Bọ́ọ̀lù tó ní ìmọ̀ ẹ̀rọ AI nínú làwọn agbábọ́ọ̀lù yóò lò níbi ife ẹ̀yẹ àgbáyé 2026

Fun ajọ FIFA, atinuda tuntun yii jẹ ọna kan to gbooro lati sọ iṣẹ rẹfiri di ohun ọtun pẹlu onka ti ko ruju.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Trionda, bọọlu ti wọn yoo gba nibi Ife Ẹyẹ Agbaye 2026.
    • Author, Ousmane Badiane
    • Role, Digital Journalist BBC Afrique
  • Published
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Bi eeyan ba kọkọ wo o, Trionda, iyẹn bọọlu ti wọn yoo gba nibi idije Ife Ẹyẹ Agbaye ọdun 2026 yii, dabii awọn bọọlu ẹgbẹ rẹ lasan. Amọ labẹ rẹ ni imọ ẹrọ to le mu ayipada tuntun de ba itan idije Ife Ẹyẹ Agbaye wa.

Bọọlu ti wọn ti fi aṣẹ gbe kalẹ pe oun ni wọn yoo gba nibi idije Ife Ẹyẹ Agbaye ọdun 2026 yii ti wọn n pe ni Trionda, ni akọkọ iru rẹ ti wọn yoo ṣe to mu imọ ẹrọ AI sunmọ awọn agbabọọlu timọtimọ, atẹlẹsẹ awọn agbabọọlu naa lo wa.

Ileeṣẹ Adidas lo gbe e kalẹ, o ni kinni kan to n ṣe odiwọn bo ṣe n yi rondo si, ati eyi ti yoo ṣe onka iṣẹ to n lọ lara rẹ ni ida ẹẹdẹgbẹta laaarin iṣẹju kan (500 data points per second). Gbogbo bi wọn ba ṣe n gba a sira wọn ati bi wọn ṣe n gba a ni ti oloke, pẹlu bo ba ṣe n lọ silẹ si ni onka rẹ n foju han lai ruju rara.

Erongba to wa nidii eyi naa ko ruju rara: lati fun awọn rẹfiri ati ẹrọ fidio lanfaani lati ri ohun to ba n ṣẹlẹ laaarin awon agbabọọlu ati bọọlu ti won n gba lorii papa lẹsẹkẹsẹ ni.

Imọ ẹrọ to wa lara bọọlu yii ki i ṣe pe o fi gbogbo ara jẹ tuntun. Wọn ti kọkọ ṣafihan rẹ nibi idije Ife Ẹyẹ Agbaye ọdun 2022, ni Qatar, pẹlu bọọlu Al Rihla. Ṣugbọn Adidas loun ti tẹsiwaju ninu iṣẹ bọọlu Trionda yii ju ti tẹlẹ lọ.

Ninu atẹjade kan, ileeṣẹ to n pese awọn irinṣẹ nilẹ Germany yii ṣalaye pe irinṣẹ IMU to wa nibẹ ni oun ti gbe sinu ọkan lara ẹka bọọlu naa, pẹlu lilo ilana tuntun.

Wọn ni eyi wa fun lati jẹ ko duro digbi, ko si ma yẹ nigba ti wọn ba gba a si ofurufu. Kika ohun to n ṣẹlẹ silẹ ko din ni ẹẹdẹgbẹta laarin iṣẹju aaya kan bi wọn ṣe sọ, ṣugbọn yoo ka a lọgan lai ṣe aṣiṣe.

Fun ajọ FIFA, atinuda tuntun yii jẹ ọna kan to gbooro lati sọ iṣẹ rẹfiri di ohun ọtun pẹlu onka ti ko ruju. Ajọ to n ri si ọrọ bọọlu yii sọ pe oun gbagbọ pe eyi yoo mu ki igba ti agbabọọlu kan fi ọwọ kan bọọlu han, o si ṣe pataki to ba di ti pe wọn fẹẹ pinnu bọọlu to bọ si ẹyin agbo.

Ife Ẹyẹ Agbaye ti ọdun 2026 yii, ti United States, Canada ati Mexico yoo gba alejo rẹ ki i ṣe pe o tobi ju ninu itan nikan, ti ikọ mejidinlgoji (48) n kopa ninu rẹ, amọ o tun le jẹ ibẹrẹ lilo imọ ẹrọ AI lagboo bọọlu afẹsẹgba lagbaaye.

Lẹyin ti wọn bẹrẹ si i lo imọ ẹrọ lati mọ aala oju ile ati ti fidio ti a mọ si VAR, pẹlu eyi ti wọn n pe ni ''semi-automatic offside'', FIFA ti n gbe ara le akojọpọ awọn ẹrọ to n ṣe onka bayii, pẹlu kamẹra ayaworan ti yoo tun maa ṣe akọsilẹ bi ere bọọlu ṣe n lọ, kawọn rẹfiri le tete ṣe ipinnu to gunrege lai ni abawọn kankan.

Lara awọn ọgbọn inu to ṣee gboriyin fun ni Trionda, bọọlu ti wọn yoo fi gba Ife Ẹyẹ Agbaye nibi idije naa.

Ilana imọ ẹrọ tuntun to yi eré pada

Ọgbọn inu n tẹsiwaju pẹlu agbekalẹ awọn bọọlu to n lo imọ ẹrọ.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba ti agbabọọlu kan ba gba a si ẹnikeji, to fọwọ kan bọọlu tabi to gbe e gba ibomi-in, lọgan ni wọn yoo ti tẹ ẹ soju opo fidio ti yoo gbe e jade.

Bẹẹ ni bọọlu yii di orisun iroyin ati ikede, to si le ran ohun ti kamẹra ka silẹ lorii papa lọwọ.

Ti a ba fi oju inu wo o, imọ ẹrọ ti wọn ṣe sinuu bọọlu yii fun un ni anfaani lati sọ ohun to ba kiyesi lẹsẹkẹsẹ, laaarin ibi ti nnkan ohun ti n ṣẹlẹ, yoo sọ asiko pato ti agbabọọlu fọwọ kan an.

Bawọn to gbe e kalẹ ṣe sọ, yoo tun tete maa ri awọn ibi kọlọfin ti bọọlu ba gba, eyi ti oju lasan le ma ri i.

Ilana yii tun n ṣeranwọ lati mọ awọn ohun to ba ṣoro lati fidi ẹ mulẹ lati ibi aworan fidio nikan. Gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe bọọlu naa, riri nnkan lai ruju yii yoo mu otitọ ati okodoro han ninu iṣẹ awọn rẹfiri.

Yatọ si imọ ẹrọ to ko sinu, Trionda tun yatọ pẹlu bo ṣe ni atẹ mẹrin to n gba ooru mọra ti wọn ti jó mọ ara rẹ wa, iru rẹ ko pọ ninu idije Ife Ẹyẹ Agbaye gẹgẹ bi FIFA ṣe wi.

Wọn ni awọn atẹ bọọlu naa wa fun ko duro rẹgi bi wọn ba gba a soke, ati bi wọn ba dari rẹ gba ibo mi-in lọ.

Iranlọwọ fun idajọ ti ko ṣègbè

Bọọlu Trionda naa ree ti rẹfiri kan mu dani.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ninu awọn idije agbaye to ti kọja lọ, wọn ti lo awon nnkan elo to jọ bayii ri lati ran awọn rẹfiri lọwọ. Ṣugbọn ti Trionda yii tun gbe igbesẹ kan tayọ tawọn iṣaaju. Eyi ri bẹẹ pẹlu bo ṣe ni irinṣẹ to le tete ka ohun to n lọ silẹ ti yoo si gbe e jade.

Fun awọn rẹfiri to n lo fidio, bọọlu ti di afikun ọna lati mọ ohun to n lọ, to n kun awọn aworan ti wọn ba ya lọwọ pẹlu ọpọ kamẹra to wa ni papa iṣere.

Koko rẹ naa ni lati din aṣiṣe awọn rẹfiri ku, ki ipinnu ṣiṣẹ si ya kankan.

Yatọ si tawọn rẹfiri, Trionda tun le yi oju ti kaluku fi n wo idije pada. Awọn ohun ti wọn ba ko jọ lorii papa yoo tete di mimọ.

Fun awọn akọnimọọgba, awoye ati awọn to n ṣiṣẹ iwadii lorii ere idaraya, ohun ti wọn ba mu jade bii akọsilẹ yii yoo ṣe iranwọ lati mọ bi agbabọọlu kan ṣe kopa si, ati ọgbọn inu ti wọn ba lo lorii papa.

Ni ipari, wọn le ṣeranwọ fun ẹkọ nipa bọọlu gbigba, yoo si tun ran agbabọọlu kọọkan ati apapọ wọn lọwọ nipa ṣiṣẹ daadaa si i ninu ere naa.

Amọ imọ ẹrọ to de yii tun ni awọn ibeere kan to mu lọwọ lati wa esi si. Fun igba wo ni imọ ẹrọ yoo lọwọ si ere idaraya tawọn eeyan n fi ọpọlọ tu da?

Ohun kan tawọn eeyan n sọrọ le lori nipa fidio to n ka ohun to ba ṣẹlẹ lorii papa silẹ 'Video Assistant Refereeing' (VAR) ni pe oju ti kaluku fi n wo o ko jọra wọn, o si n mu iyapa ẹnu wa lawujọ ere bọọlu afẹsẹgba.

Bi ayipada ṣe ti ba awọn bọọlu ti wọn lo nibi Ife Ẹyẹ Agbaye lati 2002

Awọn bọọlu ti won ti fi gba idije Ife Eye Agbaye lati 2002 ti Adidas ṣe, ti ọkọọkan wọn si ni amuyẹ imọ ẹrọ ọtọọtọ.

Oríṣun àwòrán, FIFA

Awọn bọọlu ti won ti lo fun idije Ife Ẹyẹ Agbaye lati ọdun diẹ sẹyin n jẹ kawọn to n ṣe wọn maa gbe imọ otun jade lori rẹ si i ni.

2002: Fevernova (South Korea-Japan)

Bọọlu yii ti wọn pe ni Fevernova ni wọn fi awọ dudu ati funfun dara si. Bo ṣe rẹwa naa ni wọn fi ṣapejuwe idanimọ Asia nibi idije naa.

Irisi: O ni atẹ mẹtalelọgbọn ti wọn ṣe mọ ọn.

Atinuda: Fukẹfukẹ to n mu ko rọrun lati fọwọ kan, sare tete.

2006: Teamgeist (Germany)

Ayipada imọ ẹrọ to ju ti iṣaaju lọ.

Irisi: Atẹ mẹrinla pere ni wọn ṣe mọ ọn.

Atinuda: o n dan ju ti akọkọ, o si ri rondo, o n jẹ ko rọrun lati ma ṣe tase ibi ti wọn ba gba a si.

2010: Jabulani (South Africa)

Eyi lo fẹrẹ jẹ bọọlu ti awuyewuye tori rẹ waye ju ninu itan igbalode bọọlu.

Irisi: Atẹ mẹjọ pere lo ni.

Atinuda: o ṣe e gba soke ko duro digbi, o si ṣee sun si igun.

Ọpọ amule atawọn agbabọọlu ni wọn sọrọ nipa bo ṣe n yi, wọn ni awọn ko le sọ pe ibi bayii ni yoo balẹ si tabi gba lọ.

2014: Brazuca (Brazil)

Wọn gbe e kalẹ lẹyin ayẹwo finni-finni latọdọ awọn akọṣẹmọṣẹ agbabọọlu

Irisi: Atẹ mẹfa to jọ ara wọn.

Atinuda: o yara kankan lofurufu, o si ṣee dari kia.

Kari aye ni wọn ti n gboriyin fun un, dipo Jabulani.

2018: Telstar 18 (Russia)

Wọn pada si aye orukọ to ni itumọ kan si ọpọ eeyan;Telstar.

Irisi: Atẹ mẹfa.

Koko atinuda rẹ: wọn fi kinni kekere kan ti wọn pe ni "NFC chip" sinu rẹ, eyi to jẹ ko ṣee ṣe fun awọn to waa ṣatilẹyin nibi ti wọn ti n woran lati maa nipa lilo foonu.

2022: Al Rihla (Qatar)

Eyi ni bọọlu to ya kankan ju ti wọn lo ri ni idije Ife Ẹyẹ Agbaye, gẹgẹ bi Adidas ṣe sọ.

Irisi: Atẹ ogun.

Atinuda: Wọn fi irinṣẹ IMU to n gbe ohun to ba n ṣẹlẹ jade lasiko si i, o si le mọ bọọlu to ba bọ si ẹyin agbo papa iṣere lọ.

2026: Trionda (United States, Canada, Mexico)

Eyi ni tuntun to de wayi.

O ni amuyẹ ara ọtọ lai wuwo rara.

Atinuda: o le pin ẹẹdẹgbẹta isọri ohun to n ṣẹlẹ laaarin iṣeju perete kan, o si tun fi aaye gba imọ ẹrọ AI ati fidio ayaworan to n ṣeranlọwọ.

Bọọlu yii kuro ni nnkan agbaṣere lasan, o ti di nnkan imọ ẹrọ to le maa ba awọn rẹfiri ati ẹrọ sọrọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Agbabọọlu ọmọ ilẹ Argentina ree

Ni ida kan ninu mẹrin sẹnturi, awọn bọọlu ti wọn n lo ni Idije Ife Ẹyẹ Agbaye ti kuro ni nnkan iṣere lasan, o ti yipada si imọ ẹrọ to le pese alaye ti yoo si tun gbe e jade loju ẹsẹ.

Ikọọkan idije Ife Ẹyẹ Agbaye ti fi idagbasoke tiẹ han, nigba mi-in wọn yoo gba oriyin, igba mi-in si wa ti yoo ba ariyanjiyan de, bawọn to n ṣe bọọlu naa ṣe n mu tuntun jade siwaju si i.

Pẹlu awọn bọọlu asiko yii to n gbe ohun to n ṣẹlẹ jade kia, o jọ pe aṣeyọri to lọọrin ti waye. Ife Ẹyẹ Agbaye ti 2026 yii, Trionda, ṣafihan bi ayipada ṣe ti ba de to .

Bẹẹ ni ohun gbogbo n tọka si pe imọ tuntun ko duro: awọn ọdun to n bẹ niwaju tun le mu tuntun to tun le ju ti asiko yii lọ jade, ti yoo maa fun imọ ẹrọ atinuda ni igbega labala bọọlu afẹsẹgba.