Bàbá Tolwani tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì gbìyànjú – Ẹ̀gbọ́n Toluwani
Mọlẹbi gbajugbaja olori ẹmi to di oloogbe nni, Olayemi Bayonile Bolaji, ti ọpọ mọ si Toluwani Sings ti sọ pe baba awọn ko kọ awọn ọmọ rẹ silẹ.
Lẹyin iku oloogbe naa ni oniruru awuyewuye bẹrẹ si n jade lori ayelujara, lara awuyewuye naa ni pe baba oloogbe naa jina si nigba aye rẹ.
Amọ ẹgbọn oloogbe ọhun, Olayemi Abdulazeez, ti sọ pe baba awọn tọju awọn ọmọ rẹ, o si gbiyanju lori awọn ọmọ ọhun.
Abdulazeez lo sọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.
Ọkunrin naa fidi rẹ mulẹ pe lati kekere ni iya to bi oloogbe naa ti jade laye ti awọn mọlẹbi iya rẹ si tọju rẹ niluu Eko ko to di pe irawọ rẹ tan kaaliri agbaye, amọ baba awọn ko kọ ọ silẹ.
O ni "Baba wa tọju wa, wọn dẹ sẹ igbiyani bi agbara wọn ṣe mọ lori ikọọkan wa, ti a si n fi adura ran wọn lọwọ pe ibi ti wọn ṣe e de ki a le sanjọ fun wọn ju bẹẹ lọ."
Ti ẹ ko ba gbagbe, lẹyin iku oloogbe naa ni gbas-gbos waye lori ibi ti baba oloogbe naa n fẹ ki wọn sin i si, eyii to tako ibi ti iyawo rẹ n fẹ ki wọn sin oku naa si.
Amọ ṣa, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti da si aawọ mọlẹbi naa, gbogbo awọn ti ọrọ kan si ti lọ tọwọ bowe adehun alaafia ni ọọfisi ọlọpaa.
Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun ti Abdulazeez, ẹgbọn Toluwani sọ fub BBC.






