Níṣojú mi báyìí ni wọ́n ṣe ṣá ọkọ mi ládàá pa ṣùgbọ́n mi ò lè pariwo kí wọ́n má bàá ṣá èmi náà-Ìyàwó olóyè Ibadan

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Laipẹ yii ni BBC News Yoruba mu iroyin wa nipa Oloye Oloogbe Mutairu Oladosu, Ọtun Balogun Okelade Okin, lagbegbe Omi- Adio, ipinlẹ Oyo, ẹni ti awon kan yabo oko rẹ lati fi ẹran jẹko, to kọ fun wọn ti won si ṣa a ladaa pa.

Gẹgẹ bi a ṣe fi to yin leti, iṣẹle naa ṣoju iyawo akọfẹ Oloogbe Oladosu ati ọmọ wọn obinrin kan.

Iyawo Oloogbe ati ọmọ rẹ titi kan ẹgbọn rẹ ti ba BBC News Yoruba sọrọ lori ohun to ṣẹlẹ, eyi ni ohun ti won wi.

"Mi o le pariwo ki wọn ma baa ṣa emi naa pa"

Pẹlu aworan ibanujẹ ti ko le kuro lọkan rẹ gẹgẹ bo ṣe wi, ni Abilekọ Oladosu fi ṣalaye pe:

"Ọkọ mi ni Ọtun Oluọde ni Aba Asa, niluu Omi- Adio to wa nijọba ibilẹ Ido, ni ipinlẹ Ọyọ.

"A de inu oko wa la ba awọn darandaran meji kan ti wọn n fi maaluu jẹ nnkan ọgbin wa, ọkọ mi kilọ fun wọn pe ki wọn dẹkun iwa ika naa, ki wọn ma fi maaluu jẹ ẹgẹ ti oun gbin mọ.

"Awọn darandaran naa ko gba, wọn ni awọn ko le ko maaluu awon kuro lori ilẹ wa.Iyẹn lo di ariyanjiyan ti wọn bẹrẹ si i ba ara wọn fa.

"Nibi ti ọkọ mi ti n kọ jalẹ fun wọn ni awọn meji mi-in tun jade wa lati inu igbo, wọn si bẹrẹ si i le emi ati ọmọ mi obinrin pẹlu ada ati oogun abẹnugọngọ."

Iyawo Oloogbe Oladosu tẹsiwaju pe nigba ti awọn to n le awon lọ naa ko ri awọn mu, wọn pada, wọn si darapọ mọ awọn yoku wọn, wọn n ṣa Baba Oloye ladaa ni gbogbo ara .

Iya naa fi kun un pe oju oun bayii ati ọmọ oun lo ṣe, bi awon eeyan naa ṣe n ṣa olori ile ati aba awọn ladaa.

O ni awon n ri gbogbo e kedere nibi tawon sa pamọ si, ṣugbọn awọn ko le pariwo ki wọn ma baa pa awọn.

Lẹyin naa lo ni awọn sare lọ si abule lati pe fun iranlọwọ, sugbọn nigba ti awọn ara abule yoo fi de ibẹ, awọn darandaran naa ti sa lọ, wọn si fi oku oloye naa silẹ ninu agbara ẹjẹ.

Ọmọ oloogbe ati ẹgbọn rẹ sọrọ

Alaye ti ọmọ oloogbe ṣe ko yatọ si ti mama rẹ, ọmọbinrin naa fi omije ṣalaye bi won ṣe pa baba oun loju oun lai ri nnkan kan ṣe.

Ninu ọrọ ẹgbọn Oloogbe toun naa ni ka fi orukọ bo oun laṣiiri, o ni awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti mu ọkan ninu awọn afurasi darandaran naa.

O ni ṣugbọn ki ijọba dide iranlọwọ lori idajọ ẹjọ naa.

Ni afikun, ẹgbọn oloogbe naa sọ pe awọn afurasi naa ti halẹ pe awọn ṣi n pada bọ, eyi si n mu kawọn ara abule maa bẹ ijọba ipinle Ọyọ fun aabo to peye.

Oloogbe Oloye Mutairu Oladosu ṣi ni iya laye, yatọ si iyawo meji ati awon omo to fi saye lọ.

Alaafin ní kí Aare Onakakanfo gbé ìgbésẹ̀ lórí ètò àbò ilẹ̀ Yoruba, kí ni òfin sọ?

Alaafin ke si Aarẹ Ọnakakanfo ko wa nnkan ṣe eto abo ilẹ Yoruba

Alaafin ilu Oyo, Ọba Akeem Owoade, ti ke si Aarẹ Ọna kakanfo, Iba Gani Adams lati wa nnkan ṣe si eto abo to mẹhẹ nilẹ Yoruba.

Ọrọ yi lo jẹyọ ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Alaafin, Ademola Adeniyi, fi lede.

Ninu atẹjade naa ni Alaafin ti rọ Gani Adams lati bẹrẹ ijiroro pẹlu awọn ori ade nilẹ Yoruba lori ọna abayọ si eto abo naa to mẹhẹ.

Owoade sọ pe igbesẹ ọhun ṣe pataki lasiko yii ki nnkan to buru ju bo ṣe wa lasiko yii lọ.

Atẹjade naa sọ pe "Mo gba Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams lamọran ko bẹrẹ ijiroro bi wọn ṣe le lo ọna ibilẹ lati koju eto abo pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ọba alade, olori ilu atawọn ti ọrọ eto abo kan ki eto abo to mẹhẹ le di ohun atijọ nilẹ Yoruba.

"Nibi ti ọrọ de duro yii, a rọ awọn araalu ki wọn maa ṣe sun gbera, ki wọn maa tẹlẹ ofin, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro.

"Ẹtọ gbogbo araalu ni lati maa gbe layọ ati alaafia, dandan si ni ki wọn ni eto abo to dara."

Ki ni ofin sọ lori ọrọ Alaafin yii?

BBC Yoruba kan si amofin Olusegun Kofoworola lati ileeṣẹ Lincs Attorneys lati mọ ipo ofin lori irufẹ ipe bayii.

Nigba to n sọrọ, Kofoworola sọ pe labẹ ofin Naijiria, ijọba apapọ nikan lo lẹtọọ lati da si eto aabo, eredi ree ti gbogbo awọn ileeṣẹ ati ẹka eto abo fi wa labẹ rẹ.

Ninu alaye rẹ, awọn orilẹede kan bii Amẹrika gba awọn ijọba ipinlẹ laaye lati da si ọrọ eto abo, eredi ree ti wọn fi ni awọn ọlọpaa ipinlẹ bii New York City Police Department, NYPD, Los Angeles Police Department, LAPD, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O ni Ijọba apapọ nikan, ati ile igbimọ aṣofin agba nikan lo le daba lori eto abo ni Naijiria.

Kofoworola sọ pe "Alaafin ilu Oyo ko lagbara, Gani Adams ko lagbara, gomina ipinlẹ gan ko lagbara lati sọrọ lori aabo."

Amọ ṣa o fi kun pe Alaafin tun lẹtọọ lati gbe igbesẹ eto abo lori awọn eeyan rẹ labẹ ẹka ofin to ni eeyan le daabo bo ara rẹ lọwọ ẹni to ba fẹ ṣe ijamba si, iyẹn 'right to self defence.'

Amofin ọhun sọ pe irufẹ eeyan bẹẹ le lo oogun abẹnugọngọ lati daabo bo ara rẹ, o tun le lo awọn ohun ija bii ibọn amọ wọn gbọdọ gba aṣẹ ijọba ki wọn to le lo ibọn.

O ni "Ofin to gba wọn laaye lati ṣe bẹẹ lo rọ mọ ofin to gba awọn adugbo laaye lati ni fijilante fun abo ara wọn."

Afurasí darandaran ṣá Olóyè ìlú Ibadan pa, ṣèlérí láti padà wá fún ìkọlù míì

Lẹyin nnkan bii ọsẹ mẹfa ti awọn agbebọn ṣọṣẹ ni Ori Apata, to wa ni ijọba ibilẹ Ido, nipinlẹ Oyo, iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe wọn tun ti gbẹmi oloye kan nipinlẹ naa.

A gbọ pe Aba Asa, to wa lagbegbe Omi Adio, niluu Ibadan ni wọn ti gbẹmi oloye ọhun to jẹ agbẹ.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ pe inu oko ni Oloye Mutairu Oladosu, to jẹ Otun Balogun Okelade Okin wa ki awọn afurasi Fulani darandaran to gbẹmi rẹ sibẹ.

Iyawo oloogbe naa ati ọmọ rẹ obinrin ti wọn wa nibẹ lasiko ikọlu ọhun ṣalaye pe awọn ri awọn Fulani meji ti wọn n da ẹran jẹko lori ilẹ baba awọn.

Lẹyin naa ni Oladosu kilọ fun wọn ki wọn kuro lori oko oun.

Asiko to n ni itakurọsọ pẹlu awọn darandaran naa ni awọn darandaran meji mii jade lati inu igbo ti wọn si bẹrẹ si n fi oogun ati ada le iyawo ati ọmọ rẹ obinrin naa ti ọjọ ori rẹ ko tii pe ogun ọdun.

Iyawo ati ọmọbinrin oloogbe naa sọ pe ori lo ko awọn yọ ti wọn to lugọ sinu igbo kan.

Lẹyin ti awọn darandan naa ri pe awọn ti moribọ lọwọ wọn ni wọn pada lọ kọlu Oloye Oladosu ti wọn si ṣa lada pa.

Iyawo oloogbe ọhun ni inu igbo ti oun wa loun ti n wo bi wọn ṣe n ṣa ọkọ oun ti ko si si ohun nnkankan ti oun le ṣe nipa rẹ.

Obinrin naa to ti di opo bayii sọ pe oun ko le pariwo ki awọn darandaran naa ma baa ṣa oun ati ọmọ oun pa.

O ni lẹyin ti wọn gbẹmi ọkunrin naa tan ni wọn na papa bora ki awọn eeyan abule ọhun to de ibẹ.

Awọn eeyan abule ọnaa ni ọlọpaa ti mu awọn afurasi ọhun bayii amọ awọn ko ni igbagbọ ninu ileeṣẹ ọlọpaa lati ri idajọ ododo gba.

Ọkan lara awọn agbagba abule naa sọ fun awọn akọroyin pe awọn darandaran ọhun ti ṣeleri lati pada lọ ṣọṣẹ nibẹ, eyii to mu ki wọn maa rawọ ẹbẹ si ijọba fun iranlọwọ.