Òní ni ìdájọ́ yóò wáyé lórí aáwọ̀ inú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP àti ADC

Asia idanimọ ẹgbẹ oṣelu PDP ati ADC

Oríṣun àwòrán, PDP/ADC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbogbo oju ti wa lara ẹka eto idajọ Naijiria bayii ti awọn araalu n duro de idajọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria lori ọrọ adari awọn ẹgbẹ oṣelu nla nla ni Naijiria.

Ile ẹjọ naa n mura lati tete yanju ẹjọ ọhun gẹgẹ bii alakalẹ ajọ eleto idibo, INEC.

Lonii ni idajọ yoo waye lori ọrọ adari to ti n fi awọn ẹgbẹ oṣelu PDP, LP ati ADC logbologbo.

Iṣoro ti awọn ẹgbẹ oṣelu naa n koju ni nnkan lati ṣe pẹlu ọrọ adari, eyii to n mu ko ṣoro fun wọn lati yan ẹni ti yoo ṣoju wọn ninu eto idibo Aarẹ to n bọ lọdun 2027.

Ti ẹ ko ba gbagbe, INEC ti kede ọjọ ti eto idibo gbogbo ọdun 2027 yoo waye, o si ni gbedeke akoko ti awọn ẹgbẹ oṣelu gbọdọ kede awọn ti yoo ṣoju wọn ninu eto idibo naa ki ipolongo ibo to bẹrẹ.

Gẹgẹ bii ikede INEC, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2027 ni eto idibo Aarẹ ati ile igbimọ aṣọfin yoo waye.

Nigba ti idibo sipo gomina atawọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ yoo waye lọjọ kẹfa, oṣu Keji, ọdun 2027 kan naa.

Ni imurasilẹ fun to idibo gbogbgo naa, ajọ INEC ni gbogbo ẹgbẹ oṣelu gbọdọ ṣe nnkan to yẹ, ki wọn si yanju aawọn aarin wọn ki wọn tun ṣe eto idibo abẹnu wọn laarin ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin si ọgbọn ọjọ, oṣu Karun un, ọdun 2026.

Ohun to fa ẹjọ ninu awọn ẹgbẹ oṣelu naa

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Fun ẹgbẹ oṣelu mejeji, ọrọ adari lo n ṣokunfa wahala to n mu ko ṣoro fun wọn lati tẹsiwaju.

Ni ti ẹgbẹ oṣelu ADC, ile ejẹ naa yo gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ kotẹmilọrun ti David Mark pe tako Nafiu Bala Gombe pe ipo adari ẹgbẹ naa ko tọ so Mark lasiko yii.

Lonii yii gan ni igbimọ adajọ marun un ti adajọ Lawal Garba n dari wọn yoo gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ naa.

Lati igba ti ija adari ti n waye ninu ẹgbẹ oṣelu ADC fun ọpọ oṣu ni ajọ INEC ti kọ lati kede igun kankan gẹgẹ bii eyii ti oun da mọ bii adari ninu ẹgbe naa.

Ninu iroyin kan naa, ile ẹjọ to ga julọ ọhun yoo gbe idajọ kalẹ lori ija adari to n waye ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, eyii to n fa ọwọ aago wọn sẹyin.

Adari igun kan ninu ẹgbẹ naa, Kabiru Tanimu Turaki lo pe ẹjọ ọhun tako idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun to gb kalẹ lọjọ kẹsan an, oṣu Kẹta.

Lara ohun ti wọn n ja le lori ninu ẹgbe oṣelu PDP ni ojulowo adari ẹgbẹ, awọn ti awọn ipo kan ninu ẹgbẹ naa tọ si ati abajade awọn ipade gbogbo ti wọn ṣe laipẹ yii.

Awọn onwoye ohun to n lọ ninu oṣelu ni Naijiria ti sọ pe idajọ oni le fopin si gbogbo rogbodiyan to n lọ ninu oṣelu Naijiria ṣaaju idibo ọdun 2027 tabi ko mu ki rogbodiyan naa tunbọ buru siwaju sii.