You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àbọ̀ ìwádìí BBC lórí ikú ìyàwó Wòlíì olùdásílẹ̀ ìjọ tó ń ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn ní kàyééfì
- Author, Myles Bonnar
- Role, BBC Disclosure
- Author, Ben Robinson
- Author, Kevin Anderson
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9
Ọmọ ogoji ọdun ni Charmain Speirs nigba to pade wolii Eric Adusah.
Fun ọpọlọpọ ọdun ni Speirs fi jẹ onigbagbọ to si maa n darapọ mawọn ọmọlẹyin Kristi nibi kibi ti wọn ba ti pejọ.
Ọrẹ rẹ Anne-Marie sọ pe o dabi ẹni pe o ti ri nnkan to n wa fun ọjọ pipẹ tori o kun fun ayọ.
''Speirs ko fẹ ibaṣepọ pẹlu awọn ọkunrin lasan an mọ.
Ojiṣẹ Ọlọrun lo n fẹ, lẹyin naa lo sọ pe oun ti ri ẹnikan to jẹ gbajugbaja oniwaasu.''
Ifẹ ọkan rẹ yii jẹ oludasilẹ ijọ Global Light Revival Church.
Pasitọ Adusah to jẹ ọmọbibi orilẹede Ghana maa n waasu lori ẹrọ amohunmaworan ni gbogbo igba.
Kii ṣe oniwaasu lasan an ni Adusah jẹ, ọpọ ọmọ ijọ rẹ lo maa n pe e ni wolii.
Wọn si gbagbọ pe o maa n gbọ lati ọdọ Ọlọrun o si maa n sọ iṣipaya fawọn eeyan.
Lẹyin ọdun mẹwaa ti Chairman ti ku, iwadii BBC fi kudiẹkudiẹ han ninu ọrọ ti Adusah sọ.
BBC tun bawọn alabaṣiṣẹpọ Adusah naa sọrọ lori iku Charmain.
Arabinrin Charmain pade wolii yii lódun 2014, wọn si ṣe igbeyawo loṣu Kẹsan an ọdun yii kan naa.
Lẹyin oṣu mẹfa ti wọn ṣe igbeyawo ni Charmain ku, won si ri oku rẹ ni baluwẹ ile itura kan ni Ghana.
Wọn fọwọ ofin mu Adusah lẹyin ti wọn fura si i pe o ṣee ṣe ko jẹ pe oun lo pa a.
Sugbọn wọn pada fi i silẹ lẹyin ti ko si ẹri to le fidi rẹ mulẹ pe oun lo ṣekupa Charmain.
Ilu Arobroath ni Charmain dagba si lorilẹede Scotland laarin ọdun 1970 si 1980.
Awọn ọrẹ rẹ sọ pe ẹni ti ọpọ eeyan fẹran ni Charmain nigba to n dagba.
Ni ọmọ ọdun mọkandinlogun ni Charmain lọ si ilu Glasgow nibi to ti ṣe oriṣiiriṣii iṣẹ lawọn ṣọọbu ati ile ounjẹ.
Ọrẹ rẹ kan sọ pe Charmain padanu aburo rẹ ọkunrin kan ninu ijamba ọkọ.
O tun sọ pe aburo rẹ ọkunrin mii di ẹni to n mu oogun oloro heroin.
Lẹni ọgbọn ọdun ni Charmain lọ kẹkọọ nipa fifi aworan kọ iroyin.
Charmain bi ọmọkunrin kan lọdun 2007, eyi to pe orukọ rẹ ni Isaac.
Amọ ọrẹ Charmain, Anne-Marie fura wi pe nnkan n ṣẹlẹ ninu igbeyawo rẹ nigba toun ṣabẹwo si i.
Anne-Marie ni Charmain sọ foun pe ọkọ oun ko fi ifẹ han soun rara.
Nigba ti Chairman loyun tan fun Adusah ni o rinrin ajo lọ si ilu rẹ ni Arbroath lati lọ ki iya rẹ.
Iyẹn ni igba akọkọ ti iya rẹ Linda yoo foju ri Charmain lati igba ti o ti ṣe igbeyawo.
O sọ fun mama rẹ wi pe igbeyawo oun pẹlu Adusah ko lọ bi oun ṣe fẹ.
Awọn alejo kan wa loru
Akọsilẹ awọn ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe Adusah lo ri Charmain kẹyin ki o tu ku.
O ṣalaye ninu akọsilẹ ọlọpaa pe oun lọ jẹun lọsan an pẹlu Charmain kawọn to jọ lọ wẹ ninu omi.
Adusah ni léyin naa lawọn jọ pada sinu yara nibi tawọn ti gbadun ara awọn.
Adusah ni nnkan bi ago mejila oru loun kuro ni ile itura naa lati lọ wọ baalu lọ si Accra fun ipade kan laago mẹfa aarọ, ki oun to pada si UK.
O ni o wu Chairman lati duro ni Ghana fun igba pipẹ.
Amọ, ẹlẹrii kan to wa lẹnu iṣẹ nile itura naa lalẹ ọjọ ti iṣẹlẹ ọhun waye sọ pe awọn nnkan kan wa ti wolii naa ko mẹnu ba.
Edward (ti a fi orukọ bo laṣiri) sọ pe Adusah pada si yara 112 ti Charmain wa pẹlu ọkunrin meji lalẹ ọjọ naa.
O ni oun ranti pe ọkan ninu awọn meji naa gbe baagi kan dani, eyi to sọ pe o ya awọn lẹnu.
Edward ni awọn ọkunrin meji naa wa ninu yara ọhun fun bii wakati kan, awọn si ni wọn ba Adusah ko ẹru sinu ọkọ rẹ.
O ni bi ago kan oru ni Adusah kuro ni ile itura naa, o si sọ fawọn oṣiṣẹ ile itura naa wi pe ki wọn ma yọ iyawo oun lẹnu.
Adusah sọ nipa awọn alejo naa fun ajọ ọtẹlẹmuyẹ orilẹede Ghana.
Akọsilẹ ọlọpaa sọ nipa ọkunrin mẹta to wa nile itura naa lalẹ ti iṣẹlẹ naa waye.
Iwadii fi han pe meji ninu awọn ọkunrin wa nile itura ọhun lalẹ naa, ati pe ninu ijọ ni wọn ti mọ Adusah.
Ohun ti wọn sọ ni pe awọn n gbadura ninu yara ile itura ni.
Igbimọ oluwadii BBC beere lọwọ ọtẹlẹmuyẹ orilẹede Scotland, Allan Jones, wi pe ko ṣe agbeyẹwo akọsilẹ ileeṣẹ ọlọpaa Ghana.
O ni iyalẹnu lo jẹ pe Adusah ko sọ nipa ọpọ nnkan to ṣẹlẹ.
Jones ni Edward to jẹ oṣiṣẹ ile itura naa ti sọ ọpọlọpọ ọrọ nipa awọn eeyan to ri, amọ, Adusah ko sọ nkankan.
Awijare ti ko fẹsẹ mulẹ
Adusah sọ fun ileeṣẹ ọlọpaa wi pe ni ago mejila oru loun fi iyawo oun silẹ ninu yara ile itura to wa lati lọ fun ipade pẹlu alufaa kan ni Accra ni ago mẹfa aarọ.
BBC ba alufaa naa sọrọ, ko si le fidi ọrọ Adusah mulẹ.
Ko si ẹri to daju pe ajọ ọtẹlẹmuyẹ Ghana ṣe iwadii ọrọ ti Adusah sọ pe oun fi iyawo oun silẹ ninu ile lọ si ilu Accra.
BBC kan si ileeṣẹ ọlọpaa lori ọrọ naa ṣugbọn wọn kọ lati sọrọ.
Kayeefi nipa oogun heroin
Ṣaaju ki wọn to ṣe ayẹwo oku Charmain ni Adusah ti sọ fawọn ọlọpaa pe iyawo oun ni iporuuru ọkan eyi to maa n jẹ ki o fẹ gbẹmi ara rẹ, ati pe o tun maa n lo oogun oloro tipẹ tipẹ.
Ọsẹ méfa si akoko yii ni esi ayẹwo oku rẹ fi han pe ko si eri to le fidi rẹ mulẹ pe ẹnikan huwa ipa si Charmain ko to ku.
Dokita to ṣe ayẹwo naa sọ pe esi ayẹwo naa fi han pe oogun oloro heroin wa ninu ẹjẹ rẹ.
O ni o ṣee ṣe ko jẹ pe aṣilo oogun heroin lo ṣokunfa iku rẹ.
Oogun heroin ko wọpọ lorilẹede Ghana papaa julọ lawọn ilu kekeke bii Koforidua ti Charmain n gbe.
Dokita to ṣe ayẹwo naa beere lọwọ awọn ọtẹlẹmuyẹ wi pe bawo ni arinrin-ajo afẹ ṣe ri oogun heroin.
Ileeṣẹ ọlọpaa ko ri oogun oloro kankan ninu ẹru Charmain ni yara 112 ti o wa nile itura naa.
Lara ẹri ti ọfiisi agbẹjọro agba Ghana sẹ fi Adusah silẹ ni ọrọ to sọ pe Charmain ni iporuuru ọkan eyi to maa n jẹ ko fẹ pa ara rẹ.
Amọ, awọn ẹbi ati ọrẹ Charmain sọ pe ko lo oogun oloro kankan ati pe ko kii n ṣe bi ẹni pe o maa pa ara rẹ
Ayẹwọ oku Chairman waye fun igba keji ni UK, esi ayẹwo naa si fi han pe ko si ẹri to daju pe o ti n lo oogun fun igba to ti pẹ
Ta ni wolii ti n wọ naa?
Iwadii BBC fi han pe oriṣiiriṣii orukọ ni Wolii Eric Adusah n jẹ.
Eric Adu Brefo ni wọn mọ ọn si ni Ghana.
Eric Isaiah Kusi Boateng lo n jẹ ni Maryland l'Amẹrika nibi to n gbe bayii.
Awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ tẹlẹ sọ pe oriṣiiriṣii ọrukọ ati ọjọ ori ni awọn mọ Adusah pẹlu.
Lynne o ṣapujuwe ibaṣepọ rẹ pẹlu Adusah gẹgẹ bi eyi to kun fun iwa ipa sọ pe oun mọ ọn gẹgẹ bi Daniel.
O ni oun ko tiẹ mọ wi pe oniwaasu ni.
Emily ti a fi orukọ bo laṣiri naa sọ pe gbogbo igbe aye oun lo n dari nigba toun fi wa pẹlu rẹ.
Emily sọ pe Eric gan an gan an yatọ si oniwaasu tawọn eeyan n ri ni ita.
O ni Adusah lo ẹsin lati ko oun laya jẹ debi wi pe oun lo n sọ nnkan toun gbọdọ ṣe foun.
Amọ, ọmọkunrin Charmain, Isaac sọ pe Adusah lu oun ati iya oun.
Isaac ni ''mo maa n gbọ ti iya mi ba n sunkun.
O tun wọ inu yara mi wa lu emi naa.
Mama duro laarin awa mejeeji, lẹyin naa lo ko ẹṣẹ bo mama mi loju.
Ẹmi Eṣu lo wa ninu rẹ, kii ṣe wolii rara pẹlu bi o ṣe maa ba mama mi sọrọ.
Oun lo n dari aye mama mi,'' Isaac lo sọ bẹẹ.
Mama Charmain naa sọ pe oun ri bi Adusah ṣe huwa ipa si ọmọ oun.
O ni oun ri apa ni isalẹ irun Charmain nigba toun ge irun rẹ.
Linda ni awọn apa lilu ti Adusah n lu Chairman niyii.
''Nigba t imo n ya irun Chairman ni mo ṣakiyesi oriṣiiriṣii apa labẹ irun rẹ.
Chairman ko kọkọ fẹ sọ fun mi, nigba to ya lo jẹwọ wi pe Adusah maa n fa irun oun ni.''
Awọn mii naa fidi rẹ mulẹ pe Adusah maa n lo ipa lati dari Charmain.
Ọjọ to kẹyin si ọjọ iku Chairman
Awọn ẹbi Charmain daamu lati ri ba sọrọ ṣaaju akoko iku rẹ.
Ọmọ ijọ Adusah kan sọ fun ileeṣẹ ọlọpaa UK wi pe Charmain ni lati ra foonu mii lai jẹ ki Adusah mọ tori o ti gba foonu ọwọ rẹ.
O ni Charmain tun sọ foun pe Adusah parọ nipa orukọ rẹ, ọjọ ori rẹ, ati pe o ni iyawo mii ni Ghana.
O ni Chairman ti n gbero lati fun Adusah ni iwe ikọsilẹ ki o si ṣoju abẹ nikoo fun Adusah ki o to ku.
Obinrin naa sọ pe Charmain pe oun lori foonu lalẹ ọjọ kan, oun si gbọ bi Adusah ṣe n pariwo mọ ọn ti ko si sọrọ.
O ni lẹyin iṣeju mẹẹdogun loun si asiko naa loun gbọ iro nla kan ti ipe naa si re bete.
Wiwa idahun si oniruuru ibeere
Ikọ oluwadii BBC wa adusah de Maryland l'Amẹrika nibi ti o n gbe pẹlu iyawo atawọn ọmọ rẹ.
Koda, o tun n waasu ni ijọ Global Light Revival nibẹ.
O sọ fun BBC pe iwadii ti wọn n ṣe lori oun ti jẹ ki ọkan oun poruuru lẹyin toun padanu iyawo ati ọmọ oun.
Adusah ko tun dahun ibeere BBC lori awọn ololufẹ rẹ tẹlẹ.
Ohun to jẹ otitọ gan an gan an nipa yara 112 nile itura ni Ghana le ma fara han tan laelae.
Isaac to jẹ ọmọkunrin Charmain si n wa idahun si ọpọ ibeere bo o ṣe n tẹsiwaju igbe aye rẹ lai si iya rẹ mọ.