Ìdí rèé tí ẹgbẹ́ òṣèlú NDC fi gbé ipò Ààrẹ sí ìhà gúúsù lọ́dún 2027, Peter Obi ni olùdíje ààrẹ, èmi ni igbákejì rẹ̀ - Kwankwaso

Rabiu Musa Kwankwaso ati Peter Obi nibi ipde oṣelu

Oríṣun àwòrán, Meta/Rabiu Musa Kwankwaso

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ, Rabiu Musa Kwankwaso, ti sọrọ lori idi ti ẹgbẹ oṣelu NDC ṣe gbe ipo Aarẹ si iha Guusu Naijiria lọdun 2027.

Kwankwaso, ti oun ati Peter Obi fi ẹgbẹ oṣelu ADC silẹ lọ sinu NDC lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Arise.

O ni awọn yan lati gbe ipo Aarẹ naa si Guusu Naijiria lọna ati fopin si idarudapọ to n waye lori ẹkun ti ipo naa tọ si ni Naijiria.

Gomina ipinlẹ Kano nigba kan ri naa sọ pe "Ni tiwa, ohun ti a ro ni pe ki a gbe lọ si Guusu lati pa idarudapọ to n waye rẹ.

Idarudapọ yii lo bẹrẹ lẹyin iku arakunrin wa, Umar Musa Yar'Adua."

O ni "A wo nnkan to wa nilẹ a si pinnu lati gbe awọn igbesẹ kan… lati sun ipo Aarẹ si iha Guusu fun ọdun mẹrin ti yoo si pada si iha ariwa.

Rabiu Musa Kwankwaso wọ agbada fun pẹlu fila alawọ funfun ti pupa

Oríṣun àwòrán, Meta/Rabiu Musa Kwankwaso

"Peter Obi ni yoo gbe apoti ẹgbẹ NDC lọdun 2027, gbogbo ọmọ ẹgbẹ si ti faramọ"

Kwankwaso fikun pe, "Inu wa dun pe a ni awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn jẹ olootọ si ẹgbẹ, nitori naa, gbogbgo wa ti a darapọ lati iha ariwa Ia faramọ igbesẹ naa."

Kwankwaso ni pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, Peter Obi ni yoo gbe apoti ẹgbẹ naa lọdun 2027, gbogbo ọmọ ẹgbẹ si ti faramọ pe ko ri bẹẹ.

Lasiko to n sọrọ lori irufẹ ọwọ ti awọn eeyan iha ariwa yoo fi mu igbesẹ naa, o ni pupọ ọmọ Naijiria ni ko gbe ọrọ ẹsin, ede tabi ẹya lori mọ.

Amọ o ni ohun ti wọn n fẹ ni adari rere ti yoo le mu aye dẹrun fun wọn.

Kwankwaso tẹsiwaju pe, ayipada ọtun ni araalu n fẹ bayii, ayipada naa ati igbeaye idẹrun si jẹ wọn logun ju ẹya to wa lori alefa lọ.

O ni "Idi ree ti awọn eeyan ko ṣe sọ pe ẹni ti yoo di Aare gbọdọ jẹ ẹlẹsin kan naa pẹlu wọn, tabi pe o gbọdọ wa lati apa iha kan tabi o gbọdọ jẹ ẹni kukuru tabi ẹni giga.

"Ohun ti awọn eeyan fẹ ni ẹni to ja fafa lati le ṣiṣẹ ọhun ki aye le rọrun fun gbogbo mutumuwa."

Minisita fun eto abo tẹlẹ naa fi kun pe ọpọ atilẹyin lo ti wọ inu ẹgbẹ oṣelu NDC lati asiko ti awọn eekan ninu oṣelu ni Naijiria ti darapọ mọ ẹgbẹ ọhun.

Kwankwaso ni irọ ni pe ẹgbẹ naa yoo lulẹ ni iha ariwa latari pe wọn fẹ gbe oludije to jẹ ọmọ iha guusu.