Wo pàtàkì òrìṣà Vodu Dangbe, níbi táwọn olùjọ́sìn ti ń gbé ejò sọ́rùn, kẹ̀yìn sí ìbálòpọ̀, jíjẹ epo tàbí iyọ̀ ṣaájú ètùtù
Ni ilẹ Yoruba, oniruuru orisa lo wa ninu eyi ti wọn ti n bọ eeyan tabi omi.
Iran Yoruba si lo ni awọn orisa bii Sango, Oya, Obatala, Ogun, Osun ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti gbogbo wọn jẹ akọni eeyan to ti se gudugudu meje ati yaayaa mẹfa laye igbaani.
Amọ ohun ajeji gbaa ni lati ri pe orisa kan wa to jẹ bibọ ẹranko, irufẹ orusa naa si ni Orisa Vodu Dagbe.
Ejo ni orisa yii, se ni awọn olujọsin rẹ si maa n gbe ejo sọrun lasiko ti wọn ba n bọ ọ.
Orilẹede Olominira Benin si ni orisa naa wa, nibi ti ọpọlọpọ awọn olujọsin rẹ wa, ti wọn ti n pe jọ lọdọọdun lati bọ ọ.
BBC News Yoruba bawọn peju si ilu Porto-Novo to wa ilẹ olominira Benin lati mọ si nipa ohun ti orisa Vodu Dagbe da le lori.

"Orisa Vodu Dagbe kii ge eeyan jẹ rara, bẹẹ ni kii si pa eeyan lara, kaka ko ge eeyan jẹ, se lo maa n wo eeyan san ninu oniruuru aisan"
Gẹgẹ bi wọn ti salaye fun BBC News Yoruba, orisa Vodu Dagbe kii se ayaba fun wọn amọ o jẹ orisa ti wọn jogun ba lọdọ awọn baba nla wọn.
Ngba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Mintódè Missihoun tii se abọrisa naa salaye pe o ti pẹ ti awọn ti n sin orisa naa, Dangbe-Klounón si ni wọn npe orisa naa ni ede Porto-Novo to wa nilẹ olominira Benin.
"Ejo ni orisa wa lagbegbe yii, ati ọmọde ati agba si lo fẹran ejo nibi, ti ejo kii si se wa ni ijamba kankan.
Orisa Vodu Dagbe kii ge eeyan jẹ rara, bẹẹ ni kii si pa eeyan lara, kaka ko ge eeyan jẹ, se lo maa n wo eeyan san ninu oniruuru aisan.
Bakan naa ni orisa elejo yii maa n fun awọn eeyan ni aabo to peye, ti ebi ba si n pa awọn ejo yii, a ko le sọ pe nnkan pato bayii ni wọn n jẹ.
Amọ awa maa n tu wọn silẹ, ki wọn rin jade lọ lati wa nnkan ti wọn maa jẹ.
Ti wọn ba si jade lọ, sere titi, to ba ya wọn, wọn yoo tun pada wa sile."

Bakan naa ni baba olorisa yii salaye pe orisa naa ti sami sawọn ọmọ wọn lara, ko si si abami ejo kan to ba ri wọn ninu igbo, kaka ki awọn ọmọ wọn bẹru, ejo ni ẹru yoo ba.
"Ejo lo maa n sa fun awọn ọmọ wa amọ eewọ wa gan fun bibọ orisa yii.
Emi ti mo jẹ asaaju awọn eeyan to n bọ orisa yii, n ko gbọdọ ba obinrin lopọ ki n to wa sidi orisa naa.
Eewọ keji ni pe bi etutu fun orisa naa ba ti ku ọla, maa sun ile orisa mọju tori pe n ko gbọdọ foju ri eeyan kankan, ki n to bẹrẹ etutu.
Eewọ kẹta ni pe ẹni to ba n sin orisa yii, to si fẹ gba dura nidi orisa lati ri esi gba, ko gbọdọ jẹ ata, iyọ tabi ni ibalopọ pẹlu kankan ko to wa gbadura nidi orisa naa.
Ko si ibẹrun fun ọmọ ti wọn ba bi sinu orisa yii lasiko to ba gbe ejo sọrun, se ni inu awọn ọmọ naa maa n dun pe ọdun ti sun mọle.
Ọdun orisa Vodu Dangbe ko le parẹ laelae tori ti awa ti a n sin ba ti lọ, awọn ọmọ ta bi sinu rẹ yoo maa tẹ siwaju."
Bakan naa ni awọn ọmọde to gbe ejo yii sọrun lati bọ orisa naa tun ba BBC News Yoruba sọrọ lori bi ọdun naa se ri lara wọn.







