Ẹgbẹ́ alátakò ní Israel fẹ̀sùn kan Netanyahu lórí ètò ìdìbò tó wáyé

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Olori ẹgbẹ oṣelu alatako nilẹ Israel, Gadi Eisenkot ati awọn olori ẹgbẹ oṣelu Arab ti fẹsun kan Olootu Benjamin Netanyahu lati maa da si eto oṣelu orileede miran ti ko kan an.
Ẹgbẹ oṣelu Netanyahu, Likud naa tun fẹsun kan awọn ẹgbẹ oṣelu ilẹ Arab to n ṣatilẹyin fun Israel lati ji ibo gbe.
Ileeṣẹ eleto aabo Shin Bet ti wa sọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati mọ boya Israel gba iranlọwọ owo lati orileede Qatar ati Turkey.
Ṣugbọn ṣa, ileeṣẹ to n ri sọrọ ilẹ okeere ni Qatar ti sọ pe ẹsun to ku diẹ kaato ni wọn fi kan awọn, ti awọn naa si fẹsun kan awọn oloṣelu ilẹ Israel lati maa gbe iroyin ẹlẹjẹ kaakiri nipa Doha.
Esi idibo to gbẹyin ṣafihan wi pe ati Netanyahu, ati awọn alatako Jew ko wọle nile aṣofin.
Akọsilẹ awọn ẹgbẹ oṣelu ilẹ Arab mejeeji, The Joint List ati Ra'am – sọ pe Netanyawu lo n lewaju pẹlu ipo mẹtalelaadọta, nigba ti alatako rẹ, Gadi Eisenkot n tẹle pẹlu ipo mejidinlaadọta.
Ẹgbẹ oṣelu Likud fẹsun kan awọn alatako wi pe wọn n fi owo ra ibo lọwọ awọn oludibo, lẹyin ti igbimọ eleto idibo (CEC) sọ fawọn eleto aabo Shin Bet lati ṣe iwadii kikun.

Ètò ìdìbò ń tẹ̀síwájú bí kò ṣè ì tíì sí ẹni tó jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò ní Israel

Oríṣun àwòrán, Reuters/Getty Images
Awọn esi ibo to ti n jade lati orilẹ ede Israel n fi han pe olootu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu n lewaju nibi eto idibo naa to si n ṣaaju alatako rẹ, ẹni to jẹ ọga Ologun tẹlẹ ri, Gadi Eisenkot.
Amọ sibẹ, Netanyahu ko i ti ni iye awọn aṣofin to pọ nile aṣofin.
Pẹlu ida marundinlaaadọrun-un ibo ti wọn ti ka bayii, ẹgbẹ oṣelu Likud to jẹ ti Netanyahu lo ṣeeṣe ki wọn ni awọn aṣofin mẹtalelaaadọta ninu ọgọfa, ti ẹgbẹ oṣelu Yashar ti Eisenkot ṣeeṣe ki wọn ni mẹrindinlaaadọta.
Awọn adari mejeeji yii lo ti n sọ pe awọn maa darapọ mọ awọn ẹgbẹ mii.
Awọn ẹgbe oṣelu ti awọn ẹya Araabu lo ṣeeṣe ki wọn bori ninu ibo mọkandinlogun, to si ṣeeṣe ki wọn sọ ẹni to maa di olootu ijọba ṣugbọn ẹgbẹ oṣelu kan ti sọ pe oun ko ni bawọn ṣiṣẹ.
Awọn ibo 430,000 si 480,000 to jẹ tawọn Ologun atawọn aṣoju orilẹ ede naa nilẹ okeere ni wọn ko i tii ka to si ṣeeṣe ki o to ọjọ kan si meji ki eto idibo naa to pari.
Ni kete ti wọn ba ti pari, Aarẹ Isaac Herzog maa ṣepade pẹlu awọn ẹgbẹ oṣelu, to si maa sọ fun olori to ba woye pe o ṣeeṣe ko gbegba oroke lati ko igbimọ ijọba rẹ jọ, igbesẹ to ṣeeṣe ko gba ọsẹ pupa.
Ni wọn ba kuna, eto idibo mii maa waye.
Nibi ipade kan to waye ni ile igbe rẹ ni Jerusalem, Herzog kan saara si bi ida mẹtadinlọgọrin awọn eeyan ṣe jade lati kopa nibi eto idibo ọjọ Iṣẹgun naa, eyi to jẹ pe ohun lo pọ julọ lati bi ogun ọdun sẹyin bayii.
O sọ pe o ṣeeṣe ki oun gba esi ibo naa ni ọsẹ to n bọ, ti oun yoo si bẹrẹ si ni jiroro pẹlu awọn ti ọrọ kan.
"A gbọdọ ṣe ohun gbogbo ti a le ṣe lati dena ṣiṣe eto idibo mii. Mo gbero pe gbogbo eeyan maa wa pẹlu ọkan mimọ.
Netanyahu ati alatako rẹ ni wọn ti n rọ aarẹ lati sọ fun awọn lati maa ko igbimọ to maa gba wọn ṣe ijọba jọ.
Eisenkot sọ pe awọn eeyan ti fi ibo sọrọ lati beere fun ayipada lẹyin tawọn ileeṣẹ iroyin mẹta ti woye pe o ṣeeṣe ki ẹgbẹ rẹ ni aṣofin 52 si 53.
Amọ lẹyin naa ni Netanyahu sọrọ ni Lukid pe awọn ni ni wọn ni ibo to pọ julọ.
O ni o jẹ ohun to ṣe eewọ pe ki wọn gbe ijọba sọwọ awọn to n gbarale ẹgbẹ oṣelu awọn Arab.
Olori ẹgbẹ oṣelu Democratic sọ pe o ṣeeṣe lati ni ibaṣepọ pẹlu ijọba pẹlu awọn ẹgbẹ oṣelu Arab, ki wọn si kọ akojọpọ Netanyahu.
"A o ni ọjọ iwaju nibi ti a ko ba maa dẹkun lati maa bẹru ki a fopin si iwa ẹlẹyamẹya," Yair Golan kọ soju opo X rẹ.




























