You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Aiyedatiwa jẹ wá lówó oṣù mẹ́fa, ó tún fẹ́ lé wa níbi tí ìrandíran wa ń gbé láti 1943 - Àwọn àkàndá ẹ̀dá Ago Ireti figbeta l'Ondo
Awọn olugbe agbegbe kan ti a mọ si Agọ ireti, niluu Akure, ipinlẹ Ondo, ti fi ẹhonu han nipa yiyabo ọfiisi Gomina ipinlẹ naa, Lucky Aiyedatiwa, eyi to wa ni Alagbaka, l'Akure.
Eredi ẹhonu awon eeyan naa bi won ṣe wi ni pe gomina n jẹ awọn lowo oṣu mẹfa, eyi to jẹ ẹtọ fun awon bawon ṣe jẹ akanda ẹda to ni arun ẹ̀tẹ̀.
Wọn ni bi awọn ṣe maa n gba owo naa niyẹn lati ọdun gbọọrọ sẹyin.
Yatọ si awon to ni arun ẹ̀tẹ̀ to n gbe ni Agọ ireti, awon mi-in naa n gbe nibẹ ti won ko ni arun yii ṣugbọn ti wọn ṣi jẹ akanda ti ẹya ara miran pe nija, pẹlu awọn to jẹ talika ti ko le da ọwọ mu lọ sẹnu rara.
Wọn tun fẹsun kan Gomina Aiyedatiwa, pe o n gbe igbesẹ lati le awọn kuro nibi ti irandiran awọn ti n gbe lati ọdun 1943.
Ta lo n gbọ bukata awọn eeyan Agọ ireti tẹlẹ?
Latilẹ, ṣaaju iṣakoso Gomina Aiyedatiwa, ijọba ipinlẹ Ondo lo maa n ṣetọju awọn eeyan yii, ti wọn si maa n fun wọn ni owo oṣu lati le tọju ara wọn bi wọn ṣe sọ.
Ṣugbọn ọrọ ti yi pada bayii labẹ isejọba Gomina Lucky Aiyedatiwa.
Awọn eeyan Agọ ireti sọ pe ko san owo fawọn, o si ti pe oṣu mẹfa bayii ti gbese rẹ wa lọrun gomina.
Paripari ẹhonu awon eeyan naa ni pe wọn ni gomina tun fẹ le awọn nibi tawon ti n gbe lati ọdun gbọrọ sẹyin.
Ohun ti awọn eeyan Agọ ireti n fẹ lọ́wọ́ ìjọba
BBC YORUBA de ofisi Gomina Aiyedatiwa, nibi ti ifehonuhan naa ti waye, awọn olugbe Agọ ireti si ṣalaye pe Gomina kọ lati sanwo oṣu to duro bii owo iranwọ tijọba maa n san fawọn lati bi oṣu mẹfa sẹyin.
Wọn ni awọn ti kesi ijọba titi pe ki wọn sanwo naa, sugbọn pabo lo jasi.
Yatọ si ti owo oṣu ti Aiyedatiwa ko san, awọn eeyan naa sọ pe idi gan-an tawọn fi ṣe ifẹhonuhan ni lati tako igbesẹ rẹ lati le awọn kuro nibi tawọn ti n gbe lati 1943.
Wọn ni lati 1943 ni Deji ilu Akure igba naa; Ọba Afunbiowo, ti fun awọn ni ilẹ Agọ ireti, gẹgẹ bi ibi tawọn adẹtẹ yoo tẹdo si, to si jẹ pe lati igba naa ni ẹnikẹni to fi mọ ijọba ko yọ awọn lẹnu.
Wọn ni ṣugbọn Gomina Aiyedatiwa ti sọ fawọn pe igbẹ ni adẹtẹ n gbe bayii.
Olugbe miran salaye pe ni Ọjọru, ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹrin ọdun yii ni awọn oṣisẹ ileeṣẹ ijọba to n bojuto ile gbigbe ati eto ilera, mu iwe wa pe ijọba ko fẹ awọn ni ibudo naa mọ.
Wọn ni eyi jẹ ohun tó ya awọn lẹnu lọpọlọpọ.
Awọn akanda ẹda naa wa rọ Gomina Aiyedatiwa lati di owo rẹ mu bi ko ba san an fawọn, ṣugbọn ko ṣaa fi awọn silẹ si ibi tawọn wa naa.
Wọn tun kesi gbogbo olugbe ipinlẹ Ondo ati ajọ eleto ilera lagbaye; WHO, lati dide iranlọwọ.
Wọn ni ki Gomina Aiyedatiwa maa baa ko awọn kuro ni Agọ ireti tawọn ti n gbe lati ọdun mẹtalelọgọrin (83) sẹyin lawọn ṣe figbeta.