"Ìjọba rí epo rọ̀bì ní ìlú wa àmọ́ a kò jàǹfààní kankan, kò sí omi, iná, ojú ọ̀nà, ààbò, iléẹ̀kọ́ àti ilé ìwòsàn"
Yoruba ni Ọba oke kii pa ni lori, ko ma fi irungbọn di, bẹẹ ni ọrọ awọn eeyan ilu Ẹ̀bà ri, to jẹ ilu erekusu to wa lẹba okun.
Ilu Ẹ̀bà yii si lo pa aala laarin ipinlẹ Ondo ati Ogun, o si jẹ ilu to wa lẹsẹ Odo, labẹ nijọba ibilẹ Ogun Waterside nipinlẹ Ogun.
Isẹ agbẹ ati Apẹja nisẹ wọn amọ ọpọ awọn ohun eelo amayedẹrun bii ina, omi, eto aabo, oju popo , ile ẹkọ ati ile iwosan lo n jẹ awọn araalu naa niya.
Bi wọn se n koju igbe aye ti ko dẹrun yii, sibẹ, ọba oke tun fi ohun alumọọni epo rọbi jinki wọn.
Laipẹ yii ni ijọba ri epo rọbi ni ilu naa amọ awari epo yii tun n da omi tutu sawọn araalu naa lọkan pe se ọrọ awọn ko ni di ajẹkun iya bayii.
Bi o tilẹ jẹ pe ijọba apapọ ti fi ikọ awọn ologun ransẹ lati maa sọ awọn epo rọbi naa, sibẹ, wọn ko mọ ipa ijọba apapọ ati tipinlẹ lara lagbegbe naa.
Idi ree ti BBC News Yoruba fi ṣe àbẹ̀wò sílùú Ẹ̀bá, láti mọ̀ nípa àwọn àǹfààní àti ìpèníjà tó ń kojú wọn, bí ìjọba àpapọ̀ ṣe ṣàwárí epo rọ̀bí nílùú náà.

A ko ri ọwọ ijọba kankan, ko si ọna, ko si ina, ko si ileewe, ko si ileewosan, ko si omi, koda, ko si nkankan - Baalẹ ilu Ẹ̀bá
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Baalẹ erekusu Ẹ̀bà, Ipinnuoluwa Igbile salaye pe ipinlẹ Ogun ni ilu naa wa, to si ti lo bii ọọdunrun ọdun.
O wa mẹnuba ọpọ ipenija to n ba erekusu naa finra ati bawọn ijọba to n dari ipinlẹ Ogun se kẹyin si awọn araalu naa.
"A ko ri ọwọ ijọba kankan, ko si ọna, ko si ina, ko si ileewe, ko si ileewosan, ko si omi, koda, ko si nkankan.
Lọjọ to ti pẹ nilu ti ri epo nibẹ yẹn, awọn ijọba wa wo ibẹ, wọn si ko awọn agbofinro sibẹ.
Bakan naa ni wọn tun gbe ileesẹ to n ri si ọrọ epo rọbi, NNPC wa, ti wọn si fidi rẹ mulẹ pe lootọ epo lo wa nibẹ."

"Isẹ Agbẹ ati isẹ ẹja pipa ni a yan laayo, a si mọ pe epo ti wọn se awari rẹ yii yoo maa yọ wa lẹnu lọpọlọpọ"
Bakan naa ni Baalẹ Ẹ̀bá sọrọ nipa epo rọbi ti wọn ri ni erekusu naa.
"Igba ti wọn ti ri epo ni agbegbe wa yii, ko tii si ijọba kankan to kan si wa.
Awa naa si n wo wọn boya o ni ọna miran ti wọn fẹ gbe gba.
Isẹ Agbẹ ati isẹ ẹja pipa ni a yan laayo, a si mọ pe epo ti wọn se awari rẹ yii yoo maa yọ wa lẹnu lọpọlọpọ.
Ti wọn ba ti bẹrẹ si ni wa epo, ilẹ ilu wa yii ko ni mu irugbin to dara jade mọ."
Bakan naa lo fi kun pe oju ọna ti ko dara ko jẹ ki katakara awọn maa lọ deede."
Baale wa fidi rẹ mulẹ pe awọn ti kọwe sijọba apapọ pe awọn lo ni ibẹ yẹn, awọn si n reti esi ayọ lati ọdọ ijọba.

"Ijọba ko da si wa, ti a ba loyun, a ko nile iwosan, a n lọ si Okitipupa, Igbọkọda, Ijebu Ode lati wa iwosan, ti a ba lọ laarọ, yoo to aago mẹjọ alẹ ki a to pada"
Bakan naa, obinrin kan to n gbe nilu Ẹ̀bá, Olatokunbo Adekoya, toun naa ba BBC News Yoruba sọrọ, ilẹ kun lori ọpọ isoro to n bawọn finra nilu naa.
"Ijọba ko da si wa, ti a ba loyun nibi yii, a ko nile iwosan, a le lọ si Ẹbígi, ẹlomiran n lọ si Okitipupa, omiran n lọ silu Igbọkọda.
Koda, ẹlomiran n lọ silu Ijebu Ode lati wa iwosan, ti wọn ba lọ laarọ, yoo to aago mẹjọ alẹ ki wọn to pada de.
A maa n gba omi nla yii sọda, a tun maa rin ninu igbo eyi to to Maili mejila, lẹyin naa ni a tun la omi miran kọja, ki wọn to gbe wa de ilu Àtíjẹ̀rẹ.
Nibẹ si la ti n ma n wọ̀ mọto lọ silu Ijebu Ode.
Ko si ileẹkọ ta le fawọn ọmọ wa si, emi ti mo n sọrọ yii, awọn ọmọ temi wa nilu Ayétẹ́jú, nibi ti wọn ti n lọ sile ẹkọ.
Awọn ọmọ to yẹ ki wọn wa ni akata mi, opin ọsẹ ni wọn maa n wa sile.







