Ìdí rèé tí a kò fi lè gbé Ogogo lọ fún ìtọ́jú lọ́dọ̀ èèyàn tó lé ní 500 tó fẹ́ tọ́jú rẹ̀ - Jide Kosoko, Yinka Quadri

Ọmọọba Jide Kosoko lapa osi, o wọ buba ati ṣokoto alawọ ofeefe, o de fila dudu. Ogogo lo wa lapa ọtun, o wọ aṣọ dudu, pa ọwọ rẹ mejeeji pọ bo ṣe n rẹrin-in musẹ.Ogogo lo igo dudu soju pẹlu.

Oríṣun àwòrán, Prince Jide Kosoko/Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 14

Oromọ adiẹ n sunkun ìyẹ́, igba ìyẹ́ da bo adiẹ ni ọrọ da bayii fun gbajumọ oṣere, Taiwo Hassan (Ogogo), pẹlu bi awọn eeyan to le ni ẹẹdẹgbẹta (500) ṣe ti dide fun itọju rẹ, ti wọn n sọ pe ki wọn gbe e wa kawon tọju rẹ fun aisan jẹjẹrẹ to n ṣe e.

Amọ ṣaa, Ogogo ko ṣee gbe kiri bẹẹ lasiko yii bawọn to fẹẹ tọju rẹ ṣe pọ biba to.

Agba oṣere mi-in, Ọmọọba Jide Kosoko lo sọ eyi di mimọ loju opo Instagram ati Facebook rẹ l'Ọjọru.

Bakan naa, ni ọrẹ timọtimọ Ogogo lagbo tiata, Alhaji Yinka Quadri naa salaye bẹẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aje ọsẹ yii ni awọn ọmọ Ogogo meji, Kira ati Lima Hassan, fi omije kede pe baba awọn ti ni aisan jẹjẹrẹ to ti wa ni ipele kẹrin.

"A dupẹ tọkan tọkan lọwọ gbogbo eeyan to fifẹ han lati tọju Ogogo, amọ ẹ ma binu pe a ko le gbe e wa sọdọ yin"

Ninu atẹjade ti Oloye Jide Kosoko fi soju opo Instagram ati Facebook rẹ lo ti ni:

" A dupẹ tọkantọkan lọwọ gbogbo eeyan to ti fi ti ọmọniyan ṣe nipa ilera akẹgbẹ wa ọwọn, Alhaji Taiwo Babatunde Hassan, tawọn eeyan mọ si Ogogo.

" A ti ri, bẹẹ ni a ti gba ọpọlọpọ atẹjiṣẹ, adura, iyanju ati ifẹ lati ṣe iranlọwọ, a si fẹ dupẹ gidi lọwọ gbogbo yin.

" A dupẹ gidi lọwọ gbogbo eeyan to fi ara wọn silẹ lati dide iranwọ nilana ti ẹmi, ilana iṣegun oyinbo ati ni gbogbo ọna yowu."

Atẹjade naa ko ṣai mọriri awọn eeyan to ti kan sile Ogogo pe awọn le tọju rẹ nilana ẹmi, awọn to ni awọn le ṣe ti itọju ara atawọn to tun ni ọna miran ti wọn fẹ gba tọju oṣere naa.

"Ṣugbọn a fi tọwọtọwọ bẹ kaluku wa lati ma ṣe dẹkun adura ṣiṣe fun Ogogo. Ẹ jọwọ, ẹ tẹsiwaju lati maa ṣe adura pẹlu wa.

"A gbagbọ gidigidi pe pẹlu adura yin,adura tiwa ati aanu Ọlọrun alagbara, Taye yoo bori iṣoro yii layọ, Ko sohun ti ko ṣee ṣe niwaju Ọlọrun."

Bẹẹ ni atẹjade naa ka lapa kan.

Ohun kan ti Oloye Jide Kosoko tun yannana rẹ ninu atẹjade rẹ ni pe kawọn eeyan ma ṣe binu bawọn ko ba le gbe Ogogo wa sọdọ wọn fun itọju.

Ọrọ ti Ọmọọba Jide Kosoko kọ soju opo Instagram rẹ pẹlu aworan Ogogo

Oríṣun àwòrán, princejidekosoko/Instagram

""A ti ri eeyan to le ni ọọdunrun (300), koda a ti ri awọn to le ni 500, ti gbogbo wọn fi otitọ gbagbọ pe awọn le ṣe ohun ti yoo ran an lọwọ"

Jide Kosoko fikun pe "o ṣorọ pupọ fun wa bayii lati gbe e lati ile iwosan lọ si awọn aaye ọtọọtọ fun itọju, paapaa ti a ba wo iye ọpọ eeyan to ti nawọ iranwọ.

"A ti ri eeyan to le ni ọọdunrun (300), koda a ti ri awọn to le ni 500 ti gbogbo wọn fi otitọ gbagbọ pe awọn le ṣe ohun ti yoo ran an lọwọ.

" Idojukọ ta a ni ko ju pe: Nibo la fẹẹ gbe e lọ? Ati bawo la ṣe fẹẹ gbe e lati ileewosan nigba to ṣi n gba itọju lọwọ?

"Ẹ dakun a fẹ ko ye yin pe aile gbe e lọ ba ẹnikẹni ko tumọ si pe a ko mọ riri yin o, bẹẹ ni ko tumọ so pe a n ṣiyemeji lori erongba tabi ifẹ yin lati ran ṣe iranwọ."

Atẹjade naa sọ pe kaka bẹẹ, ifẹ to le kenka yii kun awọn loju ni o, bi kaluku ṣe dide si Ogogo.

Fun idi eyi, Ọmọọba Jide Kosoko rọ kaluku lati maa ṣe ohunkohun ti wọn ba mọ lati ibi ti wọn ba wa, lai jẹ pe awọn gbe oṣere naa lọ ba wọn.

Ọrọ ti Yinka Quadri kọ soju opo Instagram rẹ pẹlu aworan Ogogo

Oríṣun àwòrán, realyinkaquadri/Instagram

Ǹjẹ́ ipele kẹ̀rin àìsàn jẹjẹrẹ jẹ́ ìdájọ́ ikú bí, ṣé òògùn ìbílẹ̀ le wò ó sàn? Àlàyé rèé

Taiwo Hassan lo igo soju, o si wọ aṣọ olomi buluu to ni funfun bii labalaba ninu, bẹẹ lo fi igo soju

Oríṣun àwòrán, Ogogo Taiwo Hassan/Instagram

Àkọlé àwòrán, Ogogo

Latigba ti iroyin ti jade sita wi pe gbajugbaja oṣere tiata nni, Taiwo Hassan, ti ọpọ eeyan mọ si Ogogo ni aisan jẹjẹrẹ, ati pe, ipele kẹrin ni aisan ọhun ti de lagọ ara rẹ, ni ẹru ti n ba awọn eeyan.

Ọpọ ti ko mọ itumọ ipele kẹrin aisan jẹjẹ ni wọn ti fẹ maa sọ ireti nu, wi pe ọlọjọ ti sunmọ etile, to si jẹ kawọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye maa banujẹ.

Idi ree ti BBC News Yoruba ṣe gbiyanju lati ṣe iwadii nipa ipele kẹrin aisan jẹjẹrẹ, lati mọ boya ẹni to ba wa ni ipele yii ṣi le maa gbe ile aye pẹlu alaafia.

Eyi si ni lati fi kọ gbogbo awọn ololufẹ wa lẹkọọ nipa itumọ ohun ti ipele kẹrin naa jẹ ninu ipele aisan jẹjẹrẹ.

Kí ni ipele kẹrìn àìsàn jẹjẹrẹ túmọ̀ sí?

Gẹgẹ bi Binaytara to jẹ oju opo iroyin nipa aisan jẹjẹrẹ ṣe ṣalaye, o jẹ ko di mimọ pe ipele kẹrin aisan jẹjẹrẹ le gan-an, ṣugbọn ṣa, kii ṣe aami iku to daju bi awọn eeyan ṣe maa n lero rẹ tẹlẹ.

Bo tilẹ jẹ pe idanimọ aisan jẹjẹrẹ eyikeyi le jẹ ohun to n ba ni lọkan jẹ gidigidi, ṣugbọn sibẹ, ipele kẹrin yii maa n ni iwọn ibẹru ati inira pataki, bi okuta ti alaisan ati mọlẹbi rẹ maa n ru kiri.

Ati pe ipele kẹrin yii ati aisan to wa lati inu kii ṣe ohun kan naa.

Ipele kẹrin aisan jẹjẹrẹ jẹ ipele to buru julọ ninu arun ara, ṣugbọn eyi ko tumọ si pe a ko gbọdọ mọ riri awọn ilọsiwaju agba iyanu ti wọn n ṣe ninu itọju aisan naa, eyi to fẹrẹẹ jẹ ojoojumọ.

Awọn itọju tuntun bi eyi to n doju kọ awọn agọ ara ti oloyinbo n pe ni 'targeted therapy', imuno therapy ati radiotherapy ti goke agba, to si ti jẹ ki ọpọ awọn to n ni aisan jẹjẹrẹ maa gbe ile aye fun ọdun pipẹ, paapaa awọn to ti wa ni ipele kẹrin.

Kí ló túmọ̀ sí bí wọ́n bá rí àìsàn jẹjẹrẹ lára èèyàn?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Jẹjẹrẹ jẹ arun kan kan ti ko dara, eyi to maa n mu ki ẹya ara inu ti a mọ si 'cell' maa dagba lai le daa duro; bi jẹjẹrẹ ba ṣe n dagba sii, bẹẹ naa lo n ṣe ipalara si.

Ipele jẹjẹrẹ lo wa laaarin akọkọ si ikẹrin ni ibamu pẹlu eemọ ti wọn n pe ni 'tumor', eyi to n dagba sii, to si n tan kaakiri inu ara.

Ipele kẹrin yii lo ṣapejuwe irin ajo jẹjẹrẹ lagọ ara, leyi ti ipilẹ rẹ ti tan kaakiri awọn ẹya inu ara. Awọn jẹjẹrẹ to n dagba ninu agọ ara yii ni wọn n pe ni 'metastases', idi ree ti wọn fi n pe ipele kẹrin naa ni "metastatic cancer'.

Ipele kẹrin yii lo n ṣalaye iwa ati bi aisan jẹjẹrẹ eeyan ṣe n ri, dipo ki o jẹ iru jẹjẹrẹ kan ni pato.

Egungun, ẹdọ, ẹdọforo ni awọn ibi ti aisan jẹjẹrẹ naa maa n tan si lọpọ igba. Jẹjẹrẹ yii tun maa n tan si awọn agbegbe bii 'lymp node', eyi to jẹ akojọpọ awọn sẹẹli to n tan kaakiri ara.

Nitori itankalẹ yii, itọju aisan jẹjẹrẹ ipele kẹrin maa n nilo itọju to lagbara ati eyi to jinlẹ ju ti awọn ipele kekere lọ.

Apejuwe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọ̀nà láti tọ́jú ipele kẹrìn àìsàn jẹjẹrẹ

Mọ ohun ti ipele kẹrin tumọ si

  • Ipele kẹrin aisan jẹjẹrẹ tumọ si pe aisan naa ti tan kaakiri awọn ẹya ara inu miran
  • Awọn kokoro aisan jẹjẹrẹ keekeekee ṣi tun maa n farahan ninu ẹrọ ayaworan nnkan lẹyin ti wọn ba yọ kinni kuro
  • yiyọ jẹjẹrẹ kuro lagọ ara patapata maa n ṣoro.

Itọju naa lo naa n gbajumọ ṣiṣe odiwọn itankalẹ jẹjẹrẹ

Ipele kẹrin yii kii ṣe e tọju lọpọ igba, koda nigba ti wọn ko ba le yọ ọ kuro patapata.

  • Awọn afojusun naa ni pe:
  • Ṣiṣe odiwọn tabi ṣiṣe akoso jẹjẹrẹ.
  • Ṣiṣe odiwọn si itankalẹ jẹjẹjrẹ ninu ara.
  • Maa n ṣe iranwọ fun ẹni to ba nii lati gbe ile aye fun igba pipẹ.

Itọju naa nii ṣe pẹlu ibi ti jẹjẹrẹ ọhun ti bẹrẹ

  • Jẹjẹrẹ 'metastatic yii ni wọn lorukọ ni ibamu pẹlu ibi to wa.
  • Fun apẹẹrẹ, aisan jẹjẹrẹ ọmu to maa n tan de ẹdọforo, wọn ṣi maa n tọju rẹ gẹgẹ bi aisan jẹjẹrẹ ọmu ni, kii ṣe jẹjẹrẹ ẹdọforo.
  • Ojulowo jẹjẹrẹ lo maa n ṣapejuwe iru itọju to yẹ.

Pabambari rẹ ni pe ipele kẹrin aisan jẹjẹrẹ yii ko tunmọ si wi pe ko ni ọna tabi ilana itọju mọ.

Se oogun ibilẹ le wo aisan jẹjẹrẹ san?

Gẹgẹ bi onimọ isegun oyinbo naa se sọ, ewu nla n bẹ loko longẹ ti wọn ba lo oogun ibilẹ fun ẹni to ni arun jẹjẹrẹ.

O ni yatọ si pe awọn oogun ibilẹ yii ko ni odiwọn, o tun le da kun aisan to n se onitọhun.

Dokita onisegun oyinbo naa wa gba awọn eeyan to ba ni aisan jẹjẹrẹ lati gba itọju oogun nilana oyinbo tori awọn isẹ iwadii nipa aisan jẹjẹrẹ ti wọn ti se eyi to le se iranwọ fun alasian naa.

Ṣé lóòótọ́ ni Ogogo ti jáde láyé? Ọmọ rẹ̀ ṣàlàyé

Taiwo Hassan Ogogo wọ Damaasi alawọ aro, o de fila, o lo ilẹkẹ sọrun o si fi aago sọwọ pẹlu ilẹkẹ.

Oríṣun àwòrán, Taiwo Hassan Ogogo/ Instagram

Lẹyin ti awọn ọmọ gbajumọ oṣere tiata Yoruba nni, Taiwo Hassan (Ogogo) kede pe aisan jẹjẹrẹ ti n ba a finra, adura alaafia ni gbogbo awon ololufẹ rẹ n gba fun un.

Amọ bi eyi ṣe n lọ lọwọ naa ni iroyin kan tun gbode pe oṣere ọmọ Yewa naa ti jade laye.

Lasan kọ ni awuyewuye iku naa gba ori ayelujara lọsan ọjọ Iṣẹgun ti i ṣe ọjọ keji ti Kira ati Lima kede aarẹ to n ṣe baba wọn,.

Lima ọmọ ogogo keji lo sare gbe ọrọ kan to kede iku naa soju opo Instagram rẹ, nigba naa si ni ariwo iku naa gbode.

Bo tilẹ jẹ pe Lima Taiwo ko jẹ ko pẹ rara to fi pa ohun to kọ soju opo naa rẹ, sibẹ, awọn aye ti ri i, wọn si ti bẹrẹ si i pin in ka.

Eyi lo fa a ti ọpọ eeyan fi n wadii otitọ, lati mọ boya oṣere ti ọpọ eeyan fẹran naa ti dagbere faye loootọ ni.

Ki ni ọmọ Ogogo kede?

Ọrọ mẹfa naa ni Lima Taiwo Hassan kọ soju opo naa lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii to fi kede ipapoda baba rẹ.

Ohun to kọ naa ree: Wọn ti pada lọ, sun ire baba.

Ọmọbinrin naa tun fi awọn ami to n ṣafihan ẹkun sibi ikede ọhun, o si fi ami ifẹ pari rẹ.

BBC News Yoruba pe Lima lori aago lẹyin eyi lati fidi atẹjade naa mulẹ, amọ aago rẹ ko lọ.

Bakan naa ni awọn eeyan kan ti bẹrẹ si i sọ pe Lima kọ lo gbe ọrọ naa si oju opo rẹ, wọn ni o ṣee ṣe ko jẹ ọgbọn arekereke ori ayelujara ni awọn kan ṣe lori ikede naa.

Amọ lati fi idi otitọ mulẹ, BBC News Yoruba kan si Olori TAMPAN, Bolaji Amusan (Mr Latin), ẹni to dahun pe oun ko fẹẹ sọ ohunkohun lori rẹ.

Eyi ni a ṣe pe ọlọpaa inu fiimu, Ọgbẹni Owolabi Ajasa to jẹ Gomina fun ẹgbẹ TAMPAN nipinlẹ Ogun, oun si da wa lohun pe:

Ikede iku Ogogo ti ọmọ rẹ obinrin gbe sori ayelujara

Oríṣun àwòrán, limataiwo_/Instagram

Emi ati Olu Ayinde, tii se aburo Ogogo sẹsẹ sọrọ tan laipẹ yii ni, ko si ohun to jọ pe ẹgbọn rẹ ti jade laye - Owolabi Ajasa

Owolabi Ajasa, Gomina TAMPAN Ogun, o wọsọ ọlọpaa alawọ aro o si de fila dudu

Oríṣun àwòrán, Owolabi Ajasa/ Facebook

Àkọlé àwòrán, Owolabi Ajasa

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Owolabi Ajasa ni iroyin naa ko ri bẹẹ rara.

"Emi ati Olu Ayinde, tii se aburo Ogogo sẹsẹ sọrọ tan laipẹ yii ni, ko si ohun to jọ pe ẹgbọn rẹ ti jade laye.

''To ba jẹ pe lootọ ni Ogogo ti dagbere fun aye, aburo wọn ko ba ti sọ fun mi.

"Emi ko si lọdọ Ogogo, n ko si ri i tabi mọ ipo to wa, tori naa, n ko le fidi rẹ mulẹ, amọ loore koore ni emi ati aburo wọn naa n sọrọ nipa ipo ti ilera wọn wa."

Bẹẹ ni Owolabi Ajasa ṣalaye.

Ṣugbọn nigba ti yoo fi di irọlẹ ọjọ Iṣẹgun naa, Lima Taiwo naa pada sọrọ, o ni iroyin ofege ni pe baba oun ku, ki awọn to n pin in kiri yee ṣe bẹẹ.

Lima sọ pe Ogogo ṣi wa laye, ki ẹnikẹni yee pin iroyin iku rẹ kiri.

Ta ni Taiwo Hassan Ogogo?

Ọjọ kọkanlelọgbọn osu kẹwa ọdun 1959 ni wọn bi Taiwo Hassan, ti ọpọ eeyan mọ si Ogogo.

Ọmọbibi ilu Ilaro, to wa ni agbegbe Yewa nipinlẹ Ogun nii se, to si jẹ ibeji, tori ibeji ni wọn saba maa n bi ninu idile rẹ.

Bakan naa ni baba ati iya rẹ naa jẹ ibeji.

Ogogo pari ile ẹkọ alakọbẹrẹ rẹ nile ẹkọ Christ Church nilu Ilaro, ko to morile ile ẹkọ girama Gazikia College nilu Eko.

Amọ Ogogo ko le pari ile ẹkọ girama naa tori ọda owo, lẹyin naa lo wa lọ sile ẹkọ ẹkọsẹ ọwọ nibi to ti kọ nipa isẹ atọkọse, ti a mọ si Mẹkaliki.

Gbajumọ osere tiata naa si sisẹ bii Mẹkaliki fun ọdun mẹtala gbako nileesẹ to n pese omi, water corporation.

Ogogo bẹrẹ isẹ tiata lọdun 1981 ni kete to bẹrẹ isẹ mẹkaliki, to si kuro lẹnu isẹ mẹkaliki nileesẹ Water Corporation lọdun 1994, ko le gbajumọ isẹ tiata to yan laayo.

Agba osere naa ti gba oniruuru ami ẹyẹ nidi isẹ tiata, to si tun gba ami ẹyẹ ipa to ko ninu ere Anikulapo, tii se Alaafin Oyo.

Àgbà òṣèré, Taiwo Hassan Ogogo ni àìsàn jẹjẹrẹ, a ń wá dókítà òyìnbó tàbí tí ìbílẹ̀ to le wò ó sàn - Àwọn ọmọ rẹ̀ figbe ta

Ogogo àti ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Collage

Gbogbo ẹ̀dá lọ máa ń gbàdúrà fún ìlera pípé láti gbé ilé ayé àmọ́ bí àìsàn bá dé, yóò kó ìpayà àti ìbànújẹ de.

Gbajugbaja ọṣèré tíátà ni èdè Yorùbá, tí ọ̀pọ̀ èèyàn nifẹ rẹ, Taiwo Hassan, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Ogogo lọ tí ń ṣàìsàn to lágbára báyìí.

Àìsàn náà sì lo ni ṣe pẹ̀lú àìsàn jẹjẹrẹ.

Ọmọ Ogogo lobinrin, Shakira Taiwo lo fi Ikede yii síta pẹ̀lú ẹkún ńlá nínú fídíò kan tó ṣe láti fi béèrè fún ìrànwọ́.

Fídíò náà sì lo gbé síta lójú òpó Instagram rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí Shakira ṣe ń fi omijé ṣe àlàyé, ó ní àìsàn jẹjẹrẹ ọhun tí de ipele kẹrin.

"Ìdí sì nìyí tí àwọn dókítà ṣe sọ pé pé àwọn kò lè fún ní ìtọ́jú tí àwọn máa ń fún àwọn èèyàn tó bá ní àìsàn jẹjẹrẹ, tí a mọ̀ sí 'Chemotherapy' mọ."

Shakira Taiwo tẹsiwaju nínú ọ̀rọ̀ rẹ pé òun ko se fídíò náà láti fi tọrọ owo lọ́wọ́ ẹnikẹni.

O fikùn pé olùdíje sípò gomina lábẹ́ Asia ẹgbẹ́ òṣèlú APC nipinlẹ Ogun, Senatọ Solomon Adeola, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Yayi, lo tí ń gbọ́ bukata ìnáwó lórí àìsàn baba òun.

O wa dúpẹ́ lọ́wọ́ àgbà oloselu náà fún ọwọ́ àànú to n na si Ogogo.

Shakira wá sísọ lójú rẹ pé "Mo ń wá àwọn onisegun to lè tojú baba mi bayi lọ́wọ́ àìsàn jẹjẹrẹ.

Bóyá àwọn onisegun oyinbo ni tàbí tí ìbílẹ̀.

Ẹ jọ̀ọ́ torí Ọlọ́run, bàbà mi kò fẹ́ kú, kò fẹ́ kú" Ọmọ Ogogo lọ ń fi ẹkún rawọ ẹ̀bẹ̀ sáwọn aráàlú náà."

Bákan náà ni Shakira ni inú ìrora ńlá ni bàbá òun wà báyìí, ẹnikẹ́ni tó bá sì lè wo àìsàn jẹjẹrẹ náà san, kí wọ́n kan sì òun tàbí àbúrò òun.

Bákan náà ni Shakira fi sita pé ó yẹ kí àgbà òṣèré náà tí lọ sí ilẹ̀ india fún ìtọ́jú àmọ́ kò le wọ bàálù torí àìsàn náà tí wọ ọ lára.

Ọmọ Ogogo, Shakira ń wá 3kun mú, ó wọ aṣọ kaba aláwọ̀ búlúù

Oríṣun àwòrán, Kira_Taiwo/Instagram

A kò mọ pé Baba mi ni àìsàn jẹjẹrẹ, ọṣẹ kẹta rèé tí a mọ̀ - Haleemah Taiwo

Bákan náà ni ọmọbìnrin Ogogo miran, Haleemah Taiwo náà ṣe fídíò miran, tí òun náà ń fi omijé sọ̀rọ̀ láti béèrè ìrànwọ́ ọwọ́.

"Baba mi nifẹ lati gbe ile ayé, kò tètè mọ pe oun ni àìsàn jẹjẹrẹ àmọ́ ó ti tàn ka ara rẹ.

Ọ̀sẹ̀ mẹta sẹ́yìn rèé tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ pe o ni àìsàn náà, táwọn dókítà sì lo tí kọjá ìtọ́jú.

A wá ń bẹ ẹnikẹ́ni to bá lè tojú rẹ, láti kan sì wà, a kò fẹ́ kí baba wá kú ó. "

Gbogbo àwọn ọṣèré tíátà bíi Toyin Abraham, Dayo Amusa àtàwọn míì sì lo n se alábàápín àwọn fídíò tí àwọn ọmọ Ogogo náà ṣe.

Wọn wá ń rọ àwọn onímọ̀ oyinbo àtàwọn onisegun ìbílẹ̀ to bá gbowọ, tí wọn lé wo àìsàn jẹjẹrẹ láti kan sì àwọn lórí aago.

Ọmọ Ogogo, Haleemah Taiwo náà ń sunkún láti bẹ̀bẹ̀ fún ìrànwọ́ aráàlú láti wá dókítà fún ìtọ́jú baba rẹ

Oríṣun àwòrán, Limataiwo_