You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Rògbòdìyàn ìdìbò 1983 kó wàhálà tó pọ̀ bá ẹbí mi nítorí bàbá mi díje, ṣùgbọ́n ìfẹ́ àráàlú ló mú mifẹ́ di gómìnà Ekiti'
Ohun tójú ẹbí mi rí nídìí òṣèlú kìí BBC News Yoruba ba oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ekiti labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọgbẹni Wọle Oluyẹde sọrọ lori eto idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ekiti ti yoo waye ni ogunjọ oṣu kẹfa.
Ọgbẹni Oluyẹde ṣalaye pe aiṣedaada to awọn to wa nipo akoso ni ipinlẹ Ekiti lo mu ki oun gbimọran lati fẹ dije ipo gomina ni ipinlẹ naa. O ni ohun ti oju oun ati idile oun ri lasiko ti baba oun fi ṣe oṣelu ni ni igba aye rẹ ti mu ki oun dẹyẹsi ohunkohun to ba nii ṣe pẹlu oṣelu.
O ni ohun ti oju awọn mọlẹbi oun ri nitori pe baba oun dije fun ipo oṣelu lọdun 1983 ko jẹ ki oun fi gbogbo ara kọbiara si oṣelu ṣiṣe.
O ni Baba oun dije fun ijoko ile aṣofin ipinlẹ lọdun 1983, awọn rogbodiyan to wọ tọ̀ idibo naa lẹyin da apa ti ko ṣee gbagbe laelae si ara idile oun. O ni wọn jo ile awọn, wọn fẹ dana sun ẹgbọn oun ki awọn ẹlẹyinju aanu kan to gba a silẹ lọwọ awọn eeyan ti wọn ti gbe bẹntiroolu jade lati fi dana sun un nigba naa.
"Nitori pe iya mi kii ṣe ọmọ ilu yii, ni ọjọ ti wọn jo ile wa, ko si ẹni to gba a sile ni ilu yii."
Ko si ija laarin emi ati Fayose, aawọ to wa ninu ẹgbẹ lo mu ko maa ṣe atilẹyin fun APC
Ninu ọrọ rẹ to sọ nipa ohun to le ṣe fa a ti awọn agba ẹgbẹ oṣelu naa bii Ayọ Fayọṣe ṣe lọ n ṣe atilẹyin fun oludije ẹgbẹmiran; Ọgbẹni Wọle Oluyede ni ko si aawọ laarin oun ati gomina Ekiti tẹlẹ to tun jẹ agba ẹgbẹ oṣelu PDP naa. O ṣalaye pe o ṣeeṣe ko jẹ wi pe edeaiyede to wa ninu ẹgbẹ naa lo mu ko gbe irufẹ igbesẹ bẹẹ.
O ni to ba jẹ pe ẹniyan to n duro ṣinṣin lori ọrọ rẹ ni Fayoṣe ni, ko yẹko yipada lori awọn ohun to ti sọ.
Ninu itẹsiwaju ọrọ rẹ, Ọgbẹni Oluyed ni ipinlẹ Ekiti ko yatọ si bo ṣe wa lọdun mẹrin sẹyin eleyi to ni oun bi awọn eeyan kan ti wọn si ṣalaye pe awọn ko ri iyatọ ilọsiwaju kankan ni ipinlẹ naa lati igba ti gomina to wa nipo nibẹ lọwọ yii ti de ori ipo.