Ta ni Andy Burnham tó fẹ́ di Olóòtú Ìjọba Ilẹ̀ Gẹ́ẹ̀sì tuntun?

Andy Burnham wọ aṣọ dudu, ọlọpaa meji wa lẹgbẹẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, Reuters

    • Author, Becky Morton
    • Role, Political reporter
    • Author, Brian Wheeler
    • Role, Political reporter
  • Published
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gbogbo eto lo ti to bayii fun Andy Burnham lati di Olootu Ijọba ilẹ Gẹẹsi kọkandinlọgọta, lẹyin tawọn aṣofin ẹgbẹ Labour Party to n ṣejọba kede atilẹyin wọn fun un gẹgẹ bi olori ẹgbẹ naa.

Oun kọ lo maa jẹ Olootu Ijọba Ilẹ Gẹẹsi akọkọ ti orukọ rẹ n jẹ Andrew - Andrew Bonar di ipo naa mu lọdun 1922.

Amọ oun lo maa jẹ Andy akọkọ ti yoo di ipo ọhun mu.

Andy jẹ oloṣelu to ko awọn eeyan mọra, o si jẹ alaṣeyọri oloṣelu fun ọpọlọpọ ọdun ni Ilẹ Gẹeṣi.

Oun ni o maa jẹ Olootu Ijọba lati ẹkun Ariwa to maa de ipo naa fun igba akọkọ, lẹyin ti Harold Wilson di ipo naa mu laarin ọdun 1960 si 1970.

Burnham ni orukọ inagijẹ eyi ti wọn fi n pe ni Ọba Ẹkun Ariwa.

Burnham to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgọta ti n ti ipo kan bọ si omiran fun ọpọlọpọ ọdun bayii.

O gbiyanju lati jẹ olori ẹgbẹ oṣelu Labour lọdun 2010 ati lọdun 2015 nigba to ṣe ipo ṣe ipo keji si Jeremy Corbyn.

Lọdun 2017 ni o dupo adari Greater Manchester.

Ọpọ adari ijọba ẹlẹkunjẹkun ni wọn ko saba gbe sori oṣuwọn lasiko ti Burnham jẹ adari ijọba ẹkun Greater Manchester.

Andy Burnham n sọrọ nibi to ti wọ aṣo ati ṣokoto olomi buluu nibi to ti na ọwọ rẹ mejeeji sọna ọtọọtọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ibẹrẹ aye Burnham: Ololufẹ Everton ni i ṣe, o si fẹran ọrin indie

A bi Burnham lọdun 1970, o dagba ni Culcheth to ko jinna si Warrington.

Onimọ ẹrọ ni baba rẹ, iya si jẹ oṣiṣẹ to maa n duro si abawọle ileeṣẹ.

Awọn mejeeji si fẹran ẹgbẹ oṣelu Labour, nibi gan an ni Burnham ti nifẹẹ si eto oṣelu.

Burnham sọ nipa bi o ti darapọ mọ ẹgbẹ Labour lọmọ ọdun mẹrinla, lẹyin ti o wo ere ori itage kan lori ileeṣẹ BBC.

Ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Everton ni Burnham ṣe, o si tun kopa ninu ere idaraya nigba to wa nile ẹkọ.

Burnham ati buọda rẹ meji lo kọkọ lọ sile ẹkọ giga fasiti ninu ẹbi rẹ, ẹkọ nipa ede Gẹẹsi ni Burnham kọ ni fasiti Cambridge.

Olootu Ijọba Ilẹ Gẹẹsi to n lọ, Sir Keir Starmer n wo ejika Andy Burnham nibi ti wọn ti n sọrọ pẹlu awọn akẹkọọ meji

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Burnham wa lori ijokoo nigba ti Olootu Ijọba to n lọ, Keir Starmer duro

Lati ipo aṣofin si ipo adari ẹkun Greater Manchester

Burnham figba kan ri ṣiṣẹ akọroyin pẹlu iwe iroyin Tank World ati Passenger World Management, atawọn mii.

Nigba to wa ni ẹni ọdun diẹ le logun, Burnham ṣiṣẹ gẹgẹ bi oluwadii pẹlu oloogbe Tessa Jowell to jẹ aṣofin to n ṣoju ẹkun Dulwich ati West Norwood nigba naa, ẹni to pada dipo minisita mu labẹ Olootu ijọba, Tony Blair ati Gordon Brown.

O ti dipo oludamọran pataki si akọwe aṣa, Chris Smith, naa mu ki wọn to dibo yan an gẹgẹ bi aṣofin to n ṣoju ilu rẹ, Leigh ni Greater Manchester lọdun 2001.

Burnham ṣiṣẹ gẹgẹ bi minisita kekere labẹ ijọba Blair ki o to darapọ mọ igbimọ alaṣẹ ijọba gẹgẹ akọwe eto iṣura.

Andy Burnham gba bọọlu sọwọ aṣọle lasiko ere bọọlu tawọn aṣofin ẹgbẹ Labour pẹlu awọn akọroyin ni Brighton lọdun 2009

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Burnham maa n kopa ninu ere bọọlu ọlọdọọdun to maa n waye laarin awọn aṣofin Labour atawọn akọroyin oṣelu

Burnham dije lati di olori ẹgbẹ Labour lọdun 2010, lẹyin ti Brown kọwe fipo silẹ lẹyin ti ẹgbẹ Labour fidirẹmi ninu eto idibo.

Ipo kẹrin ni Burnham ṣe nigba ti Ed Miliband jawe olubori ninu eto idibo naa.

O tun gbiyanju lẹẹkan si lọdun 2015, amọ, Jeremy Corbyn la a mọlẹ.

Burnham ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba Corbyn nigba naa.

Burnham ko si lara awọn to ṣe ifẹhonuhan tako ijọba Corbyn lọdun 2016.

Amọ, o dije fun ipo adari ẹkun Greater Manchester lọdun 2017, o si wọle.

Andy Burnham bọwọ pẹlu ẹnikan to wa ninu ero lẹyin ọrọ apilẹkọ rẹ ni papa iṣere Anfield lọdun 2014.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Burnham sọrọ apilẹkọ lọdun 2014 ni papa iṣere Anfield lati ṣe ayajọ ọdun kẹẹdọgbọn iṣẹlẹ Hillsborough.

Eto igbokegbodo ọkọ nile ẹkọ ni Greater Manchester

Burnham gba oriyin fun iṣẹ takun takun ti o ṣe lẹka igbokegbodo ọkọ nigba to fi jẹ adari ẹkun Greater Manchester.

Lasiko ijọba rẹ ni ẹkun Greater Manchester di ẹkun akọkọ ni England yatọ ilu London ti ijọba ti n fi ọkọ gbe awọn akẹkọọ pada labẹ eto ''Bee Network.''

Burnham tun fẹsun kan ijọba ẹgbẹ oṣelu Conservative lasiko ajakalẹ arun Covid pe wọn o ṣe daadaa sawọn eeyan to wa lẹkun ariwa Ilẹ Gẹẹsi.

Bi o ṣe sọrọ akin yii lawọn eeyan fi fun un lorukọ ''Ọba Ẹkun Ariwa.''

Andy Burnham n wa ọkọ bọọsi olomi ọsan.

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán, Burnham maa n sọ nipa ipese ọkọ to n gbawọn akẹkọọ nile ẹkọ gẹgẹ bii ọkan lara aṣeyọri ijọba ni Greater Manchester

Ni oṣu Kinni ọdun yii ni anfaani lati pada si Westminster ṣi silẹ lẹyin ti aṣofin ẹkun Greater Manchester, Andrew Gwynne kede pe oun yoo kọwe fipo silẹ.

Eyi tumọ si pe eto idibo yoo waye ni ẹkun Gorton ati Denton.

Amọ, wọn dena mọ Burnham lati dije nigba naa.

Ninu oṣu Karun un ni nnkan yipada ti ẹgbẹ oṣelu Labour si fidirẹmi ninu eto idibo to waye ni England, Scotland ati Wales.

Bayii ni nnkan o rọgbọ mọ fun Olootu Ijọba Keir Starmer bawọn minisita kan ṣe n pe fun atunto ijọba.

Lẹyin naa ni Josh Simons kede pe oun yoo fipo oun silẹ gẹgẹ bii aṣofin Makerfield lati le jẹ ki Burnham lanfaani lati wọle aṣofin.

Oṣu keji ni BurnHam pada sile aṣofin.