You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọkùnrin kan hú òkú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ báńkì bíi ẹ̀rí pé ó ti kú, òun sí ló tọ́ sí láti gba owó rẹ̀
- Author, Rakhi Ghosh and Nikita Yadav
- Role, BBC Hindi and BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Jitu Munda ni wọn ti n sọrọ rẹ ni India bayii fun igbesẹ kan to gbe eyi to ya ọpọ eeyan lẹnu.
Munda, ẹni ọdun mejilelaadọta di ilumọọka bi o ṣe lọ hu Egungun oku ẹgbọn rẹ obinrin, to si gbe lọ si ile ifowopamọ lati fidi rẹ mulẹ fun ile ifowopamọ naa pe ẹgbọn oun ti jade laye.
Ni ibẹrẹ ọsẹ yii ni Munda di ẹni ti wọn n sọrọ rẹ nigba ti fidio kan to ṣafihan bo ṣe n gbe Egungun oku ẹgbọn rẹ lọ sile ifowopamọ naa gba ori ayelujara.
O ni gbogbo igbiyanju oun lati gba owo to wa nile ifowopamọ lo ja si pabo bi wọn ṣe n sọ pe ki oun mu ẹri jade pe ẹgbọn oun ti ku ni tootọ, ti oun ko si ni ẹri mii.
Ni ẹkun Keonjhar, orilẹ ede India ni iṣẹlẹ naa ti waye lọjọ Aje eyi to n mu ki ọpọ awọn eeyan maa bu ẹnu ate lu awọn alaṣẹ ati ile ifowopamọ naa pe wọn ko ran ọkunrin naa lọwọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọkunrin naa hu Egungun oku ẹgbọn rẹ lati gbe lọ sile ifowopamọ amọ ile ifowopamọ naa jiyan pe awọn ni ko hu oku to si jẹ pe awọn akọọlẹ to le fidi rẹ mulẹ pe ẹgbọn rẹ tik u ni awọn n beere fun.
Ile ifowopamọ naa ni o jọ pe ọkunrin naa ko mọ ilana to yẹ lati beere iru owo bẹẹ lo ṣe lọ hu oku ẹgbọn rẹ ati pe awọn ti fun ẹni to tọ labẹ ofin ni owo naa.
Minisita fọrọ owo ni Odisha, Suresh Pujari sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa ati pe awọn maa fi adari ẹka ile ifowopamọ naa jofin lori iwa to wu si ọkunrin naa.
Bakan naa ni ijọba ekun Keonjharn aa tun kọminu lori aabo ẹtọ awọn eeyan eyi to ni o ye ki wọn mu ni ọkunkundun.
Munda sọ fun BBC Hindi pe iṣoro naa bẹrẹ nigba ti ẹgbọn oun, Kalara, eni ọdun mẹrindinlọgọta jade laye ni ibẹrẹ ọdun yii.
O ni o n ṣiṣẹ to si n gba owo ojumọ. O ni Kalara ti pada sile awọn lẹyin ti ọkọ rẹ ati ọmọ to bi jade laye.
Nigba to ku oṣu diẹ ti Kalara maa jade laye, o ta awọn nnkan ọsin rẹ ni 19,300 rupees, to si ko owo naa sile ifowopamọ.
Munda ni ọpọ igba ni oun ti lọ si ile ifowopamọ lati gba owo naa lẹyin iku ẹgbọn oun ṣugbọn to ja sip abo.
O ni nigba ti ẹni to n dari ẹka ile ifowopamọ naa kọ lati tẹti si oun, ti wọn si n sọ pe ki oun mu ẹri wa pe ẹgbọn oun tik u ni oun ṣe lọ wu oku rẹ lati fi ṣe ẹri pe o tik u ni tootọ.
Fidio to gba ori ayelujara ṣafihan bi Munda ṣe gbe Egungun naa sinu apo to sig be lọ siwaju ile ifowopamọ naa.
Lẹyin ti fidio naa gba ori ayelujara ni ọpọ eeyan n sọrọ lori wahala tawọn eeyan maa n ṣe lati ri owo ti ẹni to ba jade laye gba kuro nile ifowopamọ paapaa ti eni naa ko ba fi orukọ eni to le gba owo naa silẹ ni pato.
Ki lawọn igbesẹ lati fi gba owo eni to ti jade laye kuro nile ifowopamọ?
Ni India, ti eeyan ba jade laye lai sọ ẹni to le gba owo rẹ, awọn ẹbi maa nilo lati pese iwe ẹri pe ẹni naa ti jade laye lootọ, ti eyi si maa n gba ọpọlọpọ akoko.
Lẹyin fidio naa ni ile ifowopamọ Indian Overseas Bank to n ṣe akoso Odisha Grameen Bank ti iṣẹlẹ naa ti waye sọ pe awọn ko beere pe ki Munda lọ hu oku ẹgbọn rẹ.
Wọn ni awọn ti sọ igbesẹ to yẹ ko gbe fun-un amọ o kọ lati tẹle e.
Adari ẹka ile ifowopamọ ti Munda lọ naa, Sushant Kumar Sethi sọ pe ohun ti Munda kọkọ sọ ni pe ẹgbọn oun ko le rin mọ, pe ko le yọju si ile ifowopamọ ni oun fi fẹ bao wo naa tawọn si sọ fun pe awọn maa lọ sile Kalara dipo ki awọn ko owo naa fun.
Sethi tun jiyan awọn ọrọ mii ti Munda sọ, ti wọn si sọ pe kii ṣe ati oṣu meji lo ti n yọju sile ifowopamọ naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa atawọn alaṣẹ rọ Munda lati lọ sin oku naa pada, ti wọn si ṣe aridaju rẹ fun pe wọn maa ba yanju ọrọ rẹ.
Awọn alaṣẹ ṣeleri lati fun-un ni 30,000 rupees gẹgẹ bi iranwọ.
Nigba to fi maa di ọjọru, wọn ti ṣe iwe iku obinrin naa, ti wọn si fun ẹbi obinrin naa kan torukọ rẹ w ani akọọlẹ ẹni to le gba owo naa ni owo ọhun.