You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iléeṣẹ́ ọmọ ogun Naijiria àti Amẹrika gbẹ̀mí igbákejì ẹgbẹ́ ISIS, Abu-Bilal al-Minuki
Ijọba apapọ ti fidi rẹ mulẹ pe ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ ologun ilẹ Amẹrika ti ṣekupa Abu-Bilal al-Minuki, to jẹ olori ẹgbẹ agbesunmọmi ISIS.
Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lo fidi eyii mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede laarọ ọjọ Abamẹta.
Ọrọ yii lo n jẹyọ lẹyin ti Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump ti kọkọ kede igbesẹ naa.
Ninu ọrọ Tinubu, o ni orumọju ni wọn gbẹmi olori ẹgbẹ alakatakiti ọhun.
Nigba ti Aarẹ Trump n juwe Abu-Bilal al-Minuki, o ni oun ni igbakeji ẹgbẹ ISIS kaaliri agbaye.
Ki ni Tinubu sọ?
Ninu ọrọ to fi lede loju opo Facebook rẹ, Tinubu sọ pe gbigbẹmi olori agbesunmọmi naa n ṣapejuwe ibaṣepọ to wa laarin ijọba Naijiria ati Amẹrika lati rẹyin igbesunmọmi.
O ni "Awọn ọmọ ogun wa pẹlu ajọṣepọ pẹlu awọn ọmọ ogun ilẹ Amẹrika, kọju ija to lagara si ẹgbẹ Islamic State.
"Ayẹwo lẹyin ikọlu naa fidi rẹ mulẹ pe a ti ṣekupa olori ẹgbẹ ọhun ti wọn ti n wa fun ọjọ pipẹ, Abu-Bilal Al-Manuki, ti inagijẹ rẹ n jẹ Abu-Mainok, toun ti ọpọ awọn ẹmẹwa rẹ lẹyin ado oloro sinu ọgba wọn to wa ni Lake Chad Basin.
"Naijira mọ riri ajọṣepọ rẹ pẹlu Amẹrika lori ọrọ yii. Mo si dupẹ gidigidi lọwọ Aarẹ Trump fun idari ati atilẹyin rẹ lori igbiyanju yii.
"Mo tun gboriyin fun awọn ọmọ ogun to ṣiṣẹ ni iha mejeji, mo si ni afojusun pe a tun maa kọlu ọpọ ibuba awọn agbesunmọmi mii kaakiri orilẹede yii."
Ki ni Aarẹ Trump sọ?
Ninu ọrọ Aarẹ Trump lo ti kede pe ileeṣẹ ọmọ ogun orilẹede mejeji ti ṣaṣeyọri lati gbẹmi ogboju agbesunmọmi ọhun.
O ni olori agbesunmọmi naa ni "Abu-Bilal al-Minuki, to jẹ igbakeji ẹgbẹ ISIS kaakiri agbaye, to ro pe oun le lọ farapamọ si Afrika…."
Trump sọ pe Abu-Bilal al-Minuki ko ni le maa ṣeruba awọn eeyan Afrika mọ bayii lẹyin to ti gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.
Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ ijọba Naijiria fun ibaṣẹpọ rẹ lati rẹyin Abu-Bilal al-Minuki.