Mo máa pèsè ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fáráàlú tí mo bá di gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti – Segun Akande

Àkọlé fídíò, Segun Akande AAC Ekiti
Mo máa pèsè ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fáráàlú tí mo bá di gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti – Segun Akande
Published

Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AAC nipinlẹ Ekiti, Segun Akande ti ṣeleri eto ẹkọ ọfẹ fawọn eeyan ipinlẹ ọhun ti wọn ba le fi ibo wọn gbe de ipo gomina.

O ni lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ titi de le ẹkọ girama lawọn araalu yo ti maa jẹ anfani eto ẹkọ naa.

Akande lo sọ ọrọ yii lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ niluu Ado Ekiti.

O ni "Ohun ti a le ṣe ni, a si maa ṣe, ti ẹ ba fi ibo gbe mi wọle... si ipo gomina.

"Awọn to wa ni nile ẹkọ giga wa, iyẹn fasiti ipinlẹ Ekiti, a maa ge owo ile ẹkọ awọn naa si idaji.

"Nipa ti eto ilera, maa ri wi pe ni ọdun meji mi akọkọ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ekiti, maa ri wi pe ko si ohun ti a o nilo nipa ti eto ilera ti a o maa lọ siluu nla miran tabi lọ si oke okun mọ."

Oludijẹ naa to jẹ ọdọ sọ pe ọpọ awọn akẹgbẹ onu lo ti japa lọ silẹ okeere latari bi nnkan ṣe ri ni Naijiria amọ oun yan lati duro lọna ati tun ipinlẹ Ekiti ṣe.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun ti Akande ba BBC sọ lori awọn eto rẹ fun ipinlẹ Ekiti to ba le di gomina.