A kò lọ́wọ́ nínú ìdájọ́ tó yọ Atiku kúrò lára àwọn olùdíje sípò ààrẹ- APC

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar/Facebook/ Nigerian Presidency
Bi ẹgbẹ oṣelu ADC ṣe fẹsun kan ijọba apapọ labẹ asia ẹgbẹ APC, pe awọn ni wọn wa nidii bi kootu ṣe paṣẹ pe Atiku Abubakar ko ni i dije ninu idibo ọdun 2027, APC naa ti fesi pada pe ọwọ awọn ko si nibẹ rara.
Akọwe ikede apapọ fun APC, Felix Morka, sọ pe awọn ẹgbẹ alatako maa n tete di ẹbi ru APC nigbakigba ti idajọ ile ẹjọ ko ba ri bi wọn ṣe fẹ.
O ni nigba ti idajọ ba ri bi wọn ṣe fẹ ni wọn maa n gboriyin fun eto idajọ Naijiria.
Morka sọ pe to ba jẹ pe kootu ko yọ Atiku danu, awọn alatako ko ni I maa naka aleebu si ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣejọba.
"Ko sofin to ni wọn ko le yọ olori ẹgbẹ"
Bakan naa ni ọmọ ẹgbẹ APC to tun n ja fun ẹgbẹ naa, Abdulhakeem Adegoke Alawuje, sọ pe ko sohun to jọ pe APC lo wa nidii wahala to n ṣẹlẹ ninu ADC.
Alawuje sọ pe etekete ati ọna lati ṣi oju awọn eeyan kuro ninu wahala to wa ninu ADC ni wọn ṣe n sọ pe ẹgbẹ APC lo n daamu awọn.
Ninu atẹjade ti Alawuje fi sita, o ni bi kootu ṣe da igun ADC David Mark nu ki i ṣe ohun ti oju ko ri ri,nitori ko si ofin to sọ pe wọn ko le yọ olori ẹgbẹ nipo.
"Ẹ jẹ ka jọ sọ eyi ko yera wa daadaa: Ko sohun to kan APC ninu rogbodiyan abẹnu awọn olori ẹgbẹ to n ṣẹlẹ ninu ADC."
O rọ awọn to n sọ pe APC n da si ọrọ ADC lati yẹ ohun to rọ mọ ẹjọ naa wo.
"Idajọ kootu gbọdọ ye eeyan daadaa labẹ ofin ti wọn fi gbe e kalẹ, ki I ṣe ka maa yi I po lati tẹ wa lọrun tabi koju awọn ọta wa ninu oṣelu."
Bẹẹ ni Alawuje wi ninu alaye rẹ.
"To ba ru wọn loju ki wọn gba kootu lọ, ohun ti a ko fẹ ni ki wọn maa mọ ọn mọ yi ohun ti ile ẹjọ sọ po"
Gẹgẹ bi Alawuje ṣe wi lorukọ APC, o ni ariyanjiyan lori idajọ kootu ko ni ọna mi-in ti wọn fi n yanju rẹ ju ki eeyan pe ẹjọ ko tẹmi lọrun lọ.
"Bi idajọ kootu ko ba tẹ ẹnikẹni lọrun, ọna ipẹjọ ko tẹ mi lọrun ti ofin la kalẹ ṣi wa.
"Ohun ti a ko ni I gba ni ki wọn maa fun idajọ ni itumọ mi-in, ki wọn maa wa awọn eeyan ti wọn a jọ maa mu alatako lọtaa, ati igbiyanju lati mu ẹgbẹ mi-in wọnu ẹgbẹ to yẹ ko kọkọ yanju ọrọ ara rẹ na."
O ni kawọn to n sọ pe APC lọwọ si idaamu APC mu ẹri wa fun ohun ti wọn n sọ.
Ohun to ṣee sẹ ko ṣẹlẹ bayii ni pe ile ẹjọ Ko tẹ mi lọrun yoo da si ọrọ yii, nibi ti igun mejeeji yoo ti koju ara wọn.
"Ẹ má finá ṣeré o"- ADC kìlọ̀ fún APC lórí ìdájọ́ tó yọ Atiku kúro lára àwọn olùdíje ipò ààrẹ

Oríṣun àwòrán, KOLA SULAIMON/AFP via Getty Images/Nigerian Presidency
Lẹyin ti ile ẹjọ giga ilu Abuja ti gbe idajọ kalẹ, pe Atiku Abubakar to fẹ dupo aarẹ ni 2027 ninu ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC) ko le dije mọ, ẹgbẹ naa ti kilọ fun ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣejọba lati ma ṣe fina ṣere pẹlu igbesẹ yii.
ADC sọ pe bi ile ẹjọ ṣe tu igun David Mark ti Atiku ti fẹ dije ka ninu ẹgbẹ ADC, jẹ akoba fun ọpọ ọmọ ẹgbẹ naa ti wọn fẹẹ dije ninu idibo ọdun to n bọ.
Wọn ṣapejuwe idajọ to waye l'Ọjọbọ bii ohun to le ṣakoba fun ijọba Demokresi, ti ipa buruku ti yoo ni si kọja ọdọ Atiku nikan nitori yoo kan ijọba ibilẹ, ipinlẹ ati apapọ.
"Ọtẹ oṣelu ni wọn fi gbe idajọ naa kalẹ"
Ninu atẹjade ti ADC fi kilọ fun ijọba apapọ, eyi ti Akọwe ikede rẹ lapapọ, Bolaji Abdullahi, fi sita lo ti ni ọtẹ oṣelu ni kootu fi gbe idajọ to yọ Atiku kalẹ.
O ni wọn mọ ọn mọ gbe e si akoko ti ADC ṣẹṣẹ pari ipolongo idibo aarẹ nipinlẹ Sokoto ni, eyi ti ko ju ọjọ kan si akoko idajọ naa lọ.
Bolaji Abdullahi lorukọ ADC, sọ pe awọn eeyan tu jade pupọ fun ipolongo naa, eyi to n jẹ ijaya fun APC bo ṣe sọ.
To si mu wọn fẹ ba ireti ọpọ eeyan to fẹran ADC jẹ, pẹlu idajọ ti kootu gbe kalẹ.
ADC ninu atẹjade naa sọ pe:
"Ṣe ohun ti awọn eeyan yii fi n ṣere ye wọn ṣa?
"A kilọ fun APC: Ẹ ma fi ina ti ẹ ko lagbara lori rẹ ṣere.
"Awọn ọmọ Naijiria lo ni Naijiria, ki i ṣe APC. Ipo aarẹ ki i ṣe ogún. Bi Aarẹ ba ro pe oun ti ṣe daadaa nipo, ki lo de to n bẹru ifigagbaga?
"Ti APC ba ro pe awọn eto oun atawọn oludije oun gbajumọ, ki lo de ti wọn ko fa ara wọn kalẹ fun idibo alaafia?
"Eyi ki i ṣe nipa Atiku Abubakar tabi David Mark, nipa ẹtọ awọn ọmọ Naijiria lati yan adari to wu wọn funra wọn ni. "Nipa ẹtọ ẹgbẹẹgbẹrun awọn oludije lati kopa ninu ijọba awaarawa ni."
Bakan naa ni ADC koro oju si idajọ tuntun yii, wọn lo tako idajọ akọkọ to waye lọjọ keji oṣu Keje ọdun 2026, ti Adajọ Musa Liman ti ile ẹjọ giga ijọba apapọ kan naa gbe kalẹ.
Idajọ akọkọ naa ni ADC sọ pe o fi aaye gba igun ẹgbẹ yii ti David Mark n dari, to gba pe ẹgbẹ to lẹtọọ labẹ ofin ni pẹlu awọn igbimọ amuṣẹṣe rẹ.
Wọn ni ile ẹjọ onipo kan naa ko lagbara lati yi idajọ ile ẹjọ bii tirẹ pada.
Ohun to ṣẹlẹ yii, ti idajọ tuntun waye yii, ko ṣẹyin ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bi ADC ṣe sọ.
"Alaafia ati iduroṣinṣin orilẹede ju ero ọkan tabi ifẹ aarẹ tabi ẹgbẹ oṣelu lọ. Ko sẹni to gbọdọ tori pe o fẹ maa wa nipo agbara lọ ko wa fi gbogbo orilẹede sinu ewu."
Bẹẹ ni ADC wi.
Ẹgbẹ naa rọ ẹka idajọ lati da aabo bo ominira ADC.
Wọn rọ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn kaakiri Naijiria lati ma ṣe foya, ki wọn tẹle ofin ki wọn si maa wo igbesẹ ti yoo kan.
Ẹgbẹ́ òṣèlú ADC tako ìdájọ́ tó yọ Atiku gẹ́gẹ́ bíi olùdíje sípò Ààrẹ, ó ní APC fẹ́ dáná sun Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC) ti bu nu atẹ lu idajọ to wọgile igun David Mark to n ṣakoso ẹgbẹ oṣelu ADC to si yọ Atiku Abubakar gẹgẹ bii ọkan lara awọn oludije sipo Aarẹ lọdun 2027.
Akọwe gbogbogbo ẹgbẹ naa, Mallam Bolaji Abdullahi sọ ninu atẹjade kan lọjọbọ pe idajọ naa n tumọ si pe ẹgbẹ oṣelu APC fẹ pa ẹgbẹ alatako rẹ ni ati pe o fẹ dana sun Naijiira.
ADC ni bi idajọ naa ṣe waye lẹyin nnkan bii wakati mẹrinlelogun pere ti obitibiti ero jade fun ipolongo oloṣelu ibo Atiku nipinlẹ Sokoto mu ifura lọwọ.
Atẹjade naa ni "A gbagbọ pe wọn ti kọ idajọ naa ṣaaju akoko yii. Ipolongo ibo to waye ni Sokoto lo mu wọn tete gbe idajọ naa kalẹ.
"Lana, ẹgbẹgbẹrun ọmọ Naijiria lo tu jade lati ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu ADC toun ti ileri wa lati maye dẹrun fun wọn.
"Lonii, wọn wa n sọ fun awọn eeyan naa pe wọn le fi idajọ ile ẹjọ wọgilẹ ẹgbẹ ati oludije ti wọn tẹle."
Ẹgbẹ ọhun sọ siwaju si pe idajọ naa le ṣakọba fun ẹgbẹgbẹrun eeyan to n du ipo ni ijọba ibilẹ, ijọba ipinlẹ atawọn oludije mii ni ipele ijọba apapọ.
Wọn ni ọrọ naa kọja ọrọ Atiku tabi David Mark, amọ o jẹ nipa ẹtọ ogunlọgọ araalu lati yan ẹni to wu wọn sipo.
ADC wa ni idajọ naa ko tẹ awọn lọrun, awọn yoo si pe e nija ni gbogbo ọna.
Atẹjade naa tẹsiwaju pe awọn ọmọ Naijiria lo ni Naijiria; kii ṣe ẹgbẹ oṣelu APC, ati pe ipo Aarẹ kii ṣe oye idile.
Wọn ni "Ti Aarẹ Tinubu ba mọ daju pe oun ṣe daadaa nipo, ki lo n ba a lẹru?"
Lẹyin naa ni wọn rọ awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun ki wọn ṣe suuru, ki wọn ma si fi ofin sọwọ ara wọn.
Ilé-ẹjọ́ wọ́gilé igun David Mark tó ń ṣàkóso ẹgbẹ́ òṣèlú ADC, yọ Atiku gẹ́gẹ́ bí olùdíje sípò Ààrẹ

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar/Facebook
Ile ẹjọ giga apapọ to wa niluu Abuja ti yọ Atiku Abubakar kuro lara awọn oludije fun ipo aarẹ Naijiria ninu eto idibo ọdun 2027.
Ọjọbọ, ọjọ karun-un, oṣu Kọkanla, ọdun 2026 ni ile-ẹjọ naa paṣẹ pe ilana ti ẹgbẹ oṣelu ADC ti Atiku fẹẹ gba jade lati dije fi yan awọn oludije ko bao fin eto idibo mu.
Ile-ẹjọ naa paṣẹ pe ohun wọgile igbimọ iṣakoso African Democratic Congress, ADC ti Sẹnetọ David Mark jẹ alakoso rẹ, ati gbogbo igbesẹ ti wọn ti gbe sẹyin.
Onidajọ Peter Lifu to gbe idajọ naa kalẹ sọ pe ọna ẹburu ni igbimọ iṣakoso David Mark gba de ipo naa, ati pe ki wọn lọ rọkun nile.
Onidajọ Lifu sọ pe gbogbo igbesẹ ti David Mark ati igbimọ rẹ gbe patapata lori eto idibo ọdun 2027 ko lẹsẹ nilẹ.
Bakan naa lo sọ pe ọna ti wọn gba yan Atiku, ẹni to ti figba kan ri jẹ igbakeji Aarẹ Naijiria, gẹgẹ bi oludije sipo Aarẹ lọdun 2027 ko ba ofin mu.
Bakan naa ni ile-ẹjọ tun da gbogbo eto ati ilana ti wọn gba minisita fọrọ abẹle tẹlẹ, Rauf Aregbesola gẹgẹ bi akọw agba, ati awọn miran nu.
Ninu ẹjọ naa ni nọmba rẹ jẹ FHC/ABJ/CS/1819/2025, eyi ti igbakeji alakoso agba ẹgbẹ oṣelu ADC tẹlẹ, Nafiu Bala Gombe pe, ni ile-ẹjọ ti fidi rẹ mulẹ pe gbogbo awọn oludije ti igbimọ iṣakoso Mark yan lati kopa ninu eto idibo 2027 ni ki wọn lọ sinmi.
Bi ẹ ko ba gbagbe, asiko ti aawọ de sinu ẹgbẹ naa, ni wọn yan igbimọ adele ti David Mark yoo ṣakoso rẹ lati tukọ eto idibo abẹle.
Igbesẹ yii ni wọn sọ pe ko tẹ awọn kan lọrun ninu ẹgbẹ, ti wọn fi gba ile-ẹjọ lọ, lati beere fun idajọ ododo.
Kí ni ilé-ẹjọ́ sọ?
Onidajọ Lifu, nigba to n gbe idajọ naa kalẹ, sọ pe ọna David Mark ati igbimọ iṣakoso naa gba de ipo ọhun tako iwe ofin ẹgbẹ oṣelu ADC ati iwe ofin idibo, to fi mọ iwe ofin ilẹ Naijiria, ti ọdun 1999.
Bakan naa ile-ẹjọ tun sọ pe ki ajọ eleto idibo, INEC ma ṣe ri igbesẹ ti awọn alakoso ẹgbẹ naa gbe nibi ipade to waye lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2025, nitori pe ko ba ofin mu.
Ki ni idajọ yii tumọ si fun ẹgbẹ ADC ninu eto idibo to n bọ?
Nigba to n sọrọ lẹyin idajọ naa, agbẹjọro Gombe, Lukman Fagbemi ṣalaye pe "Gbogbo igbesẹ ti ẹgbẹ oṣelu ADC gbe lati ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keje, ni ile-ẹjọ ti wọgile."
Agbẹjọro miran, Luka Musa Haruna (SAN), fidi rẹ mulẹ pe idajọ naa ti sọ ẹgbẹ oṣelu ADC ni ẹgbẹ oṣelu ti ko nii kopa ninu eto idibo ọdun 2027 to n bọ.
Haruna sọ pe lati ori ipo Aarẹ, Gomina, Sẹnetọ, Ile-Igbimọ Aṣofin, ati awọn ipo yooku kaakiri Naijiria, ẹgbẹ naa ko nii ni aṣoju kankan mọ.
ADC yóò pe ẹjọ̀ kòtẹ́milọ́rùn
Ṣugbọn ṣa, akọwe to n ri sọrọ ọmọ ẹgbẹ fun ADC, toun naa wa ninu iwe ipẹjọ naa, Nkemakolam Ukandu, ti sọ pe awọn yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ naa.
Ukandu jẹ ko di mimọ pe idajọ naa kii ṣe idajọ igbẹyin, nitori pe ile-ẹjọ kọtẹmilọrun ṣi wa nibẹ fun awọn.




























