Ìjọba, ẹ bá wa ṣètò láti gbé òkú ọkọ mi wálé ká lè sin ín, ẹ sì ràn mí lọ́wọ́ lórí ètò ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ - Ìyàwó John Olaleye

Oríṣun àwòrán, Oyo Affairs
Iyawo Ọgbẹni John Olaleye to jẹ ọkan lara awọn olukọ mẹta tawọn janduku ajinigbe ṣekupa nijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso ti sọ pe ibanujẹ nla lo jẹ foun pe ọkọ oun ko si lara awọn akẹkọọ atawọn olukọ to gbominira lọwọ awọn ajinigbe.
Arabinrin naa ti wa ke pe ijọba wi pe ki wọn gbe oku ọkọ oun foun ki ẹbi le sin in.
Bakan naa tun ni iyawo oloogbe ke pe ijọba fun iranwọ lori awọn ọmọ mẹta ti oloogbe fi silẹ lọ.
Arabinrin Olaleye rọ ijọba ipinlẹ Oyo wi pe ki wọn ṣe iranwọ fun ẹbi Olaleye lori ọrọ ile ẹkọ awọn ọmọ mẹta ti oloogbe bi.
''Mo n bẹ ijọba wi pe ki wọn ṣaanu mi tori emi nikan loku bayii ti mo n tọju ẹbi.
Gbogbo nnkan ti wọn ba le ṣe lati fi ran wa lọwọ, mo bẹ ijọba wi pe ki wọn ṣe e,'' arabinrin Olaleye lo sọ bẹẹ.
O fikun ọrọ rẹ wi pe oun ko ti i gbọ nnkankan nipa aadọta miliọnu naira ti ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja kede wi pe awọn fun awọn olukọ ati akẹkọọ ti wọn bọ lọwọ ajinigbe ọhun.
Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa John Olaleye, olùkọ́ Oriire kẹta tí àwọn agbésùnmọ̀mí pa ní àhámọ́
Ọjọ Ẹti to kọja, to jẹ ọjọ kẹwaa, oṣu Keje, ọdun 2026 yii ni awọn ologun doola awọn akẹkọọ ati olukọ ti awọn agbesunmọmi ji gbe ni ijọba ibilẹ Oriire, nipinlẹ Oyo ninu oṣu Karun un, ọdun yii.
Inu ọpọlọpọ araalu lo dun lẹyin ti awọn eeyan naa pada wale.
Amọ o ṣeni laanu pe awọn agbesunmọmi ọhun ṣekupa olukọ mii, ti ọpọ araalu ko mọ.
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ pa ọgbẹni Esiyan Adegboye lasiko ti wọn ya bo ile ẹkọ wọn lọjọ karundinlogun, oṣu Karun un, ọdun yii.
Ọjọ kejilelogun, oṣu Karun un ni wọn sin oku naa nile ijọsin onitẹbọmi kan niluu Ogbomoso.
Lẹyin ti awọn eeyan naa de ahamọ ajinigbe ni wọn ge ori ọgbẹni Micheal Oyedokun, to jẹ olukọ mii, ti wọn si ka fidio iṣẹlẹ naa silẹ fun gbogbo aye lati ri.
Amọ o ṣeni laanu pe lẹyin ti awọn eeyan naa pada sile ti gbogbo mọlẹbi wọn ataraalu mii n dunnu pe wọn ti de ni a gbọ pe wọn pa ọkunrin ọhun ti araalu ko si mọ.
Gẹgẹ bii ohun ti arabinrin Rachael Alamu sọ, ọjọ Aiku, ọjọ keje, oṣu Kẹfa, ọdun 2026 yii ni wọn pa ọgbeni Olaleye si igbekun.

Oríṣun àwòrán, Matthew temitope Adewole
Ta a ni ọgbẹni John Olaleye?
Iṣẹ olukọ ni ọgbẹni Olaleye n ṣe ṣaaju iku rẹ.
O jẹ olukọ nile ẹkọ Community High School, Ahoro-Esinele, ni ijọba ibilẹ Oriire, nipinlẹ Oyo.
ọdun 2010 ni wọn gba siṣẹ gẹgẹ bii olukọ nile ẹkọ naa.
Ọkunrin naa wa lara awọn olukọ meje ti agbesunmọmi ji gbe ni Oriire.
Ẹsin Kristẹni ni oloogbe naa n ṣe ṣaaju iku ọhun, koda, diakoni ni ninu ijọ to n lọ.
Ọkunrin naa tun jẹ ẹni ti awọn eeyan n sọrọ rẹ gẹgẹ bii ẹni rere lawujọ ṣaaju iṣẹlẹ ọhun
O ni iyawo, o si ni awọn ọmọ to n duro de ipadabọ rẹ ki iroyin to gbode pe wọn ti gbẹmi rẹ si igbekun agbesunmọmi.



























