Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ètò ẹ̀yáwó iléègbé ₦100m ti Tinubu kéde fọ́mọ Naijiria

Aarẹ Bola Tinubu wọ buba olomi buluu pẹlu fila, o wa lẹgbẹẹ ile ori oke
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ Bola Tinubu ti kede eto ẹyawo ọgọrun un miliọnu naira fun ileegbe fawọn ọmọ Naijiria to ba ni amuyẹ fun ẹyawo naa.

Ijọba apapọ ni igbesẹ yii wa lara akiyitiyan lati pese ileegbe si i, eyi ti akọsilẹ sọ pe orilẹede Naijiria si nilo ile miliọnu mẹẹdogun lati koju iṣoro airilegbe.

Iroyin fi idi rẹ mulẹ pe awọn to ba gba owo yii yoo lanfaani lati san an pada fun ogun ọdun.

Tinubu kede ọrọ naa loju opo X rẹ nibi ti aarẹ ti sọ pe eto yii yoo jẹ ki ọpọ ọmọ Naijiria lanfaani si ileegbe.

Aarẹ ni eto ẹyawo yii yoo jẹ ki o rọrun fun ọpọ ọmọ Naijiria lati nile lori.

Ohun to yẹ ki o mọ nipa eto ẹyawo ileegbe N100m ti Tinubu kede

Eto ẹyawo san-an diẹ diẹ yii wa labẹ eto N1trn MOFI Real Estate Investment Fund (MREIF).

Ele 9.75% ni awọn to ba ya owo yii yoo maa da pada lọdọọdun.

Awọn to ba fẹ ya owo yii ni lati san ida 10% owo ile ti wọn ba fẹ ra, nigba ti wọn o ni anfaani lati san iyooku fun ogun ọdun.

Ijọba gbe eto yii kalẹ lati ṣeranwọ fawọn ọmọ Naijiria lati le sanwo tan ni ẹẹkan naa fun ile ti wọn ba fẹ ra.

Bi o ṣe le forukọ silẹ fun ẹyawo ileegbe ree

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba ti o n ṣalaye eto ẹyawo naa, Aarẹ Tinubu fi ẹni to ba fẹ ra ile N10m ṣe apẹẹrẹ.

Aarẹ ni iru ẹni bẹẹ gbọdọ san miliọnu kan naira na, ki o to maa san N85,400 loṣooṣu fun ogun ọdun.

Tinubu ṣalaye pe ko din ni ọmọ Naijiria 2,300 ti wọn ti jẹ anfaani ẹyawo N160bn lati ipinlẹ mẹtadinlọgbọn labẹ eto MREIF bayii.

Aarẹ ni ijọba oun gbe eto naa dide lati wa ojutuu si iṣoro tawọn ọmọ Naijiria n koju nipa ileegbe.

Aarẹ Naijiria ni ko si ọmọ orilẹede Naijiria ti ko lanfaani si ẹyawo naa niwọn igba ti wọn ba ti ni amuyẹ fun un.

''O ko nilo lati mọ minisita, tabi gomina tabi ẹnikẹni nileeṣẹ aarẹ ki o too jẹ anfaani yii.

Eto ẹyawo yii wa fawọn ọmọ Naijiria to koju oṣuwọn fun un lai fi ẹsin tabi ibi ti wọn n gbe ṣe.

Tinubu tun ṣalaye wi pe ọna miran tawọn eeyan tun le gba nile lori ni nipasẹ banki Federal Mortgage Bank of Nigeria (FMBN) to maa n yawọn eeyan lowo lati fi ra dukia eyi ti wọn yoo maa san diẹ diẹ pada.

Banki FMBN ni aarẹ sọ pe o n yawọn eeyan ni N50m pẹlu ele 6% lori owo ti wọn ba ya.

O ni awọn to ba ya owo ni banki FMBN yii lanfaani lati fi ọgbọn ọdun san an pada.

Aarẹ Tinubu fikun ọrọ rẹ pe araalu tun lanfaani lati gba ida 25% ninu owo ifẹyinti wọn lati le ra dukia.

Awọn lọkọ laya naa si le jọ gba owo yii ki o le to wọn ṣe ohun ti wọn ba fẹ ṣe.

Ileegbe 77,400 towo rẹ ko gara nijọba fẹ pese fun araalu

Ileegbe 77,400 towo rẹ ko gara nijọba fẹ pese fun araalu

Tinubu ṣalaye pe oniruuru ọna ni ijọba oun fẹ lo lati pese ile towo rẹ ko gara fawọn ọmọ Naijiria.

Lara awọn eto mii ti ijọba apapọ fẹ lo ni eto Family Homes Fund ati Renewed Hope Social Housing Programme, iyẹn akanṣe eto lati pese ileegbe fun ẹbi.

Tinubu ní eto Family Homes Fund ti pese ile to le 53 fawọn ọmọ Naijiria ti ko rọwọ họri.

Aarẹ ni eto Renewed Hope Social Housing Programme ni tiẹ fẹ pese ileegbe 77,400 kaakiri orilẹede Naijiria.

O fikun ọrọ rẹ pe ko din ni ọgọrun ile tijọba ti pese fawọn opo nipinlẹ Kaduna, nigba ti awọn iyawo awọn ọmogun to ṣubu loju ija ti ri ile aadọta gba niluu Ibadan.