Iléeṣẹ́ ológun kéde àwọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ gbé ní ìpínlẹ̀ Oyo, ọlọ́pàá ní àwọn tí wọ́n jí gbé ṣì wà ní àhámọ́

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọmọogun alaabo orilẹede Naijiria ti ṣalaye wipe awọn agbebọn ti awọn ọmọogun fi ina ija le kuro lawọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria ni wọn wa nidi ijinigbe to waye laipẹ yii ni ipinlẹ Ọyọ.

Ileeṣẹ ọmọogun alaabo lorilẹede Naijiria ṣalaye yii lasiko ti wọn fi n fesi si wọn atẹjade kan to n lọ kaakiri pe ileeṣẹ ọmọogun alaabo sọ ọrọ kan ninu eyi to ti n ṣe iyasọtọ awọn agbesunmọmi atawọn ọdaran to n ṣọṣẹ lẹkun iwọ oorun gusu Naijiria.

Ninu atẹjade kan to fi sita, alukoro ileeṣẹ ọmọ ogun alaabo, Ọgagun Michael Onoja ṣalaye pe awọn awọn ọmọ ẹgbẹ agbebọn Jama'atu Ahlis Sunna Lidda'awati wal-Jihad tawọn ọmọogun Naijiria fi ina ibọn le kaakiri awọn agbegbe ti ina ibọn awọn ologun ti n ro lakọlakọ lorilẹede Naijiria.

"O han kedere pe awọn agbesunmọmi ẹgbẹagbesunmọmi JAS ti awọn ologun ti fi ina fin kuro lawọn agbegbe kan lorilẹede yii ni wọn wa nidi ikọlu ijinigbe to waye ni ipinlẹ Ọyọ."

Ileeṣẹ ọmọogun alaabo ni Naijiria sọ pe irọ ni iroyin to n wi pe awọn ileeṣẹ ologun n sọ pe awọn ọdaran lasan lawọn to n ṣọṣẹ ni ẹkun iwọ oorun gusu Naijiria.

O ni ko si igba kankan ti ileeṣẹ ologun pe awọn agbebọn to n ṣọṣẹ ni ipinlẹ Ọyọ.

Iroyin ofege lo n lọ kaakiri pe awọn ọmọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe ti gba itusilẹ - Ọlọpaa

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ ti kede pe irọ ni iroyin kan to n kaakiri pe awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn jigbe ni ijọba ibilẹ Oriire ti gba itusilẹ. O ni awọn ọlọpaa atawọn agbofinro yooku gbogbo ti n gbe igbesẹ gbogbo to yẹ lati gba itusilẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni irọ lasan lawọn to n gbe iroyin naa n gbe kiri ati pe iroyin ofege ni.