'Aago meji oru ni mo dele; ọ́fíìsì ni màá sùn lọjọru' - aráàlú kojú ìnira, ìdádúró ọ̀pọ̀ wákàtí lópópónà Eko sí Ibadan nítorí àtúnṣe afárá Kara, ìgbà tí yóò parí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ arinrinajo ati awakọ to n gba oju ọna marosẹ Eko si Ibadan lo fi oru wọ ile wọn lọjọ Iṣẹgun latari atunṣe afara Kara to ṣokunfa sunkẹ-fakẹrẹ loju ọna naa.
Akọroyin BBC to gba oju ọhun jabọ pe sunkẹrẹ-fakẹrẹ naa bẹrẹ lati ọsan, o si gun lati afara Kara nipinlẹ Ogun titi de agbegbe 7Up niluu Eko.
Nigba ti yoo fi di aago mẹta aabọ ọsan, sunkẹrẹ-fakẹrẹ naa ti sun de ibudokọ Secretariat, gbogbo awọn ọkọ to n bọ lati Ikeja ati Agege lọna ati gba ori Afara Otedola fara gba ninu sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọhun.
Apapọ oṣiṣẹ ajọ to n ri si irinna oju popo nipinlẹ Eko, LASTMA, ti ijọba apapọ, FRSC ati ipinlẹ Ogun, Ogun State Traffic Compliance and Enforcement Corps lo ṣiṣẹ lati dari sunkẹrẹ-fakẹrẹ naa amọ o kọja agbara wọn.
Aago meji oru ni mo dele o si ṣeeṣe ki n ma pada sile lẹyin iṣẹ lọjọru - Araalu kan

Oríṣun àwòrán, screenshot
Sunkẹrẹ-fakẹrẹ yii ti ṣakoba fun irinajo ọpọ awọn olugbe ilu Eko atawọn mii to lọ si Eko lati ṣowo amọ ti sunkẹrẹ-fakẹrẹ naa mu ko ṣoro fun lati pada sile wọn, to fi mọ awọn awakọ igboro.
Obinrin kan ti ko fẹ fi orukọ ara rẹ lede sọ fun akọroyin wa pe ọja loun wa ra niluu Eko lati Ibadan amọ nigba ti sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọhun mulẹ gidi lo pe awọn mọlẹbi rẹ pe oun ko ni le dele lọjọ Iṣẹgun naa mọ.
Obinrin ọhun sọ pe oun ko lowo lati lọ gba ile itura ti oun yoo sun si lalẹ naa.
Awakọ kan, Tunji Kazeem, sọ fun ileeṣẹ iroyin Punch pe sunkẹrẹ-fakẹrẹ naa buru ju eyii ti apa oun le ka lọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, Mowe ni ipinlẹ Ogun loun n lọ amọ ko si ọna mii ti oun le gba yatọ si ọna ti sunkẹrẹ-fakẹrẹ naa wa.
Ẹlomii ti BBC ba sọrọ, ọgbẹni Adekunle Jimọ sọ pe aago meji oru loun dele latari sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọhun, o si ṣeeṣe ki oun ma pada sile lẹyin iṣẹ lọjọru.
Awọn agbegbe wo ni ọwọja rẹ de?

Oríṣun àwòrán, screenshot
Bi awọn arinrinajo ṣe wa n gba apa kan oju ọna naa lo mu ki sunkẹrẹfakẹrẹ naa o tubọ le sii.
Awọn ilu ati agbegbe bii Ibafo, Oworo, Ogudu, Mowe, Arepo, Magboro, Ikoyi, ati Berger lo di gaga ti awọn oṣiṣẹ oju pop oni ipinlẹ Eko, LASTMA si n gbiyanju lati ṣakoso lilọ bibọ ọkọ nibẹ.
Bakan naa, gbogbo awọn agbegbe bii Maryland, Ogudu, Ketu, Ikeja and Ogba ti ko sun mọ agbegbe Kara ti atunṣe yii ti n waye naa ti n foju wina wahala naa. Titi de agbegbe Iyana-Oworo nitosi Thirdmailand bridge ni ọwọja sunkẹrẹ fa kẹrẹ naa sun de lọjọ Aje.
Iye ọkọ to nrin opopona yii pọ pupọ eleyii to fa sunkẹrẹ fakẹrẹ naa nitori pe opopona Eko si Ibadan wa lara awọn opopona ti irinajo pọ julọ si lorilẹede Naijiria.
Gẹgẹbi atẹjade ti ijọba ti fi sita tẹlẹ, ọjọ kejilelogun oṣu kẹsan an ni eto atunṣe naa yoo pari.
Ki lo fa sunkẹrẹ-fakẹrẹ yii?

Oríṣun àwòrán, screenshot
Sunkẹrẹ-fakẹrẹ yii ko ṣẹyin atunṣe ori Afara Kara to n lọ lọwọ amọ kii ṣe igba akọkọ ree ti ijọba yoo ṣe atunṣe afara ọhun.
Yatọ si afara yii, atunṣe ori afara to wọ agbegbe OPIC, ni aala ipinlẹ Ogun ati ipinlẹ Eko naa kun ara ohun to fa sunkẹrẹ-fakẹrẹ naa.
Ọpọ lo n woye ohun to ṣokunfa atunṣe lemọlemọ lori afara yii atawọn afara kan nipinlẹ Eko.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, awọn eeyan n sọ pe awọn kan to n ṣa irin lati lọ ta lo n yọ awọn irin aarin ori afara naa, eyii to n mu ki ijọba ṣe atunṣe rẹ loorekoore to si n fa sunkẹrẹ-fakẹrẹ lemọlemọ.
Ki ni ijọba Eko sọ?

Oríṣun àwòrán, screenshot
Ninu ọrọ rẹ, ijọba ipinlẹ Eko rọ awọn arinrinajo atawọ̀n miran to n lo oju popo lati ṣe eto irin wọn nitori atunṣe ti ileeṣẹ ọrọ iṣẹ ode nijọba apapọ n gbe ṣe naa.
Atẹjade ti kọmiṣọna fun igbokegbodo ọkọ ni ipinlẹ Eko, Oluwaṣeun Osiyẹmi fi sita ṣaaju lọjọ keje oṣu kẹsan ọdun 2026 ṣalaye pe lati le mu ki ọwọja inira tie to atunṣe naa yoo mu ba araalu mọ niwọn, apa kan opopona naa ni wọn yoo maa ti ki awọn onimọto lee ma gba apa keji eyi ti wọn ba n ṣe.



























