Èèyàn 161 pàdánù ẹ̀mí wọn láàrin oṣù márùn ún nínú ìjàmbá ọkọ̀ l'Ogun - FRSC

Ẹṣọ ajọ FRSC duro lẹgbẹẹ ọkọ bọọsi to jona raurau

Oríṣun àwòrán, FRSC Ogun

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ ẹṣọ oju popo FRSC ti kede wi pe ko din eeyan mọkanlelọgọjọ to padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ laarin oṣu marun un ni ipinlẹ Ogun.

Ajọ naa ṣalaye wi pe ijamba ọkọ 415 lo ṣẹlẹ laarin oṣu Kinni si oṣu Karun un ọdun 2026 yii ninu eyi ti eeyan 161 ti dagbere faye.

Agbẹnusọ sọ fun ajọ FRSC ẹka ti ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Afolabi Odunsi, lo fidi ọrọ yii mulẹ fun ileeṣẹ iroyin NAN.

Ọgbẹni Odunsin fikun ọrọ rẹ pe eeyan 1,007 lo tun farapa yanayana laarin oṣiu marun un yii bakan naa.

Alukoro ajọ FRSC sọ pe adinku 79 ti ba ijamba to n ṣẹlẹ nipinlẹ Ogun pẹlu bi ijamba ọkọ 494 ti ṣe ṣẹlẹ lasiko kan naa lọdun 2025 to kọja.

Bakan naa lo tun sọ pe iye eeyan to n ku ninu ijamba ọkọ ti dinku tori eeyan 212 lo ba iṣẹlẹ ijamba ọkọ laarin oṣu marun un akọkọ ninu ọdun 2025 lọ.

O tun fikun ọrọ rẹ pe awọn eeyan to farapa naa dinku lati 1,121 si 1,007 to ṣeṣe lọdun 2026.

Ọgbẹni Odunsi ṣalaye pe adinku to ba iye eeyan to ku atawọn to farapa ko ṣẹyin ọkan-o-jọkan eto ilanilọyẹ lori iṣọra loju popo ti ajọ FRSC n ṣe fawọn awakọ ati araalu.

O ni lara awọn nnkan to maa n saba fa ijamba ọkọ ni aibọwọ fun ofin irinna, ere asaju, lilo ẹrọ ibaraẹnisọrọ nigba ti eeyan n wakọ lọwọ, ẹru akoju ti fi mọ mimu ọti wakọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O wa rọ awọn awakọ lati maa tẹle ofin oju popo ki adinku tun le ba ijamba ọkọ to n ṣẹlẹ si i.

Bakan naa ni Odunsi tun sọ pe ajọ FRSC ko ni kaarẹ nipa riri wi pe eto aabo wa loju popo ati nipa ṣiṣe ilanilọyẹ fawọn awakọ.