"Lóòótọ́ ni mò ń rówó lẹ́yìn tí mo ṣoògùn owó àmọ́ n kò le kọ́lé tàbí ra ọkọ̀"

Àkọlé fídíò, "Lóòótọ́ ni mò ń rówó lẹ́yìn tí mo ṣoògùn owó àmọ́ n kò le kọ́lé tàbí ra ọkọ̀"
"Lóòótọ́ ni mò ń rówó lẹ́yìn tí mo ṣoògùn owó àmọ́ n kò le kọ́lé tàbí ra ọkọ̀"
Published

Yoruba bọ wọn ni bi eeyan ko ba mọ ibi ẹgbẹ rẹ gbe n la, ni ṣe ni eeyan yoo ma sare asaku.

Pasitọ ijọ kan ree ni ilu Ogbomoso, ipinlẹ Oyo, Pasitọ Joel Olasunkanmi Adedeji, ẹni to igbiyanju oun lati ṣe oogun owo nigba ewe.‎

‎Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu ile iṣẹ BBC News Yoruba niluu Ogbomoso, Pasitọ Joel ni oun ko ju bi ọmọ ogun ọdun le diẹ lọ nigba naa, eyi to jẹ nnkan bii ọgbọn ọdun sẹyin ti oun pinnu lọkan ara oun lati wu gbogbo iwa to buru julọ ki Ọlọrun le binnu si oun.

‎O ni oun gbagbọ pe atunbọtan oogun owo ti oun gbiyanju lati ṣe lo sọ oun di alaabọ ara lẹyin ọdun marun-un ti oun gbe igbesẹ naa.