Tani Olorun àti Sunday Igboho ni wọ́n jẹ́ ọ̀daràn tó tako òfin iléẹjọ́, ojúlówó ni ìwé àti ọlọ́pàá tó fẹ́ mú n‘Ibadan - US Imam

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii ni igbẹjọ miran tun waye lori ẹsun ti Ilorin Heritage Foundation, IHF, fi kan gbajumọ ẹlẹsin ibilẹ nni, Azeez Adegbola, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Tani Olohun.
Nibi igbẹjọ naa si ni agbẹjọro to duro fun IHF, Umar Sa'ad Imam ati Amofin Muftar, to duro fun Tani Olorun, ti yọju sile ẹjọ giga to wa ni Upper Area nilu Ilorin.
Lẹyin igbẹjọ naa ni awọn agbẹjọro mejeeji yii se fidio lati se alaye ohun to waye nibi igbẹjọ ọhun.
Agbẹjọro fun IHF, Imam wa lo anfaani akoko naa lati sọrọ nipa isẹlẹ to waye nilu Ibadan, lasiko ti awọn ọlọpaa lọ duro fun Tani Olorun.
"A tẹ̀lé ìlànà òfin láti gbé Tani Olohun"
Ṣugbọn nigba to n sọrọ lẹyin igbẹjọ to waye ni ọjọ Isegun, agbẹjọro Ilorin Heritage Foundation, Umar Sa'ad Imam sọ pe awọn gbe gbogbo igbesẹ to yẹ lati rii daju pe awọn tẹle ofin, ko to di pe ọlọpaa lọ gbe Tani Olohun.
Imaam sọ pe gbogbo awọn to n sọrọ lori ayelujara, paapaa awọn to n gbe lẹyin Tani Olohun ko mọ nnkan ti wọn n sọ ni, nitori pe ọrọ ko ye wọn.
"Awọn to sọ pe ayederu ni iwe ipe ti a fi lọ gbe Tani Olohun ko mọ nnkan ti wọn n sọ ni, nitori pe a ti mọ iru awọn ọdaran ti a n ba dowopọ.
Idi ree to fi jẹ pe gbogbo ohun to yẹ ka ṣe labẹ ofin la ṣe," Imam sọ bẹẹ fawọn akọroyin.
"Awọn kan lọ ṣe ayederu iwe, ti wọn sọ pe agbẹnusọ ọlọpaa sọ pe ayederu ni iwe ti a ṣe.
Wọn ko jẹ ka ri iwe iroyin to gbe e, igba ti a ka ohun ti wọn gbe jade naa, la rii pe Ajayi Okasanmi, to ti fẹyin ti lati bi ọdun kan le sẹyin, ni wọn n sọ.
"Wọn ko mọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti ni agbẹnusọ miran, Adetoun Ejire, wọn ro pe bi awọn ṣe jẹ ọdaran, naa ni awa naa jẹ ọdaran bii ti wọn.
"A fi n da gbogbo aye loju pe iwe ti wọn lọ fi gbe Tani Olohun ati gbogbo awọn ti wọn lọ, ati awa ti a ran wọn niṣẹ, ojulowo ni gbogbo wa," Imam fidi rẹ mulẹ.
"Ọ̀daràn ni Sunday Igboho" - Imam
Bakan ni agbẹjọro Imam sọ ninu ọrọ pe ọdaran ni Tani Olohun ati gbogbo awọn to n gbe lẹyin rẹ, to fi mọ Sunday Adeyemo, ẹni tọpọ mọ si Sunday Igboho.
"Ile-ẹjọ sọ pe ka fun un niwe lati ori ayelujara, ka si fi iwe ipẹjọ naa sinu iwe iroyin, a si ti ṣe gbogbo rẹ.
"Oun naa ti fidi rẹ mulẹ ninu awọn fọnran to ṣe wi pe oun ni ẹjọ lati jẹ nile-ẹjọ.
Awọn mọlẹbi rẹ gan-an fidi rẹ mulẹ, ti gbogbo wọn mọ ọjọ ti igbẹjọ yoo waye.
"Ohun to ṣẹlẹ yii kii ṣe ọrọ ọga ọlọpaa kan ti yoo jokoo si ọfiisi rẹ lati maa sọrọ, ọrọ ile-ẹjọ ni.
Ohun to yẹ ki wọn ṣe tẹlẹ ni wọn ṣẹṣẹ ṣe yii.
"Emi tiẹ ro pe ọga ọlọpaa ipinlẹ Oyo ni yoo lewaju wọn wa lonii, lati wa gbẹnusọ fun Tani Olohun, nitori pe o ti wa lẹyin wọn bayii.
"Ọdaran ti ile-ẹjọ ni ka lọ mu wa, pẹlu awọn ọdaran bii tiẹ yooku bii Sunday Igboho ni wọn ti tako ofin ile-ẹjọ.
A ni ile-ẹjọ ko gbọdọ gbọ wọn, ṣugbọn ile-ẹjọ sọ ohun yoo gbọ wọn, wi pe ka mu ọjọ.
A si fẹnuko si ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹsan, ọdun 2026."
"Awa ti iṣẹlẹ yii ko dun mọ, a mọ ara wa, awọn to dun mọ ni wọn n lọ ṣe ipade pẹlu wọn, a ko si le ma ri iru rẹ.
Gbogbo awọn to ko ara wọn jọ, la maa gbe sare papọ." Imam kadi ọrọ rẹ nilẹ
"Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti dúró fún Tani Olohun" - Agbẹjọ́rò Muftar
Agbẹjọro Muftar to ṣoju fun Tani Olohun sọ pe ṣaaju ọjọ naa ni awọn ti gbe iwe ipẹjọ dide lati tako ẹsun ti awọn Ilori Heritage Foundation fi kan Azeez Adegbola
"O yẹ ka ti gbọ abajade iwe ipẹjọ wa, ṣugbọn a ko tii gbọ nnkankan, ṣugbọn wọn n sọ nile-ẹjọ pe awọn ni ọjọ mẹrinla lati dahun, a si gba si wọn lẹnu," Muftar sọ bẹẹ.
"Ile-ẹjọ ni awọn naa ni asiko lati tako iwe ipẹjọ naa, awa naa si gba.
"Nipa iwe ti wọn ni ki wọn lọ fi gbe Tani Olohun, mi o fẹẹ sọrọ pupọ lori rẹ, nitori awọn nnkan to si rọ mọ ọn ni.
"A ko gbọ ohunkohun nigba ti wọn fẹ lọ gbe Tani Olohun, wọn ko sọ fun wa, igba to di pe wọn ko rii gbe, wọn ṣẹṣẹ n sọrọ sita.
"Ọrọ Azeez Adegbola Tani Olohun kii ṣe nnkan tuntun si emi, mo ti duro fun un laimọye igba. Gbogbo agbaye lo mọ pe ki alaafia le jọba lorileede ni emi n ja fun.
"A kò mọ ìdí tí wọ́n fi fẹ́ gbé Tani Olohun"
Bakan ni Agbẹjọro Muftar jẹ ko di mimọ pe awọn ko mọ idi pataki ti wọn fi fẹẹ gbe Tani Olohun, nitori pe awọn ko ri iwe ti wọn sọ pe ile-ẹjọ fi paṣẹ lati lọ gbe e wa.
"Ti wọn ba sọ pe wọn gbe iwe dide lati lọ gbe Tani Olohun, a ni lati mọ idi pataki, titi di asiko yii, a ko mọ idi ti wọn fi fẹ lọ gbe Tani Olohun.
"Emi kọ ni wọn pe fun ẹjọ yii latilẹ, Oga mi to tun jẹ ọrẹ mi, O.A Fatoki ni wọn gbe ẹjọ naa fun, ṣugbọn nitori ko si nile lo ṣe ransẹ pe emi lati wa duro fun un.
"Lọjọ ti ile-ẹjọ sun igbẹjọ si ni wọn yoo fidi rẹ mulẹ nipa awọn to pe ẹjọ ti awa tako pe ile-ẹjọ ko ni agbara lati gbọ ẹjọ naa"
Ki lo ti waye saaju nipa igbẹjọ Tani Olorun?
Ko si nnkan meji to jẹ ki awọn IHF wọ Tani Olohun lọ sile-ẹjọ, bi ko ṣe ti bi wọn ṣe sọ pe o n sọrọ tako ẹsin Islam, eyi ti wọn lawọn yoo ba a na-an tan bi owo labẹ ofin.
Ọsẹ to kọja ni awọn ọlọpaa kan ti wọn ko wọ aṣọ gbiyanju lati lọ gbe Tani Olohun nile rẹ to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo, ṣugbọn ti erongba wọn pada ja si ofo.
Ṣaaju asiko naa ni Tani Olohun sọ pe Emir ilu Ilorin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari ti yọwọ rẹ kuro ninu ẹjọ naa, ati pe ko ni ohunkohun lati ṣe lori ẹjọ ti wọn pe oun.
Ninu fọnran ti Tani Olohun gbe soju opo ayelujara ti Facebook rẹ, sọ pe agbẹjọro to n fi ẹwọn dunkooko mọ oun, ko mọ nnkan to n sọ, nitori pe ẹjọ ti ko lẹsẹ nilẹ lo n sọrọ le lori.
Oniruuru awuyewuye lo ti waye lori ayelujara nipa iwa ti awọn ọlọpaa hu, pẹlu bi wọn ṣe fẹ fi tipatipa gbe Tani Olohun lọ siluu Ilorin.
Bi awọn kan ṣe n tako igbesẹ awọn ọlọpaa, naa ni awọn miran n sọ pe ọkunrin to n tako ẹsin ọhun ko nii lọ lai jiya, ti awọn miran si n sọ pe ọna ẹburu ni wọn fẹẹ gba gbe Tani Olohun.



























