A sa gbogbo ipá wa láti gba ẹ̀mí Ogogo là – Yayi

Oríṣun àwòrán, Facebook/Ogogo/Yayi
Oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinẹ Ogun, Sẹnetọ Olamilekan Adeola, ti inagijẹ rẹ n jẹ Yayi ti sọ pe oun ati idile oun duro ti oṣere tiata to di oloogbe, Taiwo 'Ogogo' Hassan lasiko to n ṣaisan ko to jade laye.
Yayi lo sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Facebook rẹ lati ṣe idaro oloogbe naa lẹyin ti iroyin iku rẹ gbode.
Ninu atẹjade ọhun, ti oun ati iyawo rẹ, Temitope Adeola buwọlu, o ni iroyin iku Ogogo da omi tutu sọkan awọn, o si jẹ inbanujẹ nla fun wọn.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, idilẹ rẹ duro ti Ogogo lasiko to dubulẹ aisan pẹlu ireti pe yoo pada gbadun ki aisan ọhun to ja si iku.
O juwe Ogogo gẹgẹ bii ibatan oun lati ilu Ilaro ati eeyan pataki ni gbogbo agbegbe iwọ oorun ipinlẹ Ogun.
Lẹyin naa lo tun ba iyawo Ogogo atawọn ọmọ rẹ kedun iku ọkọ ati baba wọn, to fi mọ gbogbo ọmọ bibi ilu Ilaro lapapọ.
O pari atẹjade naa pẹlu adura pe ki Eledua fori aiṣedede rẹ jin in ko si tẹ si afẹfẹ rere.
Ana ọjọ Aiku ni Ogogo fi aye silẹ lẹyin to ti kọkọ ba aisan jẹjẹrẹ finra.
Wọn ti sin oku rẹ bayii ni ilana ẹsin Musulumi niluu Ilaro to wa nipinlẹ Ogun.
"Má sunkún, ọmọbabìnrin mi, ẹkún rẹ ń bà mi lọ́kàn jẹ́, ẹ̀rín rẹ ń ró mi lágbára", Ogogo sọ̀rọ̀ ìkẹyìn f'ọ́mọ rẹ̀ ṣáájú ikú

Oríṣun àwòrán, Kira Taiwo Hassan/Instagram
Ọjọ a ku la a dere, eeyan o sunwọn laaye.
Lati ana ọjọ Aiku ti iroyin iku agba oṣere, Taiwo Hassan (Ogogo) ti gbode ni ọrọ idaro ti n pe ara wọn ran niṣẹ lori ayelujara.
Tolori-tẹlẹmu lawujọ, titi to fi mọ awọn araalu paapaa ni wọn ti n fi ibanujẹ ọkan han si bi Ogogo, ọkunrin rọgbọdọ bii ewe ìgbá ṣe jade laye lojiji lai si apẹẹrẹ iku lara rẹ ṣaaju jẹjẹrẹ to mu un lọ lẹni ọdun mẹrindinlaadọrin (66).
Lara awọn eeyan to ti kẹdun Ogogo ti wọn si ti sọrọ idaro ni Ijọba ipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Olamilekan Adeola (Yayi), Omoyele Sowore, awọn onitiata bii Ogogo titi to fi mọ ọmọ rẹ to kede lọsẹ to kọja pe Jẹjẹrẹ ti mu baba awọn.
Aṣe bi aisan naa ṣe n wọ ọ lara, ti awọn ọmọ rẹ si ti n ba ọkan jẹ ni Ogogo ti n fi ohùn silẹ fawọn ọmọ naa, eyi si ni Kira,ọkan lara awọn ọmọ rẹ to kede aarẹ naa gbe jade bayii, pe Ogogo sọ foun ṣaaju iku.
'Bi o ba n sunkun, yoo maa ba mi lọkan jẹ, ma sunkun, ọmọbabinrin mi "
Kira Taiwo, ọkan lara awọn ọmọ Ogogo to kede pe jẹjẹrẹ ti mu baba awọn naa sọrọ lori iku baba rẹ.
Kira gbe ọrọ ti baba rẹ sọ fun un lọjọ kẹrindinlogun oṣu Keje ọdun 2026 yii jade, nibi ti Ogogo ti n mu ọmọ naa lọkan le.
Bi Kira ṣe e gbe e jade, Ogogo sọ pe:
"Bawo ni, mo gbọ pe o n sunkun, ẹ̀rin iwọ atawọn aburo rẹ ti mo n ri n mu ara mi le. Ti ẹ ba n ke, o maa ba mi lọkan jẹ, ma a dẹ maa ronu."
Oloogbe naa tẹsiwaju ninu ọrọ naa pe:
"Ẹ mu ọkan le, emi naa n mọkan le. Ko si nnkan to maa ṣe mi lagbara Oloun. To ba ri bẹẹ, ma sunkun, ọmọbinrin mi."
Kira naa da baba rẹ lohun pe oun ko sunkun o, ki baba ma da aburo oun Haleemah loun.
Oṣu kan ati diẹ lẹyin ọrọ naa ni Ogogo jade laye.
Gomina Dapo Abiodun: Adanu nla ni iku Ogogo jẹ fun ipinlẹ Ogun ati Naijiria lapapọ-
Ọmọọba Dapo Abiodun ti i ṣe gomina ipinlẹ Ogun naa ti fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ lori iku Ogogo, Abiodun sọ pe adanu nla ni iku oṣere naa jẹ fun ilu Ilaro, Yewa, ipinlẹ Ogun ati Naijiria patapata.
Dapo Abiodun ṣapejuwe Ogogo bii ẹni ti iṣẹ rẹ mu ayọ wa fun aimọye eeyan, atẹni to fi iṣẹ rẹ gbe aṣa Yoruba larugẹ.
Sẹnetọ Adeola Solomon (Yayi)
Yayi to n dupo gomina Ogun ninu ẹgbẹ oṣelu APC sunmọ Oloogbe Ogogo pupọ nigba aye rẹ, Ogogo paapaa si ti n polongo ibo fun un ki iku ojiji yii too de.
Yayi ti awọn ọmọ Ogogo dupẹ lọwọ rẹ fun inawo itọju Oloogbe, daro iku naa pẹlu alaye pe ibanujẹ nla ni iku Ogogo to da bii ẹgbọn si oun.
O ni Ogogo ṣiṣẹ pupọ lojuna oṣelu toun gbe dani, amọ ohun gbogbo ye Oluwa.
Omoyele Sowore: "Ara ọtọ oṣere ni Ogogo, to ba de, awọn eeyan yoo mọ pe o de ni, ko siyemeji nipa rẹ lori itage.
" Mo gbadura pe ko sinmi ninu agbara, ki agbara naa si maa wa pẹlu rẹ."
Wasiu Ayinde: Lori itage ti gbajumọ onifuji; Alhaji Wasiu Ayinde ti n kọrin lo ti bu sẹkun lori iku Ogogo.
Ọjọ Aiku ti Ogogo ku gan-an ni Wasiu wa lode orin to si fi orin daro Ogogo, o figba kan kọyin si itage naa, o mu aṣọ inuju rẹ, o si bẹrẹ si i fi nu omije to n jade.
Femi Adebayo bu sẹkun nibi to ti n sọrọ lori iṣẹ ti Ogogo ṣe gbẹyin
Ṣaaju ni Femi Adebayo toun naa jẹ gbajumọ oṣere ti kọ ọrọ idaro lori iku Ogogo, o dupẹ lọwọ Oloogbe naa fun ipa to ko ninu aye rẹ, ati bo ṣe jẹ koun nifẹ iṣẹ sinima.
Amọ lasiko ti Femi Adebayo n sọrọ nibi ere kan ti Ogogo ṣe gbẹyin, o ni Ogogo ja fitafita lori aisan to ṣe e naa, o si jagun alaafia gidi.
Lojiji ni Femi tu puru sẹkun, fidio ẹkun naa si ti gba ori ayelujara kan.
Odunlade Adekola: Loju opo Instagram ni oṣere yii fi idaro rẹ si, o kọ pe:
"Akọni ni titi dọjọ ikẹyin rẹ. O daarọ. Akọni nla"
Saidi Balogun: Loju opo Instagram ni oṣere yii naa ti daro pe:
"O le sinmi bayii, ẹgbọn mi Taiwo Hassan Ogogo. K'Ọlọrun Alagbara Allah ṣe atọna rẹ de Aljannah. Eyi dun ni gan-an."
Bolanle Ninalowo: "Oriire nla ni mo ṣe pe mo mọ yin, mo si tun ṣiṣẹ pẹlu yin. Baba Ogogo. Sun ire, Akọni. Ẹ ṣeun ti ẹ lana fun mi ati ọpọ eeyan mi-in.
Bimbo Thomas: Ọkan lara awọn oṣere to sunmọ Oloogbe Ogogo daadaa nigba aye rẹ ni Bimbo Thomas, ẹkun ni obinrin yii n wa mu lori Instagram bo ṣe n sọ pe :
"Eyi buru pupọ. Ami ara o tiẹ sọ mi rara, aṣeyi to wu u ni Ọlọrun."
Kira Taiwo: Ọmọ Ogogo sọ̀rọ̀ lórí àwọn tó fẹ́ fi ìtọ́jú bàbá rẹ̀ pawó ńlá, àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, Kira Taiwo/ Facebook
Lẹyin fidio to ṣe lọsẹ to kọja lati kede pe Taiwo Hassan (Ogogo) ti ni aisan jẹjẹrẹ to wa ni ipele kẹrin, ọmọ oṣere naa; Shakira Taiwo, ti ṣe fọnran miran, nibi to ti ni awọn eeyan kan n gbiyanju lati fi idile Ogogo pawo nitori aisan naa.
Lori ẹka Tiktok ni Kira ti kede eyi lọjọ Abamẹta.
O ni awọn eeyan naa n yọju pe awọn fẹ tọju Ogogo, awọn ni oogun Jẹjẹrẹ lọwọ, amọ owo to le sọ idile awọn di ẹdun arinlẹ ni wọn n beere.
"Awọn kan n beere N800k, N5m, 11,000 dollars, N18,000 dollars"
Ninu fidio naa ni Kira ti sọ pe:
"Awọn eeyan kan n gbiyanju lati fi wa pawọ niru ipo yii, ẹ bẹru Ọlọrun.
"Eyi a wa, a beere N800k, N5m, 11,000 dollars, N18,000 dollars. Ṣe ẹ fẹ sọ wa dẹni ti ko lowo lọwọ ni? A ki i ṣe biliọnia."
Ọmọ Ogogo sọ pe idile awọn ko ni iru owo bẹẹ, o ni ohun to jẹ awọn logun ni kawọn ri itọju fun baba awọn.
Shakira Taiwo tun sọ pe oun paapaa ko fi gbogbo ara ni alaafia lasiko yii nitori ọrọ baba oun yii.
"Mo fẹ yẹ ifunpa mi wo, ara temi naa ko ṣe daadaa."
Ọ tun ṣalaye bi aarẹ Ogogo ṣe n nipa lara ẹgbọn oṣere naa to pe ni Big Daddy.
Kira sọ pe niṣe ni baba naa n beere pe ṣe Taiwo (Ogogo) yoo ku ni.
O fi kun un pe baba naa funra rẹ ko ni ilera pipe mọ latigba ti ọrọ aburo rẹ ti ṣẹlẹ.
O sọrọ nipa owo ti idile naa fi n ra oogun ara riro fun Ogogo bo ṣe wọn to, to jẹ eyi to kere ju ninu rẹ bẹrẹ lati ẹgbẹrun lọna aadọta naira (50,000) soke.
Shakira ni baba daadaa ni baba oun, amọ ailera to n koju yii ko tiẹ fẹ jẹ koun le wo oju rẹ.
O ni bi Oluwa ṣe n ṣe nnkan rẹ, Eledumare naa lo ye, amọ oun n wa iyanu ti yoo ṣẹlẹ, ti alaafia yoo fi pada sara Ogogo.
Ohun to ṣẹlẹ ṣaaju
Ọsẹ to kọja yii ni awọn ọmọ Ogogo meji, Kira ati Lima Taiwo, ke gbajare lori ayelujara, pe baba awọn ti ni aisan jẹjẹrẹ to ti wa ni ipele kẹrin.
Wọn fi omije rawọ ẹbẹ sawọn ọmọ Naijiria, pe ki wọn dide iranlọwọ nipasẹ oogun ibilẹ, to ba si ṣe ti oloyinbo to daju naa ni.
Awọn ọmọ naa sọ pe awọn dokita oyinbo ni ko fẹ tọju Ogogo mọ, lo jẹ kawọn jade beere ọna mi-in.
Wọn sọ nigba naa pe awọn ko ba tilẹ gbe e lọ si India fun itọju, amọ ilera rẹ ko gbe irinajo naa mọ.
Kira ati Lima sọ nigba naa pe awọn ko tọrọ owo o, iranlọwọ ni gbogbo ọna miran lawọn tori ẹ wa sori ayelujara.
Ko ju ọjọ meji lẹyin ikede naa, ti okiki kan pe Ogogo ti jade laye latari aisan naa, amọ irọ gbuu ni eyi pada jẹ.
Opin ọsẹ to kọja yii si ni awọn agba oṣere lagbo tiata Yoruba korajọ, ti wọn ṣe adua nilana ẹsin Islam fun Taiwo Hassan; gbajumọ oṣere tawọn eeyan mọ si Ogogo.


























