Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ọkọ̀ bọ́ọ̀sì tó ṣekúpa akẹ́kọ̀ọ́ ogún

Aworan ibi ijamba ọkọ bọọsi to waye

Oríṣun àwòrán, Uganda Police Force/X

Àkọlé àwòrán, Ibi ijamba naa
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ko din ni akekọọ ogun ti wọn ti padanu ẹmi sinu ijamba ọkọ bọọsi to n gbe awọn akẹkọọ lorileede Uganda, to ṣi n ba ọpọ eeyan lọka jẹ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.

Ẹkun Ila-Oorun Uganda ni ijamba naa ti waye ni irọlẹ Ọjọbọ, ọsẹ yii.

Awọn alakoso orileede Uganda sọ pe yatọ si awọn akẹkọọ ogun ti wọn ba ijamba naa lọ, agbalagba kan ku, bẹẹ ni awọn miran tun farapa yannayanna ni agbegbe Kapchorwa.

Wọn sọ pe iṣẹlẹ naa lo buru julọ ninu iṣẹlẹ ijamba to mu ẹmi lọ, to nii ṣe pẹlu ọmọ ọmọde, eyi to ti waye lati bii ọdun pipẹ sẹyin.

Iwadii sọ pe ọkọ bọọsi naa lo da iṣẹ silẹ lojiji lori iṣẹ, leyi to jẹ ki awakọ bọọsi ọhun sọ ijanu rẹ nu lori oke ti wọn n pe ni 'Chekwatit Hill'.

Oju ọna yii ni wọn lo ti fa oniruuru ijamba fun ọpọ ọkọ to n kọja lọ, gẹgẹ bi awọn alakoso ṣe sọ.

A gbọ pe irin ajo afẹ to nii ṣe pẹlu ikẹkọọ ni awọn akẹkọọ naa n lọ, lasiko ti ijamba yii ṣẹlẹ.

Kete ti ijamba naa ti ṣẹlẹ, la gbọ pe wọn ti wọgile gbogbo irin ajo to nii ṣe pẹlu eto ẹkọ, titi digba ti iwadii yoo fi wa si opin.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Gẹgẹ bii igbesẹ lati dẹkun irufẹ iṣẹlẹ yii, a ni lati gbe igbesẹ lori eto aabo awọn ọmọ wa," Minisita fọrọ eto ẹkọ, John Chrysostom Muyingo sọ bẹẹ.

"Awakọ naa lo sọ ijanu rẹ nu, to si yiwọ kuro loju ọna, leyi to jẹ ko lọ kọlu awọn okuta to wa loju ọna naa, to si gbokiti," ileeṣẹ ọlọpaa jẹ ko di mimọ.

"O jẹ ibanujẹ wi pe ogun ọmọde, agbalagba kan to jẹ oludasilẹ ati alakoso agba, Ọgbẹni Tadeo Ssekade, ti pada si ọdọ Ọlọrun," Minisita fọrọ eto ijọba ibilẹ, Balaam Ateenyi Barugahara kọ ọ soju opo 'X'rẹ.

Fonran ti awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣafihan bi ọkọ bọọsi naa ṣe bajẹ to, pẹlu bi awọn eeyan ṣe sare lọ sibẹ lati ṣe iranwọ fun awọn ọmọde to fi ara pa.

Asiko ti awọn akẹkọọ naa n bọ lati ibi irin ajo afẹ fun irolagbara eto ẹkọ wọn ni ijamba ọhun ṣẹlẹ, ati pe wọn ti lọ si ibi igbafẹ 'Sipi Falls', awọn ileeṣẹ iroyin sọ bẹẹ.

Orileede Uganda maa n ṣe akọsilẹ ẹgbẹlẹgbẹ ijamba lọdọọdun, leyi ti ere asapajude, aile ṣabojuto ọkọ daradara, ati opopona ti ko dara maa ṣokunfa, gẹgẹ bi awọn alakoso ileeṣẹ oju popona ṣe sọ.

Ijamba to ṣẹlẹ gbẹyin lo waye lẹyin ikilọ lori aabo awọn ile-ẹkọ nipa irin ajo, lẹyin ti ọpọlọpọ ijamba ọkọ bọọsi ti waye lọsẹ diẹ sẹyin lorileede naa.