Kókó ohun tó jẹyọ lásìkò àbẹ̀wò ìgbìmọ ìjọba àpapọ̀ sí Ogbomoso lórí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́ tí wọ́n jí gbé

Oríṣun àwòrán, Inside Ogbomoso/Facebook
Igbimọ ẹlẹni marun un ti adari awọn oṣiṣẹ nileeṣẹ aarẹ, Họnọrebu Femi Gbajabiamila, ko sodi ṣabẹwo si Esinele ati Yawota l'Ogbomso nibi tawọn agbebọn ti ji awọn akẹkọọ atawọn olukọ gbe lọ lọjọ kẹẹdogun oṣu Karun un to kọja.
Awọn mii to wa ninu igbimọ naa ni oludamọran aarẹ lori ọrọ eto aabo, Nuhu Ribadu, ọga agba ọlọpaa Naijiria, Tunji Disu, Minisita eto aabo, Christopher Musa ati oludamọran aarẹ lori ọrọ to n lọ, Sunday Dare.
Igbimọ naa kọminu lori iṣẹlẹ ọhun, wọn si ṣeleri pe Aarẹ Bola Tinubu yoo sa gbogbo agbara rẹ lati doola gbogbo awọn ti wọn ji gbe.
Igbimọ naa sọ fawọn adari atawọn aṣofin wi pe ijọba apapọ yoo ṣagbeyẹwo idasilẹ ibudo ologun nipinlẹ Oyo ti won n pe fun.
Gbajabiamila atawọn ọmọ igbimọ yooku tun sọ pe Tinubu ti paṣẹ wi pe kawọn ẹṣẹ eleto aabo doola awọn ti wọn ji gbe naa ni kiakia.
Ninu ọrọ rẹ, Gbajabiamila sọ pe bi Tinubu ṣe ran awọn ọga agba ileeṣẹ ologun lati lọ doola awọn olukọ atawọn akẹkọọ to wa lakata awọn ajinigbe fi han pe aarẹ ṣetan lati lo gbogbo agbara rẹ gba awọn eeyan naa lọwọ ajinigbe.
''Iṣẹlẹ ijinigbe yii n kọ aarẹ lominu gan an, ohunkohun to ba le gba, a maa doola awọn ọmọ wa atawọn olukọ lọwọ awọn ajinigbe.
Tinubu ti paṣẹ fun gbogbo awọn ẹṣọ eleto aabo lati ri pe awọn olukọ atawọn akẹkọọ to wa lakata awọn ajinigbe gbominira.
''Gbogbo inira yin ni a mọ, lagbara Ọlọrun, awọn ọmọ yin pada wale ni alaafia.
Aarẹ Tinubu ti gbọ igbe awọn obi atawọn ẹbi awọn eeyan to wa lakata ajinigbe.
Mo fẹ fi da yin loju wi pe gbogbo awọn ti wọn ji gbe ni yoo pada wale ni alaafia,'' Gbajabiamila.
Igbimọ naa tun kan si Soun Ilẹ Ogbomoso, Ọba Ghandi Afolabi Olaoye, ni aafin rẹ lati ba a kẹdun .
Igbimọ ọhun tun ṣabẹwo si iyawo olukọ tawọn agbebọn naa pa, Arabinrin Mary Oyedokun atawọn ọmọ wọn.

























