Wo bí epo tí Dangote fẹ́ máa tà ní dọ́là dípò náírà yóò ṣe kàn ọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ elepo Dangote ti kede pe oun yoo maa ta epo oun pẹlu owo dọla dipo owo naira ilẹ wa Naijiria.
Eyi ti mu ọpọ atotonu waye latigba ti ileeṣẹ naa ti ṣe ipinnu tuntun yii, awọn eeyan Naijiria atawọn onimọ nipa ọrọ aje lo si n kọ lominu ju lọ nipa bi yoo ṣe nipa lara kaluku wọn.
Alaye ti ileeṣẹ Dangote ṣe ni pe ayipada yii ṣe pataki nitori ohun ti okoowo n fẹ, ati nitori iyatọ to wa ninu owo naira ati tilẹ okeere lọja agbaye.
Amọ igbesẹ rẹ yii ti n mu ọlọkan-o-jọkan ibeere waye, akọkọ ni bi yoo ṣe kan iye ti wọn n ta jaala epo, owo naira ti ko ni kimi ati bi araalu to n tiraka ati jẹun yoo ṣe le fi irọrun ra epo.
Ọpọ lo n sọ pe tita epo nilana owo dọla yoo mu inira to le ba araalu Naijiria ni.
Amọ awọn kan wa ti wọn gbagbọ pe ohun ti Dangote gunle yii yoo ran ẹka epo lọwọ
Ki lo wa de gan-an ti Dangote fi gunle igbesẹ yii, ipa wo ni yoo si ni lori araalu Naijiria ni ibeere?.
Lati dahun awon ibeere yii, Ọjọgbọn nipa ọrọ aje lati ile ẹkọ giga Philomath University, Ahmad Adamu, dahun awọn ibeere yii pẹlu alaye kikun.
Ki lo kọkọ fa ayipada yii gan-an?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọgbọn Ahmad Adamu, ṣalaye pe ileeṣẹ Dangote gbe igbesẹ ati maa ta epo pẹlu owo dọla nitori awọn ayipada to ti ṣẹlẹ lọja epo Naijiria.
O ni adehun kan ti wa ṣaaju, to fi aaye gba ibi ifọpo naa lati gba lara epo ti won yoo ta pẹlu sisan owo naira, eyi to jẹ ki wọn le maa ta a ni naira.
Amọ eyi ti yipada lẹyin ti adinku ti ba epo to n wọle gẹgẹ bi Ọjọgbọn Adamu ṣe wi, eyi to ti mu ki ileeṣe Dangote maa ko ipa pataki lati ri i pe epo wa ni Naijiria.
"Nigba ti ogun Iran bẹrẹ, epo ti Naijiria n ko wọle lati ilẹ okeere dinku gan-an, ileeṣẹ epo lo n pese ida ọgọrin (80%) epo ti Naijiria n lo."
"O n gba ọpọ owo naira ju bo ṣe n gba a tẹlẹ lọ, (Dangote) eyi jẹ ki naira pọ lọwọ rẹ, amọ o nilo dọla pupọ nitori o ni awon epo rọbi kan to jẹ owo dola ni wọn fi n ra a".
Ọjọgbọn Adamu lo ṣalaye bẹẹ.
O ni ọpọ ileeṣẹ lo jẹ pe owo naira ni wọn n gba wọle, to si jẹ pe dọla to lagbara ju u lọ ni wọn n lo fi ṣe iṣẹ tiwọn.
Akọṣẹmọṣẹ lẹka ọrọ aje naa sọ pe koda ni Naijiria gan-an, awọn idunaa-dura kan wa to jẹ pe wọn ko le ma lo dọla, paapaa julọ bi wọn ba fẹ ra awọn oriṣi epo rọbi kan atawọn nnkan mi-in ti wọn nilo fun ifọpo.
Ọjọgbọn Adamu sọ pe bi Naijiria ṣe gbe ara le Dangote pupọ ju fun epo lo mu ileeṣẹ naa wa ọna ti yoo fi le maa ri dọla ti yoo fi ra epo tirẹ, ti yoo si fi maa ba igba mu ninu okoowo gbogbo to gbe dani.
Ipa ti ayipada yii yoo ni lara awọn eeyan Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹgẹ bi Ọjọgbọn Adamu ṣe ṣalaye, ayipada si dọla yii le mu ọrọ aje Naijiria ko si idaamu, nitori owo dọla gan-an jẹ ọkan lara iṣoro ti Naijiria n koju.
O ṣalaye pe nigbakigba ti dọla ba lọ soke, ti naira si lọ silẹ, ọrọ aje maa n buru si I ni, nitori owo ọja yoo gbowo leri, yoo si ṣoro fun araalu lati ra a.
Ọjọgbọn Adamu sọ pe to ba doju ẹ tan, to ba di pe dọla ni wọn fi n ra epo ni Naijiria ti wọn si fi n ta a, yoo mu ki owo ilẹ okeere naa lagbara si I, naira yoo si maa ja walẹ si i.
O ni ipa ti eyi yoo ni lori epo wa ko ni I mọ lori awọn to n ta epo kereje fun araalu, bi ko ṣe pe araalu to n ra a fun lilo ara wọn paapaa yoo fori ko o.
Bi a ba waa fi aaye gba a ko maa lọ bẹẹ, Ọjọgbọn Adamu sọ pe o le mu ki owo epo atawọn nnkan yoku wọn gogo, eyi ti yoo mu igbesi aye nira fun mẹkunnu ọmọ Naijiria.
"Iṣoro nla leyi, nitori bi a ba ti n wa dọla kiri ni yoo ṣe maa nipa lori owo ọja ati igbesi aye wa lagbegbe wa."
Ọjọgbọn Adamu lo fi kun alaye naa bẹẹ.
Bawo ni dọla yoo ṣe nipa lori iye ti wọn n ta epo ni Naijiria?
Ọjọgbọn naa tẹsiwaju pe lọwọlọwọ yii, ti a ba wo iye ti wọn n ta epo ati iye ti dọla kan jẹ, o ṣee ṣe ki lita kan jẹ iye ti dọla kan yii jẹ ti a ba ṣẹ ẹ si naira.
"Nisinyi ti wọn n ta jaala epo kan ni bii 1,300 naira, ti dọla kan si to 1,300 tabi 1,400 naira, a le sọ pe lita kan epo wa le jẹ dọla kan."
Bẹẹ ni Ọjọgbọn Ahmad Adamu ṣalaye.
O ni amọ eyi ko tumọ si pe bẹẹ ni yoo duro laelae, nitori bi dọla ba tun fi le gunke si I, bẹẹ ni owo epo jaala naa yoo ṣe gunke si i.
O ni idi niyẹn to fi ṣe pataki lati lati mojuto bi wọn yoo ṣe maa lo dọla lọja epo, nitori bi owo ilẹ okeere naa ba ṣe n ṣe si ni yoo ṣe maa kan owo naira ati igbesi aye awọn eeyan Naijiria.
Ki ni ọna abayọ?
Lati koju iṣoro yii, Onimọ nipa ọrọ aje naa sọ pe ijọba ni ipa pataki lati ko, ti wọn yoo fi yanju idaamu to ba ṣẹyọ lati ara epo ti Dangote fẹ maa ta ni dọla dipo naira yii.
O ni igbesẹ akọkọ ni ki ijọba ba Dangote sọrọ, ki wọn ri I daju pe naira lo fi n ta epo rẹ lọ, ko ma ṣe sọ ọ di dọla labẹle.
Ọjọgbọn Adamu sọ pe bi ileeṣẹ naa ba nilo dọla fun iṣẹ rẹ, ijọba le ran an lọwọ nipa ipese owo ilẹ okeere, ti Dangote yoo si maa ta epo rẹ lọ ni naira.
Eyi yoo mu wahala kuro lọrun awọn to n ra epo, paapaa lasiko yii ti naira n koju iṣoro ailagbara lọja agbaye.
O fi kun un pe ijọba ni agbara lati fi dọla ọwọ rẹ din iye epo ti wọn fi dọla ra ku.
Ọna abayọ mi-in bo ṣe wi ni ki ijọba ṣe iranwọ asiko diẹ fawọn to n ta epo kereje, kawọn naa le baa din iye ti wọn n ta a fun araalu ku.
O ni o ṣee ṣe ki eyi tako awọn ilana ijọba kan ti wọn ti la kalẹ, amọ igba mi-in maa n wa ti iṣoro ko ṣee duro wo, to jẹ gbogbo ọna to ba foju han ni eeyan gbọdọ gba lati wa ojutuu si i.
Ọjọgbọn Adamu ni kijọba boju wo gbogbo ọna ti wọn ba le gba lati ran araalu lọwọ lori idaamu to fẹ tibi epo wa yii, ki igbesi aye le rọrun fun ọmọ Naijiria.



























