Ẹ wo ìbẹ̀rẹ̀ ayé Aisha Yusuf Ojora, ọmọ atàpátadìde tò di igbákejì akọ́nimọ̀ọ́gbá fun Super Falcons

Àkọlé fídíò, Agbabọọlu
Ẹ wo ìbẹ̀rẹ̀ ayé Aisha Yusuf Ojora, ọmọ atàpátadìde tò di igbákejì akọ́nimọ̀ọ́gbá fun Super Falcons
Aisha Yusuf-Ojora
Published

Fun ọpọ obi lorilẹede yii, bii ẹni to n fi akoko ṣofo ni nigba ti ọmọ wọn ba yọ ere bọọlu gbigba laayo, paapaa ọmọbinrin.

Bẹẹ naa lo ṣe ri fun Aisha Ojora, ọmọbinrin to wa lati ile ẹlẹsin Islam, ti baba rẹ jẹ Imaamu, ti wọn ko si gba fun un bo ṣe fẹ lati maa kopa ninu ere bọọlu to yan laayo.

Aisha ti wọn ti yan bii Igbakeji akọnimọọgba bayii fun ikọ agbabọọlu obinrin Naijiria, ba BBC News Yoruba sọrọ lori irinajo aye rẹ.

Bo ṣe jẹ pe baba oun ko gba koun maa kopa ninu bọọlu, boun ṣe n sa kuro nile lawọn igba kan, ko too di pe baba ku.

O ni awọn ẹbi baba paapaa ko gba koun gba bọọlu lẹyin iku imaamu, bẹẹ ni awọn asiko kan wa toun ko foju kan iya oun.

Aisha ti gba bọọlu fun ilẹ Naijiria , o ti gba awọn ami ẹyẹ agbaye. Wo alaye rẹ ninu fidio yii, nipa bo ṣe pada kogo ja, pẹlu imọran to fun awọn obi nipa ohun ti ọmọ ba fẹ ṣe