Àwọn afurasí tò ṣekúpa òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì OGTV fojú ba ilé ẹjọ́, bí ìgbẹ́jọ́ ṣe lọ rèé

Awọn afurasi mẹta naa ree bi ọlọpaa ṣe ṣafihan wọn ni Eleweeran, l'Abeokuta. Wọn kọyin si kamẹra bi ofin ṣe faaye gba wọn, nitori afurasi ni wọn ṣi ka wọn si labẹ ofin titi digba ti kootu ba dajọ to si fidi ẹ mulẹ pe wọn jẹbi.

Oríṣun àwòrán, Ogun State Police Command

Àkọlé àwòrán, Awọn afurasi mẹta naa ree bi ọlọpaa ṣe ṣafihan wọn ni Eleweeran, l'Abeokuta
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Lọjọ Aje, ọsẹ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi oju awọn afurasi mẹta ti wọn ṣeku pa oṣiṣẹfẹyinti nileeṣẹ amohunmaworan OGTV, Arabinrin Kitan Oyesiku ba ile-ẹjọ.

Sodeinde Phillip, Sobu Obafunso ati Sakirudeen Ayoola ni awọn afurasi mẹta naa ti ọwọ ọlọpaa tẹ lori iku oloogbe Oyesiku.

Kitan Oyesiku ati ẹṣọ alaabo rẹ, Pelumi Adetayo ni awọn amookunṣeka naa pa nipakupa laipẹ yii niluu Kobape to wa loju ọna marosẹ Abeokuta si Sagamu.

Onidajọ ile-ẹjọ Majisireeti kẹta ti awọn afurasi naa foju ba, O. T. Odubanjo sọ pe awọn yoo duro de amọran lati ọdọ ajọ to n ri sọrọ igbẹjọ awọn ọdaran, DPP lati mọ ohun to yẹ ki ile-ẹjọ ṣe lori ẹsun naa.

Agbẹnusọ ọlọpaa, A. S. Abiodun to ko awọn mẹtẹẹta lọ siwaju ile-ẹjọ sọ pe ẹsun ti awọn fi kan awọn afurasi yii lo tako abala ẹfalelọọdun ninu iwe ofin ọdaran tipinlẹ Ogun, ti ọdun 2017.

Abiodun rọ ile-ẹjọ lati fi awọn afurasi naa si ọgba ẹwọn fun ọgọta ọjọ, titi digba ti ajọ DPP nileeṣẹ eto idajọ tipinlẹ Ogun yoo fi gbe amoran dide labẹ ofin.

O jẹ ko di mimọ pe iwe ẹsun alabala mẹrinlelogun ti awọn gbe wa siwaju ile-ẹjọ ni ASP Saka ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si iwadii ọdaran, SCID ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweran, Abeokuta buwọ lu.

O fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo awọn oniṣẹ iwadii ọdaran ti iṣẹlẹ naa kan ni wọn fi awọn ẹri mẹtadinlogun silẹ, pẹlu akọsilẹ lati ṣatilẹyin fun iwe ẹsun toun gbe wa.

Bakan lo wa rọ ile-ẹjọ lati tẹwọ gba ẹbẹ oun, leyi ti yoo jẹ ki idajọ ododo waye, ati lati jẹ ki awọn oniṣẹ iwadii pari iṣẹ wọn, ko to di pe igbẹjọ bẹrẹ ni pẹrẹu.

Lẹyin gbogbo eyi ni Onidajọ Odubanjo sọ pe o di dandan lotitọ lati jẹ ki ofin ṣiṣẹ rẹ, to si paṣẹ pe ki awọn afurasi naa wa ọgba ẹwọn didi digba ti ajọ DPP yoo fi gba wọn lamọnran lori ọna ti ile-ẹjọ yoo tọ.

A ṣekúpa òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì iléeṣẹ́ OGTV láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ni - Afurasí

Loootọ ni awọn amookunṣika ẹda kan da ẹmi sọrọsọrọ tẹlẹ nileeṣẹ tẹlifiṣan ipinlẹ Ogun, Arabinrin Kitan Ibilola Oyesiku, legbodo , amọ ọwọ ọlọpaa ti ba afurasi mẹta lori iku naa bayii.

Eyi nikan kọ, CP Bode Ojajuni ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, sọ fawọn akoroyin l'Ọjọbọ pe awon afurasi naa jẹwọ pe awon pa Kitan ati ọlọdẹ to n ṣọ ọgba rẹ, Pelumi Adetayo lati kọ iya naa lẹkọọ ni.

Awọn afurasi naa bi ileeṣẹ ọlọpaa Ogun ṣe fi orukọ wọn lede ni:

Sodeinde Olajuwon Philip; ẹni ọdun mejilelogun (22), Sakirudeen Abdulraheem Ayoola; ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ( 27) ati Sobu Obafunsho; ẹni ọdun mẹtadinlogoji (36).

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Oloogbe Kitan Ibilola Oyesiku

Oríṣun àwòrán, Kitan Oyesiku

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Kitan Ibilola Oyesiku

Lọjọ Aiku, ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹfa ọdun yii ni iroyin gbode, pe awọn eeyan kan wọ ibugbe Arabinrin Oyesiku to wa ni Owode Egba, nipinle Ogun.

Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa lo ke gbajare lẹyin tawọn eeyan naa lọ tan.

Nigba ti won wọnu ọgba ile naa ni won ba oku Pelumi Adetayo to jẹ aṣọgba lẹnu ọna, bakan naa ni oku Kitan paapaa wa ninu ile nibi ti won pa a si.

Yatọ si pe wọn gba ẹmi lẹnu awọn meji yii, awọn to ṣiṣẹ ibi naa tun gbe mọto Lexus RX300 ti i ṣe ti Oloogbe Kitan lọ.

Ọlọpaa bẹrẹ iwadii

Bi iroyin iku awọn eeyan meji naa ṣe gbode ni ileeṣẹ ọlọpaa Ogun ti dide si i.

Ọjọ Satide naa ni CP Ojajuni atawọn ikọ rẹ si de ile naa.

Nibi abẹwo ti wọn ṣe sile naa ni wọn ti ri apẹẹrẹ pe awon eeyan kan fipa wọ inu ile Oloogbe Kitan loootọ.

Nigba to n ṣalaye lori iwadii ti wọn ṣe, Kọmiṣanaa ọlọpaa Ogun sọ pe awọn pada ri mọto iya ti wọn pa naa ni agbegbe Onikolobo, niluu Abeokuta kan naa.

O ni iwe pelebe kan wa ninu ọkọ naa to ṣatọna bọwọ ṣe ba awọn afurasi mẹta yii.

"Ọjọru ni ọwọ ba Sodeinde, afurasi akọkọ to lewaju ipaniyan naa, o jẹwọ fun wa pe oun lọwọ siku Arabinrin Kitan Oyesiku- CP Ojajuni

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

CP Ojajuni ṣalaye pe ayẹwo finni-finni nipasẹ imọ sayẹnsi tawọn ṣe si iwe pelebe ti wọn kọ naa lo ṣatọna bọwọ ṣe ba Sodeinde Olajuwon Philip, afurasi akọkọ ninu ipaniyan yii.

Ojajuni sọ pe Ọjọru lọwọ ba a lagbegbe Ibara,nibi kan ti wọn ti n ṣiṣẹ ile kikọ lọwọ l'Abeokuta.

O ni nibi ti Sodeinde ti n ba wọn ṣiṣẹ lebura ni ọlọpaa ti mu un.

"Lẹyin iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ miran ni ọwọ tun ba Sakirudeen Abdulraheem Ayoola to n ṣiṣẹ aṣọgba ati Sobu Obafunsho toun n ṣiṣẹ birikila.

"Bẹẹ la ṣe fi awọn mẹtẹẹta ti iṣẹlẹ naa rọ mọ si ahamọ."

Ojajuni tẹsiwaju ninu alaye rẹ fawọn akọroyin, pe lasiko tawọn n fọrọ wa awọn afurasi naa lẹnu wo, Philip jẹwọ pe oun loun ṣeto ipaniyan naa.

"Lasiko ta a n fọrọ wa wọn lẹnu wo, Sodeinde Olajuwon Philip, jẹwọ pe oun lọwọ si iku Arabinrin Olakitan Oyesiku. O tun sọ fun wa pe oun gba Sakirudeen Abdulraheem Ayoola ati Sobu Obafunsho lati ran oun lọwọ ninu iwa ika naa.

"Gẹgẹ bo ṣe sọ fun wa, o ti ṣiṣẹ pẹlu Oloogbe Kitan ri gẹgẹ bii ọlọdẹ to n ṣọ ọgba naa.

"Sodeinde sọ fun wa pe oun pa Olakitan Oyesiku lati kọ ọ lẹkọọ kan ni."

Nipa bi wọn ṣe pa awọn meji yii, CP Ojajuni ṣalaye pe awọn afurasi naa jẹwọ pe agbara awọn ka Pelumi to wa lẹnu geeti, bawọn ṣe fi ajulọ han an tan ni awọn raye wọle sinu ile.

Lẹyin naa ni wọn pa Arabinrin Oyesiku naa sinu ile, wọn si pada pa aṣọgba naa.

Awọn nnkan ti ọlọpaa ri bii ẹri

Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun ṣalaye pe awọn ri hama kan to ti kan, ada kan, apola igi kan ati biro ikọwe to ni awọ dudu lawọn ibi tawọn ti mu awọn afurasi naa.

"Iwadii n tẹsiwaju lati fi ẹsẹ awọn ẹri mulẹ, ki igbẹjọ awọn afurasi naa si bẹrẹ ni pẹrẹwu."

Bẹẹ ni CP Bode Ojajuni ṣalaye.

O ni ileeṣẹ ọlọpaa Ogun duro ṣinṣin lorii pe idajọ ododo gbọdọ waye.

Ati pe gbogbo awọn to ba lọwọ si ọran yii yoo foju wina ofin.

Iru iṣẹlẹ yii ti waye ri l'Abeokuta

Oloogbe Kehinde ati Bukola Fatinoye ti dẹrẹba wọn pa l'Abeokuta ni 2023.

Oríṣun àwòrán, Late Mr and Mrs Fatinoye

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Kehinde ati Bukola Fatinoye ti dẹrẹba wọn pa l'Abeokuta

Tẹ o ba gbagbe, eyi kọ ni igba akọkọ ti iṣẹlẹ iṣekupani latọwọ ọmọọṣẹ yoo waye si ọga nipinlẹ Ogun.

Lọjọ akọkọ oṣu Kin-in-ni ọdun 2023 ni awọn kan ṣeku pe tọkọtaya Kehinde ati Bukola Fatinoye.

Dẹrẹba to n wa awọn lọkọlaya naa torukọ rẹ n jẹ Lekan Alabi lo pada jẹwọ pe wọn ki i ṣe oun daadaa lẹnu iṣẹ toun ti n ba wọn ṣe fun ọdun pipẹ loun ṣe ṣeto iku fun wọn.

O ni wọn ko fi kun owo oṣu oun, bẹẹ ni iṣẹ ti wọn n ran oun pọ ju owo ti wọn n san lọ.

Eyi ni Lekan ṣalaye pe o fa a toun fi lẹdi apo pọ pẹlu awọn kan, wọn si wọle to tọkọtaya naa bi wọn ṣe n de lati ṣọọṣi fun isin ọdun tuntun.

Wọn pa dumbu ọkọ, wọn si fọ hama mọ iyawo lori, wọn tun gbe ọmọ wọn ju sodo Ogun niluu Abeokuta nibi ti ọmọ naa pada dakẹ si.

Ni ti Oloogbe Kitan Ibilola Oyesiku yii naa, awọn agbofinro sọ pe apẹẹrẹ pe hámà ni wọn fọ mọ ọn lori to fi ku han.