Mo máa dárúkọ àwọn olóṣèlú tó ṣagbátẹrù ìjinigbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ l'Ogbomoso tí wọn kò bá jáwọ́ - Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho
Ajijagbara fun idasilẹ Yoruba Nation, Oloye Sunday Adeyemo tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, ti sọ pe oun le darukọ awọn oloṣelu ''to wa nidii'' ijinigbe awọn akẹkọọ ati olukọ ni ijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso.
Igboho sọrọ yii lasiko ti ẹgbẹ awọn akẹkọọ NANS ti Akinteye Babatunde ko sodi ṣabẹwo si i nile rẹ lagbegbe Soka niluu Ibadan.
Owo Baba Dami ṣalaye pe oun ti fi ara oun silẹ lati lọ doola awọn akẹkọọ ati olukọ to wa ni akata ajinigbe, amọ, ijọba ipinlẹ Oyo ko foun laye.
Ọgbẹni Adeyemo ni oun ko beere owo kankan lọwọ ijọba lati wọ inu igbo lọ koju awọn agbebọn.
''Ti wọn ba fun mi laye lati lọ koju awọn janduku agbebọn to n ṣọṣẹ yii, wọn o salọ.
Awọn agbebọn yii kii ṣe ṣigidi, wọn kii ṣe ẹmi airi, eeyan ẹlẹran ara bii tiwa bayii naa ni wọn.
Ti awọn oloṣelu to n ṣagbatẹru ipaniyan ati ijinigbe yii ko ba jawọ, mo maa darukọ gbogbo wọn tori mo mọ wọn.
Awọn oloṣelu to n ṣagbatẹru awọn agbesunmọmi lo n fun wọn lowo ati nnkan ija oloro.
Nnkan ti wọn ṣe fun Aarẹ Goodluck Jonathan gan an niyii, wọn da gbogbo ilu ru ki o ma baa roju raye ṣe ijọba.
Ijọba ipinlẹ Oyo sọ pe awọn ajinigbe yoo fẹmi awọn akẹkọọ naa ṣofo ti mo ba lọ koju wọn ninu igbo.
Ijọba gbọdọ gba emi atawọn ọmọlẹyin mi laye lati lọ le awọn agbebọn kuro ninu igbo, ti ijọba ba ni nnkan lati ṣe,'' Igboho ṣalaye.
Mo ní ipa tí mo lè kó láti dóòlà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso, àmọ́, Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo ni kò gbàmí láyè - Igboho

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X/Sunday Igboho/Facebook
Ajijagbara fun idasilẹ Yoruba nation, Sunday Adeyemo tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho ti sọ pe oun lagbara lati lọ gbawọn akẹkọọ ati olukọ ti wọn ji gbe l'Ogbomoso, amọ, Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ni ko foun ni iyọnd lati ṣe bẹẹ.
Igboho ni ''gomina mọ pe mo le dasi ọrọ ijinigbe awọn akẹkọọ ati olukọ ni ijọba ibilẹ Oriire, ṣugbọn ki lo de ti ko gba mi laye lati lọ ibẹ?
Mo ṣe agbekalẹ ẹṣọ eleto aabo Iru Ekun, ijọba apapọ si ti tẹwọ gba a.''
Ọgbẹni Adeyemo ni kete toun ṣe agbekalẹ Iru Ekun tan ni ijọba ipinlẹ Oyo sọ pe gbogbo ẹṣọ eleto aabo kankan ko gbọdọ gbe igbesẹ kankan lẹyin oun.
Ooṣa wa beere pe ''njẹ o nilo ka maa duro de aṣẹ lẹnu ẹnikan lati lọ koju awọn ajinigbe?
Gomina ipinlẹ Oyo mọ pe mo nipa ti mo le ko lori nnkan iṣẹlẹ ijinigbe l'Ogbomoso.''
''Mi o beere owo lọwọ ẹnikankan lati lọ koju awọn ajinigbe ninu igbo''
Sunday Igboho ni ''mo ṣetan lati lọ doola awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti awọn janduku agbebọn ji gbe l'Ogbomoso pẹlu awọn ọmọlẹyin mi.
Mi o dẹ beere owo lọwọ ẹnikẹni lati lọ koju awọn ajinigbe ninu igbo.
Nnkan ti wọn n sọ fun mi ni pe ki a ni suuru, ki ijọba fi fun wa nui iyọnda lati wọ inu igbo lọ bawọn ajinigbe.''
Igboho ni oun ko le dasi ọrọ naa bayii lai gbaṣẹ tori nnkan ti oju oun ti ri tẹlẹ.
O ni oun ko le ba ijọba ja, eyi si lo jẹ koun maa woran bayii lori ọrọ naa.
Owo Baba Dami sọ pe ko ṣeni to le ji oun gbe, bẹẹ ni wọn o si le ji awọn ọmọ oun naa gbe tori wọn o si ni Naijiria.
Ọgbẹni Adeyemo ni awọn araalu ti wọn ko ni ẹni to le daabo bo wọn loun n ja fun.
Igboho Ooṣa fikun ọrọ rẹ pe wọn ti fi ọrọ oṣelu bọ ọrọ eto aabo to mẹhẹ bayii.


























