Ìjọba àpapọ̀ wọ́gilé àfikún owó ìdánwò WAEC àti NECO tó ṣe láti ₦27,500 sí ₦50,000

Awọn akẹkọọ to n ṣedanwo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ijọba apapọ ti kede pe oun ti wọgile afikun owo ti oun fi le owo idanwo WAEC ati NECO lọdun 2027.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ijọba to n ri si eto ekọ ni Naijiria fi lede, ijọba ni oun gbe igbesẹ yii lọna ati kọkọ jiroro pẹlu awọn ti ọrọ kan lori igbesẹ ọhun.

Ileeṣẹ naa sọ pe lẹta ti awọn kọ lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹfa lati kede afikun naa lawọn ti wọgile bayii ki awọn le bojuwo ọrọ naa daadaa ki wọn to le gbe igbesẹ to gbẹyin lori rẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Boriowo Folasade sọ ninu atẹjade ọhun pe awọn gbe igbesẹ naa lẹyin ti awọn araalu yari lẹyin ikede afikun owo naa.

Nigba to n sọrọ lori eredi ijọba lati fikun owo naa, o ni ko ṣẹyin ọwọgogo to gbode.

Ijọba ni iye owo ti oun n na lori ipese ohun elo idanwo, eto abo, titẹ iwe idanwo, imọ ẹrọ atawọn nnkan mii to nilo fun aṣeyọri idanwo ọhun.

Atẹjade ijọba naa ni minisita eto ẹkọ, Tunji Alausa, ti paṣẹ ki wọn da igbesẹ afikun owo naa duro lasiko yii.

Atẹjade ileeṣẹ ijọba to n ri si eto ẹkọ

Oríṣun àwòrán, Federal Ministry of Education, Nigeria

Ohun ti Atiku sọ lẹyin ti ijọba kede afikun owo idanwo naa

Oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu ADC, Atiku Abubakar, bẹnu ẹtẹ lu afikun owo idanwo aṣejade nilẹ ẹkọ girama WAEC ati NECO si N50,000 lati ọdun 2027 to n bọ.

Atiku tun koro oju si afikun owo awọn ile ẹkọ girama ijọba apapọ ti wọn n pe ni Unity Schools.

Igbakeji Aarẹ Naijiria tẹlẹ ri ṣapejuwe igbesẹ yii gẹgẹ bi eyi to buru jai ti yoo si ni ipa ti ko dara lori awọn ọmọ Naijiria papaa julọ awọn ti ko rọwọ họri.

Iye ti a gbọ wi pe awọn akẹkọọ to ba n ṣe idanwo aṣejade yii n san fun idanwo NECO tẹlẹ ni N27,500, nigba ti wọn n san N30,000 fun WAEC.

Awọn akẹkọọ meji wọ aṣọ ile ẹkọ, Aarẹ Bola Tinubu wọ buba olomi buluu pẹlu fila; o mu ẹrọ gbohungbohun lọwọ

Oríṣun àwòrán, WAEC Nigeria/X/Asiwaju Bola Ahmed Tinubu/X

Ṣaaju ni adari eto ile ẹkọ girama ni ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si eto ẹkọ, Ọgbẹni Adeniji Ibrahim, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita wi pe ijọba gbe igbesẹ yii lẹyin ipade kan to waye laarin minisita eto ẹkọ atawọn aṣoju ajọ WAEC ati NECO.

Ọgbẹni Ibrahim ṣalaye wi pe nibi ipade yii ni wọn ti fẹnu ko wi pe o yẹ ki awọn ṣe afikun owo idanwo naa.

O ni lẹyin ipade naa ni minisita eto ẹkọ ni Naijiria sọ fun ajọ WAEC ati NECO wi pe ki wọn jẹ kawọn akẹkọọ maa san iye kan naa fun idanwo mejeeji.

Amọ, ninu atẹjade ti oludamọran igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹ ri, Phrank Shuaibu, fi sita ni Atiku ti sọ pe kii ṣe iru asiko yii ti ọwọngogo nnkan gbode ni Naijiria, ti ounjẹ gbowo lori, ti owo ọkọ gara, ti ọpọ ọdọ ko si ri iṣẹ ṣe lo yẹ ki ijọba Aarẹ Bola Tinubu ṣe afikun owo idanwo WAEC ati NECO.

Atiku ni igbesẹ yii yoo fi ẹtọ lilọ sile ẹkọ to jẹ ojuṣe ijọba dun ọpọ ọmọ Naijiria.

''Kii ṣe asiko yii ti Naijiria wa lara awọn orilẹede tawọn ọmọde ti ko si nile ẹkọ ti pọ julọ lo yẹ ki ijọba ṣe afikun owo idanwo WAEC ati NECO''

Oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu ADC sọ pe nipasẹ eto ẹkọ ni ẹgbẹlẹgbẹ eeyan ti iṣẹ n ba finra ti le di eeyan laye.

''Ijọba to ba gbagbọ ni tootọ ninu ọjọ iwaju araalu ko ni dena mọ awọn eeyan lati lanfaani si eto ẹkọ to ye koororo.

Eto ẹkọ ko wa fawọn to ba lowo lọwọ nikan, ẹtọ gbogbo eeyan to jẹ ọmọ Naijiria ni.

Kii ṣe asiko yii ti orilẹede Naijiria wa lara awọn orilẹede tawọn ọmọde ti ko si nile ẹkọ ti pọ julọ lo yẹ ki ijọba tun gbe iru igbesẹ yii.

Bii miliọnu mẹẹdogun ọmọde ni akọsilẹ sọ pe wọn o si nile ẹkọ ni Naijiria.

Ni ṣe lo yẹ ki ijọba maa wa ọna lati da awọn ọmọ yii pada sile ẹkọ, ṣugbọn igbesẹ ti yoo jẹ ki iru awọn ọmọ yii maa pọ si ni ijọba apapọ n gbe,'' Atiku lo sọ bẹẹ.

Atiku fikun ọrọ rẹ pe afikun owo ile iwe girama Unity Schools naa yoo ṣakoba fun awọn akẹkọọ tawọn obi wọn ko lowo lọwọ.