Ẹ foríjìn mí, mo ṣetán láti d'ówó padà f'áwọn tó bá fẹ́ gbowó tí wọ́n dá fún mi - Blessing CEO

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajumọ sọrọsọrọ ori ayelujara, Blessing Nkiruka Okoro, ti ọpọ eeyan mọ si Blessing CEO ti tọrọ aforijin lọwọ ọmọ Naijiria lori awuyewuye to n lọ nipa ailera rẹ.

Ti ẹ o ba gbagbe, Blessing ṣe fidio kan ninu eyi to ti bẹbẹ fun iranwọ owo lẹyin to ni oun ti lugbadi arun jẹjẹ, arun naa si ti de ipele ''stage 4.''

Bayii ni ọpọ ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria bẹrẹ si ni da owo fun arabinrin naa.

Ko pẹ si asiko yii lawọn kan bẹrẹ si ni beere fun ẹri lọwọ Blessing lati fidi rẹ mulẹ pe loootọ ni o ni arun naa.

Eyi gan an lo fa awuyewuye ti ọpọ si ti n sọ pe Blessing ti lu awọn ọmọ Naijiria ni jibiti.

Ṣugbọn ni bayii, Blessing ti ṣe fidio miran ninu eyi to ti tọrọ aforijin.

Bakan naa lo sọ ninu fidio ọhun wi pe oun ko purọ mọ ara oun lori ailera oun.

Blessing CEO tun sọ ninu fidio naa wi pe oun ṣetan lati da owo pada fun ẹnikẹni to ba fẹ gba owo ti wọn da foun pada.

''Ohun ti mo fẹ kọkọ sọ ni pe ẹ forijin mi gbogbo ẹyin ololufẹ mi ati gbogbo ọmọ Naijiria.

Ẹ forijin mi nipa awuyewuye to jẹyọ lori ailera mi.

Ni bayii, mo ṣetan lati jẹ ki ẹ maa mọ gbogbo nnkan to niṣe pẹlu eto ilera mi to fi mọ gbogbo ayẹwo ti mo ba n ṣe.

Mo fẹ ki ẹ ni suuru pẹlu mi, gbogbo nnkan to ba ṣẹlẹ pẹlu eto ilera mi ni ẹ maa gbọ nipa rẹ.

Mo tun fẹ ki ẹ mọ pe mi o purọ nigba ailera mi rara,'' Blessing CEO lo sọ bẹẹ.

''Ẹ fi nọmba akanti ranṣẹ, mo maa da owo yin pada''

Blessing ko ṣai dupẹ lọwọ gbogbo eeyan ti wọn dawo jọ fun un lati ran an lọwọ lori ailera rẹ.

O ni oun mọ riri ore ti wọn ṣe foun gan an ni, o si gbadura wi pe ki Ọlọrun maa bu sapo wọn si i.

Gbajugbaja alẹnulọrọ ori ayelujara naa tun sọ pe oun ṣetan lati dawo awọn ọmọ Naijiria ti wọn fẹ gba owo ti wọn da foun pada.

Blessing CEO ni ''mo fẹ ki ẹnikẹni to ba fẹ gba owo rẹ pada kan si mi lori WhatsApp pẹlu ẹri to daju wi pe loootọ ni wọn fowo ranṣẹ si mi.

Ẹ fi nọmba akanti ranṣẹ, mo maa da owo naa pada fun ẹnikẹni to ba fẹ gba owo rẹ.

Mo si tun nilo adura yin, ẹ maa ranti mi ninu adura yin nigba gbogbo wi pe ki Eledua ṣe aṣepe iṣẹ to n ṣe laye mi.''