Ṣé òótọ́ ni pé Ààrẹ Tinubu fẹ́ pa orúkọ Naijiria dà tó tún fẹ́ wọ́gilé òfin Sharia ní Naijiria?

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba apapọ ti kede pe irọ ni iroyin to n lọ n igboro pe Aarẹ Bola Ahmed Tinubu fẹ yi orukọ Naijiria pada si "United States of Nigeria," ati pe o fẹ wọgile ofin Sharia ni iha ariwa.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Aarẹ, Bayo Onanuga, fi lede, o ni irọ nla gbaa ni iroyin naa ati pe awọn to n gbe iroyin ọhun kiri fẹ mọọmọ fi da wahala silẹ ni Naijiria ni.

O ni "Ileeṣẹ Aarẹ fẹ fi to awọn ọmọ Naijiria leti ati lati sọ ni gbangba pe ko si ootọ kankan ninu iroyin ẹlẹjẹ to n lọ nigboro pe Aarẹ Bola Tinubu fẹ ṣe atunṣe si ofin ti yoo yi orukọ Naijiria pada si United States of Nigeria ati lati wọgile ofin Sharia ni iha ariwa."

Gẹgẹ bii Onanuga ṣe sọ, awọn oloṣelu kan to fẹ da omi alaafia Naijiria ru lo n gbe iroyin naa kiri.

O ni "Iroyin ọhun, ti ko darukọ orisun to ti jade jẹ ọkan lara awọn ọna ti awọn kọlọrọsi oloṣelu kan n lo lati mu idarudapọ wa si aarin awọn araalu ati lati da ija oṣelu silẹ ṣaaju eto idibo gbogbogbo to n bọ lọna."

Ọọfisi Aarẹ wa rọ awọn ọmọ Naijiria ki wọn maṣẹ naani iroyin naa.

Onanuga tun ni irọ ni iroyin pe Aarẹ fẹ fi atunto ofin kan to pe ni "Project True Federation" ranṣẹ sile igbimọ aṣofin agba.

Agbẹnusọ Aarẹ ọhun ṣalaye pe Tinubu ko ni erongba kankan lati fi "Project True Federation" ṣọwọ sile igbimọ aṣofin agba lọjọ karundinlogun, oṣu Kejila, ọdun yii to jẹ ọsẹ diẹ si eto idibo ọdun 2026.

O ni ọrọ to ṣe pataki ni ọrọ atunto ofin, nitori naa kii ṣe nnkan ti Aarẹ tabi ile igbimọ aṣofin yoo kan maa ṣe bo ṣe wu wọn.

O fi kun pe ohun to jẹ Aarẹ logun lọwọ yii ni bi yoo ṣe sọ eto ọrọ aje Naijiria to di dẹnukọlẹ ji.

Lẹyin naa lo rọ awọn ọmọ Naijiria ki wọn dẹkun ati maa pin iroyin ẹlẹjẹ kiri, paapaa lasiko ti oniruru nnkan n ṣẹlẹ bayii ṣaaju eto idibo ọdun 2027.