A gbàgbọ́ pé àlàáfíà yóò jọba ní Cameroon lẹ́yìn àbẹ̀wò Pope Leo XIV- Aráàlú

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn eeyan lorilẹede Cameroon ti fi igbagbọ wọn han, pe alaafia yoo jọba ni awọn ibi ti rogbodiyan ti n ṣẹlẹ niluu naa, lẹyin abẹwo Pope Leo XIV, olori ijọ Aguda lagbaaye.

Ọjọruu, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kẹrin ọdun 2026 ni Olori ijọ Aguda lagbaaye naa balẹ si papakọ ofurufu Yaoundé Nsimalen International Airport, nibi ti Olootu ijọba, Joseph Dion Ngute, ti gba gba a lalejo.

Pope Leo XIV ninu abẹwo ọlọjọ mọkanla rẹ to n ṣe si orilẹede Africa mẹrin ti wa ni Cameroon bayii.

Awọn olori ẹsin ati araalu rẹpẹtẹ to ti n duro de Papa naa ni wọn fi tilu-tifọn ki I kaabọ.

Ninu ọrọ ọkan lara awọn ọmọ orilẹẹede Cameroon, Modestine Abomo, o sọ fun BBC pe inu oun dun pe Cameroon wa lara ilu ti Papa yan laaayo lati ṣabẹwo si.

Obinrin to jẹ ọkan lara awọn ikọ olorin ẹmi to waa ki Pope kaabọ naa sọ pe awọn n fẹ ki Alufaa agba ijọ Aguda naa boju wo awọn apa ibi ti ogun ti n ja Cameroon.

Ko si bu ororo itura si awọn ibi ti iṣoro ti n koju orilẹede naa.

"Lẹyin abẹwo rẹ, a gbagbọ pe gbogbo nnkan yoo da ani Cameroon."

Ọmọ lẹyin Jesu miran toun naa waa ki Pope kaabọ, Perpetue Lema, lo sọ bẹẹ.

Bi Pope Leo XIV yoo ṣe rin ni Cameroon

Ile Aarẹ orilẹede Cameroon; Paul Biya ni Pope kọkọ ṣabẹwo si bo ṣe de, nibi ti eto ti wa pe yoo ba Aarẹ ati awọn olori awujọ sọrọ.

Bakan naa ni eto ti wa nilẹ fun Pope Leo lati ṣabẹwo sile awọn ọmọ alailobi to wa ni olu ilu naa.

Pope yoo tun foju kan awon Biṣọọbu ijọ Aguda pẹlu lasiko abẹwo ọlọjọ mẹta rẹ si Cameroon yii.

Tẹ o ba gbagbe, ilẹ Africa mẹrin ti i ṣe Algeria, Cameroon, Angola ati Equatorial Guinea ni Pope yii yoo ṣabẹwo si laaarin ọjọ kẹtala si ikẹtalelogun oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii.

Irinajo naa da le siso okun ifẹ le laarin awọn ilẹ Africa, mimu idagbasoke ba ijọ Aguda, sisọ asọye lori ọrọ ẹsin ati bẹẹ bẹẹ lọ.