You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọwọ́ tẹ afurasí tó yìnbọn níbi àpèjẹ akọ̀ròyìn tí Trump wá nílùú Washington
Ọwọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ FBI ti tẹ ọkunrin kan ti wọn funra si pe oun lo ṣina ibọn bolẹ nibi ipade awọn akọroyin to Aarẹ Donald Trump wa niluu Washington.
FBI ti bẹrẹ si n fi awọn akọsilẹ diẹdiẹ nipa afurasi naa lede.
Wọn ni ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ni ọkunrin ọhun.
Ọlọpaa ti kede orukọ rẹ gẹgẹ bi Cole Tomas Allen to n gbe ni Torrance, California, nipinlẹ Los Angeles.
Ileeṣẹ iroyin CBS, to ni ajọṣepọ pẹlu BBC jabọ pe iṣẹ olukọ ni Allen n ṣe ni Torrance lẹyin to kẹkọọjade nile ẹkọ California Institute of Technology.
Ọlọpaa sọ pe ile itura ti iṣẹlẹ naa ti waye ni afurasi naa wọ si ṣaaju iṣẹlẹ ọhun, oniruru ohun ija oloro lo si wa ni ikawọ rẹ bii ibọn ati ọbẹ.
Lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, ọlọpaa ti lọ tu gbogbo ilẹ rẹ ka fun awọn ẹri ti yoo ran iwadii wọn lọwọ.
Ẹwẹ, CBS ni afurasi naa sọ pe awọn kan lara awọn to n ba Trump ṣiṣẹ lo wa nidi ikọlu naa.
Gẹgẹ bi wọn ṣe jabọ, igba marun un si mẹjọ ni iro ibọn naa dun lakọlakọ ki ọwọ to tẹ Allen.
Amọ awọn agbofinro tete gbe Trump kuro nibẹ naa ki nnkan to yiwọ.
Agbébọn yìnbọn níbi àpèjẹ àwọn oníròyìn tí Trump àti ìyàwó rẹ̀ wà nílé ìjọba America
Ọrọ di bo o lọ o ya fun mi lọna lanaa ode yii ti i ṣe Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu Kẹrin ọdun 2026, nile ijọba ilẹ America, nigba ti ẹnikan ṣina ibọn bolẹ nibi ipade awọn oniroyin ti Aarẹ Donald Trump ati iyawo rẹ, Melania, ti n ṣe faaji.
Niṣe ni wọn pada gbe Trump ati iyawo rẹ jade kuro ni gbagede apejẹ naa.
Ọfiisi abẹnu ijọba America fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, bo tilẹ jẹ pe ẹnikẹni ko pada farapa.
Wọn ni ṣugbọn ọwọ ba ẹnikan to ti wa ni ahamọ bayii lori iṣẹlẹ naa.
"O maa n jẹ iyalẹnu bi iru nnkan bayii ba ṣẹlẹ, ko si yipada."
Aarẹ Trump lo sọ bẹẹ ninu ọrọ rẹ to sọ lẹyin iro ibọn ọhun.
O si kọ ọ soju opo ayelujara Truth Social pe:
"Wọn ti mu ẹni to yinbọn naa, mo si ti ni ki wọn jẹ ki eto maa tẹsiwaju, ṣugbọn awọn agbofinro yoo pesẹ bamu."
Lẹyin naa lo tun kọ ọ soju opo naa pe awọn agbofinro sọ pe koun ati iyawo oun fi ibudo apejẹ naa silẹ.
Ki lo ṣẹlẹ nibi apejẹ ounjẹ alẹ ọjọ naa gan-an?
Apeje awọn oniroyin yii jẹ ti awọn akọroyin to maa n gbe ohun to ba n ṣẹlẹ nile ijọba America ti a mọ si White House jade.
Ọdọọdun ni apeje naa maa n waye, nibi ti won ti maa n ṣeto ironilagbara fun awon to ba n kọ nipa iṣẹ iroyin, ti won si tun maa n fun awon akoroyin to ba yẹ ni ami ẹyẹ.
Ni ti ana ode yii, ile itura Washington Hilton lo ti waye, wọn si n reti ki Aarẹ Donald Trump sọrọ nibẹ.
Bi apeje ọjọ naa ṣe n lọ lọwọ ni wọn gburoo ibọn lagbegbe ibi ti eto ti n lọ lọwọ.
Ọpọ awọn akọroyin BBC to wa nibẹ, royin pe akọlukọgba bẹrẹ si i waye bi iro ibọn ṣe n dun ni.
Nigba naa ni awọn oṣiṣẹ abẹnu US jade lati mu Aarẹ Trump ati iyawo rẹ jade ni gbọngan apejẹ naa.
Awọn ẹṣọ alaabo lo ṣeto bi awọn alakooso agba bii Robert F Kennedy Jr to wa fun eto ilera, ati Pete Hegseth to n ri si aabo ṣe jade.
Awọn eeyan yoku to wa nikalẹ wa ninu gbọngan naa, ṣugbọn wọn ti i pa- Ọpọ akọroyin lo wa nibẹ pẹlu, ti wọn n gbiyanju lati fi ohun to n ṣẹlẹ ranṣẹ si ileeṣẹ iroyin wọn.
Apeje awọn akọroyin yii ti di aṣa ti ko ṣee ma ṣe l'America, ọdun 1921 lo ti bẹrẹ, aarẹ to ba si wa lori aleefa maa n yọju sibẹ lati ba wọn kopa.
Eyi ni igba akọkọ ti Trump yoo yọju si apeje naa gẹgẹ bii aarẹ to wa lori aleefa, ọdun 2011 lo yọju si wọn gbẹyin.
Ta a ni afurasi tọwọ ba?
Afurasi tọwọ ba pe o yinbọn naa ni wọn pe orukọ rẹ ni Cole Tomas Allen, ẹni ọdun 31.
Wọn ni o n gbe ni Torrance, California, bi ẹka iroyin CBS to jẹ alabaaṣẹ BBC North America ṣe sọ.
Aarẹ Trump sọ pe ẹka ọtẹlẹmuyẹ FBI ati awon oniṣẹ abẹnu America n gbe igbesẹ lati lọ yẹ ile rẹ wo ni California.
Ọga ọlọpaa fidihẹ-ẹ ni Washington; Jeffery Carroll, ṣalaye pe oun naa wa lara awon alejo to wa ninu otẹẹli naa nigba ti ibọn yinyin ọhun waye.
O ni ko sẹni kankan ninu ewu.
''Awon agbofiro ni awon naa yinbọn pada, a ko le fi iye awon to yinbon mulẹ, pẹlu afurasi.''
Bẹẹ ni ọlọpaa sọ.
Carroll sọ pe afurasi agbebọn naa ni "ibọn kukuru lọwọ, o tun ni ti ilewọ pẹlu ọ̀bẹ ọlọkan-o-jọkan. "
Jeanine Pirro, Olootu idajọ ni Washington, ṣalaye pe afurasi naa yoo koju ẹsun meji.
Ẹsun lilo nnkan bii ibọn lasiko rogbodiyan ati lilo nnkan oloro fun awon oṣiṣẹ agbofinro.
Ọla ọjọ Aje ni wọn yoo gbe e lọ si kootu bi Olootu idajọ ṣe wi.
Bo si tilẹ jẹ pe idi ti afurasi naa fi yinbọn ko ti I foju han, Trump loun yoo fi alaye lori rẹ lede ọjọ Aiku.