Ademola Adeleke àti APC sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí ara wọn lẹ́yìn ìjà òṣèlú tó wáyé l'Osun

Àkọlé fídíò, Ija oṣelu Osun
Ademola Adeleke àti APC sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí ara wọn lẹ́yìn ìjà òṣèlú tó wáyé l'Osun
Published

Rogbodiyan oṣelu ipinlẹ Osun ti gbọna mii yọ ni bayii ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ati Accord n fẹsun iwa janduku kan ara wọn.

Ṣaaju ni gomina ipinlẹ ọhun ti kọkọ ke sita pe awọn janduku ninu ẹgbẹ oṣelu APC n kọlu awọn ọmọ ẹgbẹ oun, Accord.

Adeleke sọ pe kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ ọhun ko ba oun ṣiṣẹ pọ lati yanju rogbodiyan oṣelu to n waye nipinlẹ naa.

Eyii to ṣẹlẹ lẹnu lọlọ yii ni a gbọ pe ẹmi eeyan meji sọnu si, ti awọn mii tun farapa.

Asimiyu Ajibola, oloṣelu ti ibọn ba sọ fun BBC pe ṣe lawọn janduku oloṣelu naa dena de oun lati gbẹmi oun ki Eledua to ko oun yọ.

Dokita to ṣetọju rẹ, Babatunde Afolabi, sọ fun wa pe ikun ni ibọ ti ba a.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọta ibọ naa wọ inu rẹ, o si gba odi keji jade amọ wọn ṣiṣẹ abẹ fun lati doola ẹmi rẹ.

Victor Akande, to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu Accord ni ipinlẹ Osun ati gomina Adeleke fẹsun gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Gboyega Oyetola pe oun lo n ran awọn janduku lati kọlu awọn ọmọ ẹgbẹ awọn.

Ẹwẹ, Adebayo Adeleke, to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Osun ti sọ pe irọ ni Accord n pa mọ ẹgbẹ awọn, a ti pe awọn ko wu iwa janduku kankan, bẹẹ ni APC ko fi ibọn le ẹnikẹni kiri.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ.