Ìdí rèé tí ọ̀dà tí o fi ń kun irun rẹ sí àwọ̀ mìràn ṣe lè fa jẹjẹrẹ ọyàn fún ọ

Ìdí rèé tí ọ̀dà tí o fi ń kun irun rẹ sí àwọ̀ mìràn ṣe lè fa jẹjẹrẹ ọyàn fún ọ

Iyi ati ẹwà ni irun to ba dudu jẹ gẹgẹ bi Ẹlẹdaa ṣe da irun awa eeyan ilẹ Adulawọ. ṣugbọn bi agba ba n de ati fun awon idi mi-in, irun dudu maa n di funfun.

Bi irun dudu ba n di funfun yii ki i tẹ ọpọ eeyan lọrun, kaluku lo n fẹ da bii èwe.

Eyi naa lo n fa ti ọpọ eeyan ṣe maa n fi ọda ikunrun dudu ti a mọ si dye kun irun wọn, ko too di lasiko yii to di pe oriṣiriṣi awọ lo wa ti wọn n kun irun.

Ṣugbọn njẹ o mọ pe ewu buruku lo n bẹ ninu ki eeyan kun irun rẹ lọda?

Ṣe o mọ pe o le fa aisan jẹjẹrẹ ọyan fun ọ?

Iṣẹ iwadii kan ti National Institute of Environmental Health Sciences gbe jade lo fidi ẹ mulẹ, pe o ṣee ṣe ki awọn eroja dai ti a fi n kun irun si awọ oriṣiriṣi, ṣe afikun ewu to rọ mọ nini aisan jẹjẹrẹ ọyan ni ida ọgọta si i fun awọn obinrin ilẹ Adulawọ to ba n lo dai ni gbogbo igba.

Wo bi fifi dáì sí irun rẹ ṣe le fa jẹjẹrẹ ọyan

Awon onimọ ijinlẹ ṣe iwadii pẹlu lilo obinrin 56,000, iyẹn ẹgbẹrun mẹrindinlọgọta, abọ rẹ si fi han pe awọn obinrin ilẹ alawọ dudu lo ṣee ṣe lati ni aisan jẹjẹrẹ ọyan ni ida ọgọta ninu ọgọrun-un (60/100).

Eyi ko pọ to bẹẹ fun awọn obinrin alawọ funfun.

Iwadii naa tun fi han pe ida ọgbọn (30%) ninu ọgọrun-un awọn obinrin to ba n lo kẹmika amurungun (Chemical hair straightener) lo wa ninu ewu aisan jẹjẹrẹ lai fi ti ẹya tabi awọ ara wọn ṣe.

Loootọ ni iṣẹ iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ohun to n ṣokunfa arun jẹjẹrẹ ni pato nipa lilo dai lẹẹkan laarin oṣu meji tabi ju bẹẹ lọ, ṣugbọn abajade iwadii to ti jade to apero fun kaluku lati ronu si gẹgẹ bii Adulawọ.

Ṣọra fun iru eroja aṣaraloge to n lo loorekoore, ko o si maa wa lalaafia.