Ìfúpá àwọn èèyàn Ayetoro l‘Ondo ń ga sí, torí bí òkun ṣe ń ya wọ ìlú, gbé iléẹ̀kọ́, ilégbèé, iléeṣẹ́, ilẹ̀ àti ibojì òkù lọ

Àkọlé fídíò, Ìfúpá àwọn èèyàn ìlú Ayetoro l‘Ondo ń ga sí, bí òkun ṣe ń ya wọ ìlú, gbé iléẹ̀kọ́, ilégbèé, iléeṣẹ́, ilẹ̀ àti ibojì òkù lọ
Ìfúpá àwọn èèyàn Ayetoro l‘Ondo ń ga sí, torí bí òkun ṣe ń ya wọ ìlú, gbé iléẹ̀kọ́, ilégbèé, iléeṣẹ́, ilẹ̀ àti ibojì òkù lọ
Published

Ilu kan to jẹ erekoso to wa lẹba okun ni ilu Ayetoro jẹ eyi to wa ni ipinlẹ Ondo.

Bi agbekalẹ ilu naa sẹba okun se jẹ ire fawọn araalu naa, lo tun n mu ibi ati ewu ba wọn.

Idi ni pe bi okun se n bi siwa, bi sẹyin, ti ọwọja rẹ n lọ soke si lo ti n wọ ọpọ ohun meremere ilu naa lọ.

Koda, okun ti fẹrẹ gba gbogbo ilu naa tan, tawọn araalu naa si n gbe ninu ibẹrubojo pe ki okun ma wọ wọn lọ patapata ni lọjọ kan.

Akọroyin BBC, Esther Omopariola sabẹwo silu naa lati mọ iru ewu ti wọn wa ati isoro ti wọn n koju tori ọwọja omi okun to n pọ si lagbegbe naa.

Aworan bi omi okun se ru titi de odidi ile kan ni Ayetoro

"O ti to igba marun ti ile ẹkọ mi paarọ ibi ti a n lo, inu wa ko dun bi omi okun se n wọ ile ẹkọ wa, o nira fun wa bi a se n kuro nile iwe kan bọ si omiran"

Ọkan lara awọn eeyan to ba BBC sọrọ nilu Ayetoro jẹ akẹkọọ, to si salaye bi okun se n se akoba fun eto ẹkọ wọn.

"O ti to igba marun ti ile ẹkọ mi paarọ ibi ti a n lo, inu wa ko dun bi omi okun se n wọ ile ẹkọ wa lọ.

O nira fun wa bi a se n kuro nile iwe kan bọ si omiran.

Nigbakiigba ti omi yii ba de, yoo wọnu yara ikawe wa, yoo gbe iwe wa lọ, to fi mọ baagi wa atawọn aga ti a fi n joko."

A gbọ pe o ti le ni ogun ọdun, tilu Ayetoro ti n koju isoro ẹkun omi.

Lara awọn eeyan to tun ba BBC sọrọ fidi rẹ mulẹ pe ilu Ayetoro ti padanu oju ọna to le ni ogoji ninu marundinlaadọta to wa ni agbegbe wọn.

"A ti padanu ida ọgọta ninu ilẹ to wa nilu naa si ọwọ okun to n ya bo wa, ilẹ to si ku ko ju ida mẹẹdogun pere lọ."

Obinrin kan tiẹ tun salaye awọn isoro to koju nidi ilegbe tori ẹkun omi to n ba ilu Ayetoro finra ni gbogbo igba.

"Mo gbe ile iya mi ni ọdun 2000, nigba to ya, ẹkun omi wa, o gbe ile naa lọ, bakan naa, mo tun lọ sile iya mi amọ oun naa tun ti wa ninu isoro ẹkun omi bayii.

Aworan bi omi okun se ru titi de odidi ile kan ni Ayetoro

"N ko le sọ pe saare baba mi ree nilu Ayetoro, koda ile mọlẹbi ko si mọ, ifunpa wa n ga lojoojumọ, a si n lo oogun ẹjẹ riru tori a ko mọ igba ti omi tun le wa"

Bakan naa, a tun gbọ pe ọpọ iboji oku ni omi ti wọ lọ nilu Ayetoro, ti ọpọ ọmọ ati ẹbi ko si mọ iboji awọn obi tabi ẹbi wọn mọ.

"N ko le sọ pe saare baba mi ree nilu Ayetoro, koda ile mọlẹbi ko si mọ."

Obinrin naa ni ifunpa oun n ga lojoojumọ, ti oun si n lo oogun ẹjẹ riru nitori awọn ko mọ igba ti omi naa yoo tun wa.

O ni awọn ko le pa oju de, ọkan awọn ko si balẹ pe omi naa le wa nigba kuugba, fun idi eyi, awọn ko le sun tori ọkan awọn ko balẹ rara.

Omi okun to n ya lu ilu Ayetoro maa n ga fiofio, bo se n fẹ ni yoo ma tobi si, o si maa n ga to iwọn ẹsẹ bata mẹfa si mẹwa nigba mii.

Bo se n ya wọle, ni yoo maa kọlu awọn nnkan miran, titi ti yoo fi da wọn wo lulẹ, ti yoo si wọ wọn lọ sinu okun.

Ẹlomii to tun ba BBC sọrọ ni "gbogbo ileesẹ tawọn baba wa kọ, ni a ti padanu.

Bi ileesẹ ti wọn ti n se bata, ọsẹ, ile ẹkọ fawọn to n kọ ile ati ile ẹkọsẹ ọwọ atawọn ile ẹkọ ti wọn ti n kọ nipa okun.

Gbogbo awọn ohun alumọọni ti a ni, ni a ti padanu."

Itan ilu Ayetoro jẹ eyi to ba ni lọkan jẹ pupọ tori bi ayipada oju ọjọ, wiwa epo rọbi lawọn agbegbe kan, lile omi pada ati aisi idagbasoke se n se akoba fun Naijiria.

Aworan bi omi okun se ru titi de odidi ileẹkọ kan ni Ayetoro