Wo àwọn àyípadà tó máa wáyé sí ètò ààbò bí Ààrẹ Tinubu ṣe buwọ́lu àfikún ẹkùn iléeṣẹ́ ológun di méjìlá

Aare Bola Tinubu, Aare ile Naijiria lo jokoo, to n ko iwe pelu igo loju re ati fila to de sori

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/Facebook

Àkọlé àwòrán, Aare Bola Tinubu
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Nipa erongba lati jẹ ki iṣe eto aabo ẹmi ati dukia araalu tubọ ni idagbasoke, Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti buwọ lu afikun si ẹkun ileeṣẹ ologun kaakiri Naijiria.

Aarẹ Tinubu sọ pe afikun naa yoo ṣe iranwọ pupọ fun eto aabo, ati pe awọn ologun yoo tun wa ni arọwọto lati daabo bo araalu.

Yatọ si afikun si ẹkun ileeṣẹ ologun naa, Aarẹ tun kede gbigba awọn ọmọ ogun ẹgbẹrun mejidinlọgbọn sẹnu iṣẹ, lati ṣafikun si awọn to wa nilẹ tẹlẹ.

Oludamọran pataki si Aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga lo fidi iroyin naa mulẹ ninu atẹjade to fi sita fun gbogbo eeyan l'Ọjọbọ, ọsẹ yii.

Ọnanuga sọ pe lara akitiyan ati ifarajin aarẹ nipa riro ileeṣẹ ologun lagbara, ati lati koju iṣoro to n dojukọ eto aabo ni igbesẹ naa wa fun.

"Bibuwọ lu yii lo ṣafihan akitiyan ati ifarajin aarẹ lati ro ileeṣẹ ologun lagbara nipa kikoju iṣoro ati ipenija to n dojukọ eto aabo, ati lati mu agbara idaabo bo orileede tẹsiwaju," Onanuga sọ bẹẹ.

"Afikun yii lo wa lara igbesẹ didokoowo sinu iṣẹ ologun, to fi mọ gbigba awọn ọmọ ogun tuntun sẹnu iṣẹ, gbigba awọn irinṣẹ ati ohun elo tuntun, to fi mọ imugbooro si igbayegbadun awọn ologun, ati iranlọwọ fun idagbasoke iṣẹ naa lọna igbalode."

Labẹ atunto tuntun yii, ileeṣẹ ologun ilẹ Naijiria yoo bẹrẹ sii ṣakoso ẹkun mejila ni awọn ẹkun to ṣara-ọtọ kaakiri ilẹ naa.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ileeṣẹ aarẹ jẹ ko di mimọ pe idasilẹ ẹkun tuntun mẹrin niluu Makurdi, Ilorin, Jalingo ati Benin yoo mu idagbasoke ba iṣẹ ologun ati asiko ti wọn yoo dide ṣisẹ.

"Idasilẹ ẹkun tuntun lawọn ilu bii Makurdi, Ilorin, Jalingo ati Benin yoo ko ipa rere ninu itẹsiwaju ati akoso awọn ẹkun naa, yoo mu aabo ala orileede gbooro si i, mu awọn ohun amayedẹrun pataki ti orileede pọ si i. Ko si daju pe awọn ọmọ ogun le fesi yara si awọn ewu tuntun to n farahan kaakiri orileede," Onanuga ṣalaye.

Ipele meji ni atunto idasilẹ naa yoo ti ṣiṣẹ.

Ipele akọkọ ni ti idasilẹ ẹkun Karun-un, Ikẹsan ati Ikẹwaa, ati atunto ninu agbekalẹ to ti wa nilẹ tẹlẹ, eyi to yẹ ko pari ninu oṣu Kẹsan.

Ipele keji ni idasilẹ ẹkun kẹtalelọgọrin and atunto agbekalẹ, eyi ti yoo pari ninu oṣu Kejila, ọdun 2026.

Aarẹ Tinubu wa gbe oriyin fun ọga ologun, Lt. Gen. Waidi Ibrahim Shuaibu, ati awọn oṣiṣẹ ati ologun, pẹlu ifarajin lati daabo bo orileede.

Siwaju sii ni aarẹ fidi ileri mulẹ lati tubọ maa ro awọn ologun lagbara, lati rii daju pe "wọn n gba ohun elo to yẹ, wọn n gba iwuri, ati igboya lati nipa didaabo bo gbogbo ọmọ ati olugbe Naijiria."

Awọn ẹkun tuntun ati ibi ti wọn yoo ti ṣiṣẹ ni:

Ẹkun Kaduna, ti yoo ṣiṣẹ fun ipinlẹ Kaduna, Kano, Katsina ati Jigawa;

Ẹkun Ibadan, ti yoo ṣiṣẹ fun ipinlẹ Oyo, Osun, Ekiti ati Ondo;

Ẹkun Jos, ti yoo ṣiṣẹ fun ipinlẹ Plateau, Bauchi ati Gombe;

Ẹkun Makurdi, ti yoo ṣiṣẹ fun ipinlẹ Benue, Nasarawa ati Kogi;

Ẹkun Port Harcourt, ti yoo ṣiṣẹ fun ipinlẹ Rivers, Akwa Ibom ati Cross River;

Ẹkun Maiduguri, ti yoo ṣiṣẹ fun ipinlẹ Borno ati Yobe;

Ẹkun Sokoto, ti yoo ṣiṣẹ fun ipinlẹ Sokoto, Kebbi ati Zamfara;

Ẹkun Ilorin, ti yoo ṣiṣẹ fun ipinlẹ Kwara ati Niger;

Ẹkun Jalingo, ti yoo ṣiṣẹ fun ipinlẹ Taraba ati Adamawa;

Ẹkun Lagos, ti yoo ṣiṣẹ fun ipinlẹ Eko ati Ogun;

Ẹkun Enugu, ti yoo ṣiṣẹ fun ipinlẹ Enugu, Anambra, Abia, Ebonyi ati Imo states; to fi mọ

Ẹkun Benin City, ti yoo ṣiṣẹ fun ipinlẹ Edo, Delta ati Bayelsa.