Mo ṣetán láti dupò ààrẹ ní 2027, ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ ni ìdìbò abẹ́lé wa- Omoyele Sowore

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bi igbaradi ṣe ti bẹrẹ lagbo oṣelu fun idibo apapọ ọdun 2027 lorilẹede Naijiria, ajijagabra ati oloṣelu, Omoyele Sowore, naa ti fi ẹrongba rẹ lati dupo aarẹ ilẹ yii ni 2027 han.

Tẹ o ba gbagbe, Sowore du ipo aarẹ Naijiria ni 2019 ati 2023, ṣugbọn ipo naa ko bọ si I lọwọ.

Ọjọ Ẹti ana, ọjọ kejilelogun oṣu Karun-un ọdun 2026 yii ni Sowore kede erongba rẹ lati dupo aarẹ lori eto ileeṣẹ amohunmaworan Channels kan.

Koda, o ni eto ti n lọ lati dibo abẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu ti oun yoo ti dije.

Sowore sọ pe ọsẹ to n bọ yii ni idibo abẹle naa yoo waye pẹlu.

Ṣe Sowore nikan ni ẹgbẹ fẹ fa kalẹ tabi yoo ba awọn kan ta kangbọn?

Nigba ti ibeere jẹ jade fun ajijagbara naa, pe ṣe oun nikan ni ẹgbẹ yoo fa kalẹ lati dije ipo aarẹ naa tabi yoo ba awọn kan ta kangbọn, Omoyele Sowore dahun pe:

"Ẹ jẹ ki ẹgbẹ pinnu lori awọn oludije rẹ."

Sowore fi kun alaye rẹ pe o yẹ ki awọn ọmọ Naijiria dan ijọba mi-in wo, yatọ sawọn oloṣelu to ti n ba a bọ tipẹ ti wọn ti mọ.

Nigba to n dahun ibeere lori idi to fi ro pe ẹgbẹ oṣelu tirẹ daa ju tawọn Tinubu, Atiku Abubakar, Peter Obi ati bẹẹ bẹẹ lọ, Sowore sọ pe awọn wọnyi ti ja ọmọ Naijiria kulẹ.

"Gbogbo awon ti o n darukọ yii lo ko Naijiria sinu oṣi, aisi aabo, inira, ibanujẹ ati ipohunrere ẹkun to n koju.

"Ṣe o tun fẹ ki Naijria tẹsiwaju ninu yiyan awọn eeyan yii sipo to ba wu wọn ni, ki wọn tun le maa jiya si I abi, ko wa di pe wọn ko ni I tẹti si awa ta a ni ọgbọn to le gba orilẹede yii silẹ ?"

Sowore tẹsiwaju pe oun n dije lọtẹ yii lati jawe olubori ni.

O ni nnkan ti yipada, igba ti le ju ti tẹlẹ lọ lorilẹede yii, awọn ọmọ Naijiria naa n wa ilana ọtọ to yatọ si ohun ti won ti n ba bọ tẹlẹ.

Nipa ilana iforukọsilẹ lọna imọ ẹrọ ti ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC,gbe kalẹ fun awọn ẹgbẹ oṣelu, Sowore ṣalaye pe ẹgbẹ African Action Congress (AAC) toun yoo ti dije ko ti I pari eto tirẹ lori iyẹn, ṣugbọn eyi ko di ipinnu ati dije oun lọwọ.