà, àmọ̀tẹ́kùn àti ọdẹ tó pàdánù ẹ̀mí wọn lásìkò ìgbìyànjú láti gba ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ Oriire

Ogagun Felix Isaac ati aworan awọn amọtẹkun kan ati ọdẹ kan to gbe ibọn rẹ soke.

Oríṣun àwòrán, screenshot/akeredolu/x/getty images

Ọpọ eeyan ti wọn ba gun ẹṣin ninu wọn ni ko ni kọ ẹsẹ lalẹ ọjọ Ẹti, ọjọ Kẹwaa, oṣu Keje bi ijọba ṣe kede gbigba itusilẹ awọn akẹkọọ ati olukọ ilẹ ẹkọ Esinele ati Yawota tawọn agbebọn ji gbe lati ọjọ Kẹẹdogun, oṣu Karun-un.

Amọ bi idunnu ṣe n ṣubu layọ paapaa fawọn idile tawọn eeyan wọn ti wa ni ahamọ awọn ajinigbe fun ọjọ mẹrindinlaaadọta, niṣe ni awọn idile kan ko sinu ibanujẹ nitori awọn eeyan wọn to ba gbigba itusilẹ naa lọ.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, awọn ẹṣọ aabo mẹwaa ọtọọtọ lo kopa ninu igbiyanju lati tu awọn eeyan naa silẹ eyi ti Ọgagun Chinedu Ralph Nnebeife ti ọga ileeṣẹ ologun Commanding 2 Division tẹka ileeṣẹ ologun.

Gomina Seyi Makinde, nigba to n sọrọ ni ọpọ awọn ẹṣọ aabo lo padanu ẹmi wọn lasiko ti wọn gbiyanju lati gba itusilẹ awọn eeyan naa.

Lara awọn ẹṣọ aabo to padanu awọn oṣiṣẹ wọn ni ileeṣẹ ologun, ẹṣọ aabo Amotekun, ọlọdẹ atawọn mii.

Makinde ni awọn ko le gbagbe awọn ẹṣọ eleto aabo, awọn ọlọdẹ atawọn ẹṣọ Amotekun nipinlẹ Oyo to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ọmogun F.A. Isaac, Ọgbẹni Adigun Shuaibu, Ọgbẹni Isa Saliu, Ọgbẹnu Rafiu Ayuba, ati ọmogun kan ti n ko mọ orukọ rẹ.

Mo tun gboṣuba fun Ọgbẹni Bamidele Paul to farapa yanayana to n gba itọju lọwọ yii,'' Makinde lo sọ bẹẹ.

Ta ni awọn to padanu ẹmi wọn?

Ọgagun Felix Ademe Isaac

Isaac Felix wọ aṣọ ogun, o n wo ẹgbẹ

Oríṣun àwòrán, Others

Ọkan lara awọn ẹṣọ aabo to padanu ẹmi wọn nibi igbiyanju awọn lati gba itusilẹ awọn akẹkọọ ati olukọ naa ni Ọgagun Felix Ademe Isaac.

Ọmọ bibi ilu Yola ni ipinlẹ Adamawa ni ọgagun naa.

Ni ọjọ Karundinlọgbọn, oṣu Kẹjọ ọdun 1997 ni wọn bii to si jẹ ẹni ọdun mejidinlọgbọn ni ko to jade laye.

Ọgagun naa padanu emi rẹ lasiko to ṣaaju awọn ọmọ ogun lati fẹ lọ gba itusilẹ awọn eeyan to wa ni ahamọ ajinigbe naa.

Oniruuru iroyin lo jade lori ohun to ṣokunfa ọgagun naa. Awọn kan sọ pe ọgagun naa padanu ẹmi rẹ nigba ti awọn agbeṣumọmi naa ju ado oloro si ọkọ tawọn Ologun naa ninu igbo Old Oyo National Park.

Awọn mii ni niṣe ni ọgagun naa tẹ ado oloro tawọn agbeṣumomi ọhun fi silẹ.

Ni ọjọ Kẹwaa, oṣu Keje ni wọn sin ọgagun naa si ilu Yola pẹlu iyi ati ẹyẹ tawọn ologun ṣe fun-un.

Ẹṣọ Amọtẹkun ati ọdẹ kan pẹlu jade laye

Bakan naa ni awọn alaṣẹ tun fi idi rẹ mulẹ pe oṣiṣẹ amọtẹkun kan ati ọlọdẹ ti wọn jọ kọkọ kan lu igbo lati ṣe awari awọn eeyan naa nigba ti wọn ji wọn gbe pẹlu jade laye.

Olukọ John Olaleye

John Olaleye wọ aṣọ olomi, o so tai pupa mọ ọrun, o n wo ọọkan

Oríṣun àwòrán, Femi Ogunlana/Facebook

Yatọ si awọn ologun ati olukọ meji ti iroyin kọkọ gbe pe awọn agbebọn to ji awọn akẹkọọ naa gbe ṣekupa amọ ti iroyin ti jade bayii pe olukọ mii tun padanu emi rẹ ni ahamọ awọn ajinigbe naa.

Ni ọjọ Aje, ọjọ Kẹtala ni iroyin jẹ jade pe olukọ mii tun padanu ẹmi rẹ nigba ti wọn wa ni ahamọ awọn ajinigbe naa.

Iroyin ni awọn agbebọn naa pa John Olaleye nitori wọn gbagbọ pe o maa tete mu ki ijọba tete dahun awọn ibeere wọn.

Niṣe ni ọpọ eeyan ti n daro iyawo, ọmọ atawọn ẹbi John Olaleye lori iku rẹ.