Kò sí ẹni tó gbà mí gbọ́ pé mi ò kì ń mu sìgá tàbí fa igbó gẹ́gẹ́bí akọrin Fuji - Yeye Qibla onimama

Àkọlé fídíò, 'Ẹ̀bùn ni orin Fuji fún mi'
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ẹya orin to gbajumọ kaakiri agbaye ni orin Fuji jẹ, ọpọlọpọ ọdun lo si ti gbilẹ kaakiri to fi di eyi ti ọpọlọpọ n kọ ti wọn si ni ifẹ si.

Awọn ọkunrin lo pọ ju ni idi orin yii ti ọpọ si maa n wo o pe awọn ti ko kawe lo n kọ orin Fuji, bi o tilẹ jẹ wi pe eyi ti yipada pẹlu bi o ti ṣe jẹ pe awọn onifuji pẹlu ti n kawe gboye bayii.

Lara awọn obinrin to n da bi ẹdun rọ bi owe lagbo Fuji lode oni yii ni Yeye Qibla Onimama.

O ba BBC News Yoruba sọrọ lori irinajo rẹ ninu orin Fuji kikọ.