You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Tinubu yọ Mínísítà ètò ìṣúná Wale Edun nípò, fi Taiwo Oyedele rọ́pò rẹ̀
Aarẹ Bola Tinubu ti yọ minisita eto iṣuna, Wale Edun, nipo o si ti fi Taiwo Oyedele rọpo rẹ.
Igbesẹ yii jẹ iṣẹ atunto ranpẹ ti aarẹ ṣe ninu igbimọ alaṣẹ orilẹede Naijiria lonii ọjọ Iṣẹgun ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹrin yii.
Gẹgẹ bi akọwe ijọba apapọ, George Akume, ti ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita ni irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, minisita meji ni Aarẹ Tinubu yọ nipo ti o si ti rọpo wọn pẹlu.
Sẹnẹtọ Akume fidi rẹ mulẹ pe Edun ati Ahmed Musa Dangiwa ni minisita meji ti aarẹ yọ nipo.
O ni awọn mejeeji si ni Aarẹ Tinubu ti sọ pe ki wọn jọwọ gbogbo nnkan to ba wa ni ikawọ wọn fawọn minisita tuntun ti aarẹ ṣeṣẹ yan.
Oyedele to wa nipo minisita abẹnu fun eto iṣuna ni Naijiria tẹlẹ ti gba ipo ọga rẹ bayii.
Ẹwẹ, Tinubu ti yan Muttaqha Rabe Darma lati rọpo Dangiwa gẹgẹ bi minisita ileegbe ati idagbasoke awujọ.
Ijọba apapọ ko sọ idi ti Tinubu fi rọpọ awọn minsita mejeeji nipo ninu atẹjade ti akọwe agba ijọba fi sita.
Ohun to wa ninu atẹjade ti akọwe ijọba fi sita ni pe aarẹ ti paṣẹ wi pe kawọn minisita mejeeji jọwọ gbogbo nnkan to wa ni ikawọ wọn fawọn minisita tuntun titi Ọjọbọ ọjọ kẹtalelogun ọsẹ yii.
Amọ, Akume ṣalaye wi pe ''igbesẹ aarẹ ṣe pataki lati ri pe eto iṣejọba n lọ bo ṣe yẹ ki o lọ.
Aare tun ṣe eyi lati ri pe eto ọrọ aje Naijiria dara si i lati mu irọrun ba awọn araalu.''
Akume ni igbesẹ aarẹ lati ṣe atunto igbimọ alaṣẹ ijọba wa ni ibamu pẹlu abala 147 ati 148 iwe ofin orilẹede Naijiria ọdun 1999 gẹgẹ bi wọn ti ṣe atunṣe rẹ.
Aarẹ Tinubu wa dupẹ lọwọ awọn minisita meji to yọ nipo fun iṣẹ ribi ribi ti wọn ti ṣe fun orilẹede wọn.